Hos 6:1-11

Hos 6:1-11 Yoruba Bible (YCE)

Wọn óo wí pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á pada sọ́dọ̀ OLUWA; nítorí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti fà wá ya, sibẹ yóo wò wá sàn; ó ti pa wá lára lóòótọ́, ṣugbọn yóo di ọgbẹ́ wa. Lẹ́yìn ọjọ́ meji, yóo sọ wá jí, ní ọjọ́ kẹta, yóo gbé wa dìde, kí á lè wà láàyè níwájú rẹ̀. Ẹ jẹ́ kí á mọ̀ ọ́n, ẹ jẹ́ kí á tẹ̀síwájú kí á mọ OLUWA. Dídé rẹ̀ dájú bí àfẹ̀mọ́jú; yóo sì pada wá sọ́dọ̀ wa bí ọ̀wààrà òjò, ati bí àkọ́rọ̀ òjò tí ń bomirin ilẹ̀.” Ṣugbọn OLUWA wí pé, “Kí ni kí n ti ṣe ọ́ sí, ìwọ Efuraimu? Kí ni kí n ti ṣe ọ́ sí, ìwọ Juda? Ìfẹ́ yín dàbí ìkùukùu òwúrọ̀, ati bí ìrì tíí yára á gbẹ. Nítorí náà ni mo fi jẹ́ kí àwọn wolii mi ké wọn lulẹ̀, mo ti fi ọ̀rọ̀ ẹnu mi pa wọ́n, ìdájọ́ mi sì yọ bí ìmọ́lẹ̀. Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ni mo fẹ́, kì í ṣe ẹbọ rírú; ìmọ̀ Ọlọrun ni mo bèèrè, kì í ṣe ẹbọ sísun. “Ṣugbọn wọ́n yẹ àdéhùn tí mo bá wọn ṣe, bí Adamu, wọ́n hùwà aiṣododo sí èmi Ọlọrun. Gileadi ti di ìlú àwọn ẹni ibi, ó kún fún ìpànìyàn. Bí àwọn ọlọ́ṣà tií ba de eniyan, bẹ́ẹ̀ ni àwọn alufaa kó ara wọn jọ, láti paniyan ní ọ̀nà Ṣekemu, wọ́n ń ṣe nǹkan ìtìjú láìbìkítà. Mo rí ohun tí ó burú gan-an ní Israẹli; ìbọ̀rìṣà Efuraimu wà níbẹ̀, Israẹli sì ti ba ara wọn jẹ́. “Ẹ̀yin ará Juda pàápàá, mo ti dá ọjọ́ ìjìyà yín sọ́nà, fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ̀ ń dá.

Hos 6:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a padà sọ́dọ̀ OLúWA ó ti fà wá ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ ṣùgbọ́n yóò mú wa láradá Ó ti pa wá lára ṣùgbọ́n yóò dí ojú ọgbẹ́ wa. Lẹ́yìn ọjọ́ méjì, yóò sọ wá jí ní ọjọ́ kẹta yóò mú wa padà bọ̀ sípò kí a ba à le wá gbé níwájú rẹ̀ Ẹ jẹ́ kí a mọ OLúWA Ẹ jẹ́ kí a tẹ̀síwájú láti mọ̀ ọ́n. Gẹ́gẹ́ bí oòrùn ṣe ń yọ, Yóò jáde; Yóò tọ̀ wá wá bí òjò bí òjò àkọ́rọ̀ ti ń bomirin ilẹ̀.” “Kí ni èmi ó ṣe pẹ̀lú rẹ, Efraimu? Kí ni èmi ó ṣe pẹ̀lú rẹ, Juda? Ìfẹ́ rẹ dàbí ìkùùkuu òwúrọ̀ bí ìrì ìdájí tí ó kọjá lọ kíákíá. Nítorí náà ni mo ṣe gé e yín sí wẹ́wẹ́ láti ọwọ́ àwọn wòlíì. Mo pa yín pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ẹnu mi Ìdájọ́ mi tàn bí i mọ̀nàmọ́ná lórí yín Nítorí àánú ni mo fẹ́, kì í ṣe ẹbọ; àti ìmọ̀ Ọlọ́run ju ọrẹ ẹbọ sísun lọ. Bí i Adamu, wọ́n da májẹ̀mú wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́ sí mi níbẹ̀. Gileadi jẹ́ ìlú àwọn ènìyàn búburú tí ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, a sí ti fi ẹ̀ṣẹ̀ bà á jẹ́. Bí adigunjalè ṣe ń ba ní bùba de àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà, ń parapọ̀; tí wọ́n sì ń pànìyàn lójú ọ̀nà tó lọ sí Ṣekemu, tí wọ́n sì ń dá ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti ni lójú. Mo ti rí ohun tó ba ni lẹ́rù ní ilé Israẹli. Níbẹ̀ Efraimu, fi ara rẹ̀ fún àgbèrè Israẹli sì di aláìmọ́. “Àti fún ìwọ, Juda A ti yan ọjọ́ ìkórè rẹ.