Hos 7:1-2
Hos 7:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBATI emi iba mu Israeli li ara dá, nigbana ni ẹ̀ṣẹ Efraimu fi ara hàn, ati ìwa-buburu Samaria; nitori nwọn ṣeké; olè si wọle, ọwọ́ olè si nkoni lode. Nwọn kò si rò li ọkàn wọn pe, emi ranti gbogbo ìwa-buburu wọn: nisisiyi iṣẹ ara wọn duro yi wọn ka; nwọn wà niwaju mi.
Hos 7:1-2 Yoruba Bible (YCE)
“Nígbà tí mo bá fẹ́ dá ire Israẹli eniyan mi pada, tí mo bá sì fẹ́ wò wọ́n sàn, kìkì ìwà ìbàjẹ́ Efuraimu ati ìwà ìkà Samaria ni mò ń rí; nítorí pé ìwà aiṣododo ni wọ́n ń hù. Àwọn olè ń fọ́lé, àwọn jàgùdà sì ń jalè ní ìgboro. Ṣugbọn wọn kò rò ó pé mò ń ranti gbogbo ìwà burúkú àwọn. Ìwà burúkú wọn yí wọn ká, ẹ̀ṣẹ̀ wọn sì wà níwájú mi.”
Hos 7:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
nígbà tí èmi ìbá mú Israẹli láradá. Ẹ̀ṣẹ̀ Efraimu ń farahàn ìwà búburú Samaria sì ń hàn síta. Wọ́n ń ṣe ẹ̀tàn, àwọn olè ń fọ́ ilé; àwọn ọlọ́ṣà ń jalè ní òpópónà; Ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀ pé mo rántí gbogbo ìwà búburú wọn: Ẹ̀ṣẹ̀ wọn gbé wọn mì pátápátá; wọ́n wà níwájú mi nígbà gbogbo.