Isa 12:1-4
Isa 12:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
ATI li ọjọ na iwọ o si wipe, Oluwa, emi o yìn ọ: bi o tilẹ ti binu si mi, ibinu rẹ ti yi kuro, iwọ si tù mi ninu. Kiyesi i, Ọlọrun ni igbala mi; emi o gbẹkẹle, emi ki yio si bẹ̀ru: nitori Oluwa Jehofah li agbara mi ati orin mi; on pẹlu si di igbala mi. Ẹnyin o si fi ayọ̀ fà omi jade lati inu kanga igbala wá. Li ọjọ na li ẹnyin o si wipe, Yìn Oluwa, kepe orukọ rẹ̀, sọ iṣẹ́ rẹ̀ lãrin awọn enia, mu u wá si iranti pe, orukọ rẹ̀ li a gbe leke.
Isa 12:1-4 Yoruba Bible (YCE)
O óo sọ ní ọjọ́ náà pé, “N óo fi ọpẹ́ fún OLUWA, nítorí pé bí ó tilẹ̀ bínú sí mi, inú rẹ̀ ti rọ̀, ó sì tù mí ninu. Wò ó! Ọlọrun ni olùgbàlà mi, n óo gbẹ́kẹ̀lé e ẹ̀rù kò sì ní bà mí, nítorí pé OLUWA Ọlọrun ni agbára mi, ati orin mi, òun sì ni Olùgbàlà mi.” Tayọ̀tayọ̀ ni ẹ óo fi máa rí ìgbàlà bí ẹni pọn omi láti inú kànga. Ẹ óo sọ ní ọjọ́ náà pé, “Ẹ fọpẹ́ fún OLUWA, ẹ ké pe orúkọ rẹ̀, ẹ kéde iṣẹ́ rere rẹ̀ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè; ẹ kéde pé a gbé orúkọ rẹ̀ ga.
Isa 12:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ọjọ́ náà ni ìwọ ó wí pé: “Èmi ó yìn ọ́, OLúWA. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ò ti bínú sí mi ìbínú rẹ ti yí kúrò níbẹ̀ ìwọ sì ti tù mí nínú. Nítòótọ́ Ọlọ́run ni ìgbàlà mi, èmi yóò gbẹ́kẹ̀lé e èmi kì yóò bẹ̀rù. OLúWA, OLúWA náà ni agbára à mi àti orin ìn mi, òun ti di ìgbàlà mi.” Pẹ̀lú ayọ̀ ni ìwọ yóò máa pọn omi láti inú kànga ìgbàlà. Ní ọjọ́ náà, ìwọ yóò wí pé: “Fi ọpẹ́ fún OLúWA, ké pe orúkọ rẹ̀, Jẹ́ kí ó di mí mọ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ohun tí ó ti ṣe kí o sì kéde pé a ti gbé orúkọ rẹ̀ ga.