Hos 8:1-10
Hos 8:1-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
FI ipè si ẹnu rẹ. Yio wá bi idì si ile Oluwa, nitori nwọn ti re majẹmu mi kọja, nwọn si ti rú ofin mi. Nwọn o kigbe si mi pe, Ọlọrun mi, awa Israeli mọ̀ ọ. Israeli ti gbe ohunrere sọnù; ọta yio lepa rẹ̀. Nwọn ti fi ọba jẹ, ṣugbọn kì iṣe nipasẹ̀ mi: nwọn ti jẹ olori, ṣugbọn emi kò si mọ̀: fàdakà wọn ati wurà wọn ni nwọn fi ṣe òriṣa fun ara wọn, ki a ba le ké wọn kuro. Ọmọ-malu rẹ ti ta ọ nù, Samaria; ibinu mi rú si wọn: yio ti pẹ to ki nwọn to de ipò ailẹ̀ṣẹ? Nitori lati ọdọ Israeli wá li o ti ri bẹ̃ pẹlu; oniṣọ̀na li o ṣe e; nitorina on kì iṣe Ọlọrun: ṣugbọn ọmọ malu Samaria yio fọ tũtũ. Nitori nwọn ti gbìn ẹfũfũ, nwọn o si ka ãjà: kò ni igi ọka: irúdi kì yio si mu onjẹ wá: bi o ba ṣepe o mu wá, alejò yio gbe e mì. A gbe Israeli mì: nisisiyi ni nwọn o wà lãrin awọn Keferi bi ohun-elò ninu eyiti inu-didùn kò si. Nitori nwọn goke lọ si Assiria, kẹtẹ́kẹtẹ́ igbẹ́ nikan fun ara rẹ̀: Efraimu ti bẹ̀ awọn ọrẹ li ọ̀wẹ. Nitõtọ, bi nwọn tilẹ ti bẹ̀ ọ̀wẹ lãrin awọn orilẹ-ède, nisisiyi li emi o ko wọn jọ, nwọn o si kãnu diẹ fun ẹrù ọba awọn ọmọ-alade.
Hos 8:1-10 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA ní: “Ẹ ti fèrè bọnu, nítorí ẹyẹ igún wà lórí ilé mi, nítorí pé wọ́n ti yẹ àdéhùn tí mo bá wọn ṣe, wọ́n sì ti rú òfin mi. Wọ́n ń ké pè mí, wọ́n ń wí pé, ‘Ọlọrun wa, àwa ọmọ Israẹli mọ̀ ọ́.’ Israẹli ti kọ ohun rere sílẹ̀; nítorí náà, àwọn ọ̀tá yóo máa lépa wọn. “Wọ́n ń fi ọba jẹ, láìsí àṣẹ mi. Wọ́n ń yan àwọn aláṣẹ, ṣugbọn n kò mọ̀ nípa rẹ̀. Wọ́n ń fi fadaka ati wúrà wọn yá ère fún ìparun ara wọn. Mo kọ oriṣa ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù yín, ẹ̀yin ará Samaria. Inú mi ń ru sí wọn. Yóo ti pẹ́ tó kí àwọn ọmọ Israẹli tó di mímọ́? Oriṣa ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù kì í ṣe Ọlọrun, iṣẹ́ ọwọ́ eniyan ni, a óo sì rún ti Samaria wómúwómú. Wọ́n ń gbin afẹ́fẹ́, wọn yóo sì ká ìjì líle. Ọkà tí kò bá tú, kò lè lọ́mọ, bí wọ́n bá tilẹ̀ lọ́mọ, tí wọ́n sì gbó, àwọn àjèjì ni yóo jẹ ẹ́ run. A ti tú Israẹli ká, wọ́n ti kọ́ àṣàkaṣà àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà láàrin wọn, wọ́n sì dàbí ohun èlò tí kò wúlò. Nítorí pé wọ́n lọ sí Asiria, wọ́n dàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ìgbẹ́ tí ń dá rìn; Efuraimu ti bẹ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ lọ́wẹ̀ fún ààbò. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti ta ara wọn fún àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, n óo kó wọn jọ láìpẹ́, láti jẹ wọ́n níyà, fún ìgbà díẹ̀, lọ́dọ̀ àwọn ọba alágbára tí yóo ni wọ́n lára.
Hos 8:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Fi ìpè sí ẹnu rẹ! Ẹyẹ idì wà lórí ilé OLúWA nítorí pé àwọn ènìyàn ti dalẹ̀ májẹ̀mú, wọ́n sì ti ṣọ̀tẹ̀ sí òfin mi. Israẹli kígbe pè mí ‘Háà! Ọlọ́run wa, àwa mọ̀ ọ́n!’ Ṣùgbọ́n Israẹli ti kọ ohun tí ó dára sílẹ̀ ọ̀tá yóò sì máa lépa rẹ̀ Wọ́n fi àwọn ọba jẹ ṣùgbọ́n, kì í ṣe nípasẹ̀ mi wọ́n yan ọmọ-aládé láì si ìmọ̀ mi níbẹ̀. Wọ́n fi fàdákà àti wúrà ṣe ère fún ara wọn, si ìparun ara wọn. Ju ère ẹgbọrọ màlúù rẹ, ìwọ Samaria! Ìbínú mi ń ru sí wọn: yóò ti pẹ́ tó kí wọ́n tó dé ipò àìmọ̀kan? Israẹli ni wọ́n ti wá! Ère yìí—agbẹ́gilére ló ṣe é Àní ère ẹgbọrọ màlúù Samaria, ni a ó fọ́ túútúú. “Wọ́n gbin afẹ́fẹ́ wọ́n sì ká ìjì Igi ọkà kò lórí, kò sì ní mú oúnjẹ wá. Bí ó bá tilẹ̀ ní ọkà àwọn àjèjì ni yóò jẹ. A ti gbé Israẹli mì, báyìí, ó sì ti wà láàrín àwọn orílẹ̀-èdè bí ohun èlò tí kò wúlò. Nítorí pé wọ́n ti gòkè lọ sí Asiria gẹ́gẹ́ bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó tó ń rìn kiri. Efraimu ti ta ara rẹ̀ fún àwọn olólùfẹ́ rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti ta ara wọn sí àárín orílẹ̀-èdè Èmi ó ṣà wọ́n jọ nísinsin yìí Wọn ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣòfò dànù lọ́wọ́ ìnilára ọba alágbára.