Hos 6:2-3
Hos 6:2-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
Lẹhìn ijọ meji, yio tún wa jí: ni ijọ kẹta yio ji wa dide, awa o si wà lãyè niwaju rẹ̀. Nigbana li awa o mọ̀, bi a ba tẹramọ́ ati mọ̀ Oluwa: ati pèse ijadelọ rẹ̀ bi owùrọ: on o si tọ̀ wa wá bi ojò: bi arọ̀kuro ati akọrọ̀ òjo si ilẹ.
Pín
Kà Hos 6Hos 6:2-3 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn ọjọ́ meji, yóo sọ wá jí, ní ọjọ́ kẹta, yóo gbé wa dìde, kí á lè wà láàyè níwájú rẹ̀. Ẹ jẹ́ kí á mọ̀ ọ́n, ẹ jẹ́ kí á tẹ̀síwájú kí á mọ OLUWA. Dídé rẹ̀ dájú bí àfẹ̀mọ́jú; yóo sì pada wá sọ́dọ̀ wa bí ọ̀wààrà òjò, ati bí àkọ́rọ̀ òjò tí ń bomirin ilẹ̀.”
Pín
Kà Hos 6Hos 6:2-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn ọjọ́ méjì, yóò sọ wá jí ní ọjọ́ kẹta yóò mú wa padà bọ̀ sípò kí a ba à le wá gbé níwájú rẹ̀ Ẹ jẹ́ kí a mọ OLúWA Ẹ jẹ́ kí a tẹ̀síwájú láti mọ̀ ọ́n. Gẹ́gẹ́ bí oòrùn ṣe ń yọ, Yóò jáde; Yóò tọ̀ wá wá bí òjò bí òjò àkọ́rọ̀ ti ń bomirin ilẹ̀.”
Pín
Kà Hos 6