Isa 10:1-4
Isa 10:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
EGBE ni fun awọn ti npaṣẹ aiṣododo, ati fun awọn akọwe ti nkọ iwe ìka; Lati yi alaini kuro ni idajọ, ati lati mu ohun ẹtọ kuro lọwọ talakà enia mi, ki awọn opo ba le di ijẹ wọn, ati ki wọn ba le jà alainibaba li ole! Kili ẹnyin o ṣe lọjọ ibẹ̀wo, ati ni idahoro ti yio ti okere wá? tali ẹnyin o sá tọ̀ fun irànlọwọ? nibo li ẹnyin o si fi ogo nyin si? Laisi emi nwọn o tẹ̀ ba labẹ awọn ara-tubu, nwọn o si ṣubu labẹ awọn ti a pa. Ni gbogbo eyi ibinu rẹ̀ kò yi kuro, ṣugbọn ọwọ́ rẹ̀ nà jade sibẹ.
Isa 10:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn tí ń ṣe òfin tí kò tọ́ gbé! Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn akọ̀wé, tí ń kọ̀wé láti ni eniyan lára; wọ́n ń dínà ìdájọ́ òdodo fún àwọn aláìní, wọn kò sì jẹ́ kí àwọn talaka ààrin àwọn eniyan mi rí ẹ̀tọ́ wọn gbà, kí wọ́n lè sọ àwọn opó di ìkógun. Kí ni ẹ óo ṣe lọ́jọ́ ìjìyà yín tí ìparun bá dé láti òkèèrè? Ta ni ẹ óo sá tọ̀ lọ fún ìrànlọ́wọ́? Níbo ni ẹ óo kó ọrọ̀ yín sí? Kò sí ohun tí ó kù àfi kí ẹ kú lójú ogun, tabi kí ẹ ká góńgó láàrin àwọn tí wọ́n kó lẹ́rú. Sibẹsibẹ inú OLUWA kò ní rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò ní dá ọwọ́ ìjà rẹ̀ dúró.
Isa 10:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ègbé ni fún àwọn ti ń ṣe òfin àìṣòdodo láti dún àwọn aláìní ní ẹ̀tọ́ wọn àti láti fa ọwọ́ ìdájọ́ sẹ́yìn kúrò níwájú àwọn olùpọ́njú ènìyàn mi, Wọ́n sọ àwọn ọ̀pọ̀ di ìjẹ fún wọn. Wọ́n sì ń ja àwọn aláìní baba lólè. Kí ni ìwọ yóò ṣe ní ọjọ́ ìṣirò nígbà tí ìparun bá ti ọ̀nà jíjìn wá? Ta ni ìwọ yóò sá tọ̀ fún ìrànlọ́wọ́? Níbo ni ìwọ yóò fi ọrọ̀ rẹ sí? Ohunkóhun kò ní ṣẹ́kù mọ́ bí kò ṣe láti tẹ̀ ba láàrín àwọn ìgbèkùn tàbí kí o ṣubú sáàrín àwọn tí a pa.