Hos 5:1-15
Hos 5:1-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ gbọ́ eyi, ẹnyin alufa: si tẹtilelẹ ẹnyin ile Israeli; ki ẹ si gbọ́, ile ọba na; nitori idajọ kàn nyin, nitoriti ẹnyin ti jẹ ẹgẹ́ si Mispa, àwọn ti a nà silẹ lori Tabori. Awọn ọlọ̀tẹ si jinlẹ ni pipanirun, emi o jẹ olùbawi gbogbo wọn. Emi mọ̀ Efraimu, Israeli kò si pamọ́ fun mi: nitori nisisiyi, Efraimu, iwọ ṣe agbère, Israeli si dibajẹ. Iṣe wọn kì o jọ̀wọ wọn lati yipadà si Ọlọrun wọn: nitori ẹmi agbère wà lãrin wọn, nwọn kò si mọ̀ Oluwa. A si rẹ̀ ogo Israeli silẹ loju ara rẹ̀; nitorina ni Israeli ati Efraimu yio ṣubu ninu aiṣedẽde wọn, Juda yio si ṣubu pẹlu wọn. Nwọn o lọ ti awọn ti agbo-ẹran wọn ati ọ̀wọ ẹran wọn lati wá Oluwa: ṣugbọn nwọn kì o ri i, on ti fà ara rẹ̀ sẹhìn kuro lọdọ wọn. Nwọn ti hùwa arekerekè si Oluwa: nitori nwọn ti bi ajèji ọmọ: nisisiyi li oṣù titun yio jẹ wọn run, pẹlu ipin wọn. Ẹ fun korneti ni Gibea, ati ipè ni Rama; kigbe kikan ni Bet-afeni, lẹhìn rẹ, iwọ Benjamini. Efraimu yio di ahoro li ọjọ ibawi: ninu awọn ẹyà Israeli li emi ti fi ohun ti o wà nitõtọ hàn. Awọn olori Juda dàbi awọn ti o yẹ̀ oju àla: lara wọn li emi o tú ibinu mi si bi omi. A tẹ̀ ori Efraimu ba, a si ṣẹgun rẹ̀ ninu idajọ, nitoriti on mọ̃mọ̀ tẹ̀le ofin na. Nitorina ni emi o ṣe dabi kòkoro aṣọ si Efraimu, ati si ile Juda bi idin. Nigbati Efraimu ri arùn rẹ̀, ti Juda si ri ọgbẹ́ rẹ̀, nigbana ni Efraimu tọ̀ ara Assiria lọ, o si ranṣẹ si ọba Jarebu; ṣugbọn on kò le mu ọ lara da, bẹ̃ni kò le wò ọgbẹ́ rẹ jiná. Nitori emi o dàbi kiniun si Efraimu, ati bi ọmọ kiniun si ile Juda, emi, ani emi o fàya, emi o si lọ, emi o mu lọ, ẹnikẹni kì yio si gbà a silẹ. Emi o padà lọ si ipò mi, titi nwọn o fi jẹwọ ẹ̀ṣẹ wọn, ti nwọn o si wá oju mi: ninu ipọnju wọn, nwọn o wá mi ni kùtukùtu.
