Hos 9:10-17

Hos 9:10-17 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA wí pé: “Mo rí Israẹli he bí ìgbà tí eniyan rí èso àjàrà he ninu aṣálẹ̀. Lójú mi, àwọn baba ńlá yín dàbí èso tí igi ọ̀pọ̀tọ́ kọ́ so ní àkókò àkọ́so rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n rí sí mi, ṣugbọn nígbà tí wọ́n dé òkè Baali Peori, wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ fún oriṣa Baali, wọ́n sì di ohun ẹ̀gbin, bí oriṣa tí wọ́n fẹ́ràn. Ògo Efuraimu yóo fò lọ bí ẹyẹ, wọn kò ní lóyún, wọn kò ní bímọ, bẹ́ẹ̀ ni ọlẹ̀ kò ní sọ ninu wọn! Bí wọ́n bá tilẹ̀ bímọ, n óo pa wọ́n tí kò ní ku ẹyọ kan. Bí mo bá kọ̀ wọ́n sílẹ̀, wọ́n gbé!” Mo rí àwọn ọmọ Efuraimu bí ẹran àpajẹ; Efuraimu gbọdọ̀ kó àwọn ọmọ rẹ̀ jáde fún pípa. Fún wọn ní nǹkankan, OLUWA, OLUWA, kí ni ò bá tilẹ̀ fún wọn? Jẹ́ kí oyún máa bàjẹ́ lára obinrin wọn, kí ọmú wọn sì gbẹ. OLUWA ní, “Gbogbo ìwà burúkú wọn wà ní Giligali, ibẹ̀ ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí kórìíra wọn. Nítorí iṣẹ́ burúkú wọn, n óo lé wọn jáde ní ilé mi. N kò ní fẹ́ràn wọn mọ́, ọlọ̀tẹ̀ ni gbogbo àwọn olórí wọn. Ìyà jẹ Efuraimu, gbòǹgbò wọn ti gbẹ, wọn kò sì ní so èso mọ́. Bí wọ́n tilẹ̀ bímọ, n óo pa àwọn ọmọ tí wọ́n fẹ́ràn.” Ọlọrun mi yóo pa wọ́n run, nítorí pé wọn kò fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀; wọn yóo di alárìnkiri láàrin àwọn orílẹ̀-èdè.

Hos 9:10-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Mo rí Israẹli bí èso àjàrà ní aginjù. Mo rí àwọn baba yín, bí àkọ́pọ́n nínú igi ọ̀pọ̀tọ́ ní àkọ́so rẹ̀. Ṣùgbọ́n wọ́n tọ Baali-Peori lọ, wọ́n yà wọn sọ́tọ̀ fún òrìṣà tó ń mú ìtìjú bá ni, ohun ìríra wọn sì rí gẹ́gẹ́ bí wọn ti fẹ́. Ògo Efraimu yóò fò lọ bí ẹyẹ kò ní sí ìfẹ́rakù, ìlóyún àti ìbímọ. Bí wọ́n tilẹ̀ tọ́ ọmọ dàgbà. Èmi yóò mú wọn ṣọ̀fọ̀ lórí gbogbo wọn Ègbé ni fún wọn, nígbà tí mo yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn! Mo rí Efraimu bí ìlú Tire tí a tẹ̀dó sí ibi dáradára ṣùgbọ́n Efraimu yóò kó àwọn ọmọ rẹ̀ jáde fún àwọn apànìyàn.” Fún wọn, OLúWA! Kí ni ìwọ yóò fún wọn? Fún wọn ní inú tí ń ba oyún jẹ́ àti ọyàn gbígbẹ. “Nítorí gbogbo ìwà búburú tí wọ́n hù ní Gilgali Mo kórìíra wọn níbẹ̀, nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Èmi yóò lé wọn jáde ní ilé mi Èmi kò ní ní ìfẹ́ wọn mọ́ ọlọ̀tẹ̀ ni gbogbo olórí wọn. Efraimu ti rẹ̀ dànù gbogbo rẹ̀ sì ti rọ, kò sì so èso, Bí wọ́n tilẹ̀ bímọ. Èmi ó pa àwọn ọmọ wọn tí wọ́n fẹ́ràn jùlọ.” Ọlọ́run mi yóò kọ̀ wọ́n sílẹ̀ nítorí pé wọn kò gbọ́rọ̀ sí i; wọn yóò sì di alárìnkiri láàrín àwọn orílẹ̀-èdè.