Hos 6:1-7
Hos 6:1-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ wá, ẹ jẹ ki a yipadà si Oluwa: nitori o ti fà wa ya, on o si mu wa lara da; o ti lù wa, yio si tun wa dì. Lẹhìn ijọ meji, yio tún wa jí: ni ijọ kẹta yio ji wa dide, awa o si wà lãyè niwaju rẹ̀. Nigbana li awa o mọ̀, bi a ba tẹramọ́ ati mọ̀ Oluwa: ati pèse ijadelọ rẹ̀ bi owùrọ: on o si tọ̀ wa wá bi ojò: bi arọ̀kuro ati akọrọ̀ òjo si ilẹ. Efraimu, kili emi o ṣe si ọ? Juda, kili emi o ṣe si ọ? nitori ore nyin dàbi ikuku owurọ̀, ati bi ìri kùtukùtu ti o kọja lọ. Nitorina ni mo ṣe fi ãké ké wọn lati ọwọ awọn woli; mo ti fi ọ̀rọ ẹnu mi pa wọn: ki idajọ rẹ le ri bi imọlẹ ti o jade lọ. Nitori ãnu ni mo fẹ́, ki iṣe ẹbọ; ati ìmọ Ọlọrun jù ọrẹ-ẹbọ sisun lọ. Ṣugbọn bi Adamu nwọn ti dá majẹmu kọja: nibẹ̀ ni nwọn ti ṣẹ̀tan si mi.
Hos 6:1-7 Yoruba Bible (YCE)
Wọn óo wí pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á pada sọ́dọ̀ OLUWA; nítorí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti fà wá ya, sibẹ yóo wò wá sàn; ó ti pa wá lára lóòótọ́, ṣugbọn yóo di ọgbẹ́ wa. Lẹ́yìn ọjọ́ meji, yóo sọ wá jí, ní ọjọ́ kẹta, yóo gbé wa dìde, kí á lè wà láàyè níwájú rẹ̀. Ẹ jẹ́ kí á mọ̀ ọ́n, ẹ jẹ́ kí á tẹ̀síwájú kí á mọ OLUWA. Dídé rẹ̀ dájú bí àfẹ̀mọ́jú; yóo sì pada wá sọ́dọ̀ wa bí ọ̀wààrà òjò, ati bí àkọ́rọ̀ òjò tí ń bomirin ilẹ̀.” Ṣugbọn OLUWA wí pé, “Kí ni kí n ti ṣe ọ́ sí, ìwọ Efuraimu? Kí ni kí n ti ṣe ọ́ sí, ìwọ Juda? Ìfẹ́ yín dàbí ìkùukùu òwúrọ̀, ati bí ìrì tíí yára á gbẹ. Nítorí náà ni mo fi jẹ́ kí àwọn wolii mi ké wọn lulẹ̀, mo ti fi ọ̀rọ̀ ẹnu mi pa wọ́n, ìdájọ́ mi sì yọ bí ìmọ́lẹ̀. Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ni mo fẹ́, kì í ṣe ẹbọ rírú; ìmọ̀ Ọlọrun ni mo bèèrè, kì í ṣe ẹbọ sísun. “Ṣugbọn wọ́n yẹ àdéhùn tí mo bá wọn ṣe, bí Adamu, wọ́n hùwà aiṣododo sí èmi Ọlọrun.
Hos 6:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a padà sọ́dọ̀ OLúWA ó ti fà wá ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ ṣùgbọ́n yóò mú wa láradá Ó ti pa wá lára ṣùgbọ́n yóò dí ojú ọgbẹ́ wa. Lẹ́yìn ọjọ́ méjì, yóò sọ wá jí ní ọjọ́ kẹta yóò mú wa padà bọ̀ sípò kí a ba à le wá gbé níwájú rẹ̀ Ẹ jẹ́ kí a mọ OLúWA Ẹ jẹ́ kí a tẹ̀síwájú láti mọ̀ ọ́n. Gẹ́gẹ́ bí oòrùn ṣe ń yọ, Yóò jáde; Yóò tọ̀ wá wá bí òjò bí òjò àkọ́rọ̀ ti ń bomirin ilẹ̀.” “Kí ni èmi ó ṣe pẹ̀lú rẹ, Efraimu? Kí ni èmi ó ṣe pẹ̀lú rẹ, Juda? Ìfẹ́ rẹ dàbí ìkùùkuu òwúrọ̀ bí ìrì ìdájí tí ó kọjá lọ kíákíá. Nítorí náà ni mo ṣe gé e yín sí wẹ́wẹ́ láti ọwọ́ àwọn wòlíì. Mo pa yín pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ẹnu mi Ìdájọ́ mi tàn bí i mọ̀nàmọ́ná lórí yín Nítorí àánú ni mo fẹ́, kì í ṣe ẹbọ; àti ìmọ̀ Ọlọ́run ju ọrẹ ẹbọ sísun lọ. Bí i Adamu, wọ́n da májẹ̀mú wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́ sí mi níbẹ̀.