Hos 5:1-15 Yoruba Bible (YCE)
“Ẹ gbọ́, ẹ̀yin alufaa! Ẹ tẹ́tí sílẹ̀, ẹ̀yin ọmọ Israẹli ati ẹ̀yin ìdílé ọba! Ẹ̀yin ni ìdájọ́ náà dé bá; nítorí ẹ dàbí tàkúté ní Misipa, ati bí àwọ̀n tí a ta sílẹ̀ lórí òkè Tabori. Wọ́n ti gbẹ́ kòtò jíjìn ní ìlú Ṣitimu; ṣugbọn n óo jẹ wọ́n níyà. Mo mọ Efuraimu, bẹ́ẹ̀ ni Israẹli kò ṣàjèjì sí mi; nisinsinyii, ìwọ Efuraimu ti ṣe àgbèrè ẹ̀sìn, Israẹli sì ti di aláìmọ́.” Gbogbo ibi tí wọn ń ṣe, kò jẹ́ kí wọ́n lè pada sọ́dọ̀ Ọlọrun wọn, nítorí pé ọkàn wọn kún fún ẹ̀mí àgbèrè, wọn kò sì mọ OLUWA. Ìgbéraga Israẹli hàn kedere lójú rẹ̀; Efuraimu yóo kọsẹ̀, yóo sì ṣubú ninu ìwà burúkú rẹ̀, Juda náà yóo ṣubú pẹlu wọn. Wọn yóo mú mààlúù ati aguntan wá, láti fi wá ojurere OLUWA, ṣugbọn wọn kò ní rí i; nítorí pé, ó ti fi ara pamọ́ fún wọn. Wọ́n ti hùwà aiṣootọ sí OLUWA; nítorí pé wọ́n ti bí ọmọ àjèjì. Oṣù tuntun ni yóo run àtàwọn, àtoko wọn. Ẹ fọn fèrè ní Gibea, ẹ fọn fèrè ogun ní Rama, ẹ pariwo ogun ní Betafeni, ogun dé o, ẹ̀yin ará Bẹnjamini! Efuraimu yóo di ahoro ní ọjọ́ ìjìyà; mo ti fi ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ dájúdájú hàn, láàrin àwọn ẹ̀yà Israẹli. OLUWA wí pé: “Àwọn olórí ní Juda dàbí àwọn tí wọn ń yí ààlà ilẹ̀ pada, n óo da ibinu mi sórí wọn, bí ẹni da omi. Ìyà ń jẹ Efuraimu, ìdájọ́ ìparun sì ti dé bá a, nítorí pé, ó ti pinnu láti máa tẹ̀lé ohun asán. Nítorí náà, mo dàbí kòkòrò ajẹnirun sí Efuraimu, ati bí ìdíbàjẹ́ sí Juda. “Nígbà tí Efuraimu rí àìsàn rẹ̀, tí Juda sì rí ọgbẹ́ rẹ̀, Efuraimu sá tọ Asiria lọ, ó sì ranṣẹ sí ọba ńlá ibẹ̀. Ṣugbọn kò lè wo àìsàn Israẹli tabi kí ó wo ọgbẹ́ rẹ̀ sàn. Bíi kinniun ni n óo rí sí Efuraimu, n óo sì fò mọ́ Juda bí ọ̀dọ́ kinniun. Èmi fúnra mi ni n óo fà wọ́n ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, n óo sì kúrò níbẹ̀. N óo kó wọn lọ, kò sì ní sí ẹni tí yóo lè gbà wọ́n sílẹ̀. “N óo pada sí ibùgbé mi títí wọn yóo fi mọ ẹ̀bi wọn, tí wọn yóo sì máa wá mi nígbà tí ojú bá pọ́n wọn.”
Hos 5:1-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yìn àlùfáà! Ẹ fetísílẹ̀ ẹ̀yin ọmọ Israẹli! Ẹ gbọ́, ẹ̀yìn ilé ọba! Ìdájọ́ yìí kàn yín: Ẹ ti jẹ́ ẹ̀bìtì ní Mispa àwọ̀n ti a nà sílẹ̀ lórí Tabori Àwọn ọlọ̀tẹ̀ ti gbilẹ̀ nínú ìpànìyàn gbogbo wọn ni èmi ó bá wí, Mo mọ ohun gbogbo nípa Efraimu Israẹli kò sì pamọ́ fún mi Efraimu, ní báyìí ó ti ṣe àgbèrè Israẹli sì ti díbàjẹ́. “Ìṣe wọn kò gbà wọ́n láààyè láti padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọn. Ẹ̀mí àgbèrè wà ni ọkàn wọn, wọn kò sì mọ OLúWA. Ìgbéraga Israẹli ń jẹ́rìí lé wọn; Àwọn ọmọ Israẹli, àti Efraimu pàápàá kọsẹ̀ nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Juda náà sì kọsẹ̀ pẹ̀lú wọn. Nígbà tí wọ́n bá lọ pẹ̀lú agbo ẹran àti ọ̀wọ́ ẹran wọn láti wá OLúWA, wọn kò ní rí i, ó ti yọ ara rẹ̀ kúrò láàrín wọn. Wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́ sí OLúWA wọ́n sì bí àwọn àjèjì ọmọ. Nísinsin yìí, ọdún oṣù tuntun wọn, ni yóò pa wọn run pẹ̀lú ìpín wọn. “Fọn fèrè ní Gibeah, kí ẹ sì fun ìpè ní Rama. Ẹ pariwo ogun ní Beti-Afeni máa wárìrì, ìwọ Benjamini. Efraimu yóò di ahoro ní ọjọ́ ìbáwí láàrín àwọn ẹ̀yà Israẹli Mo sọ ohun tí ó dájú. Àwọn olórí Juda dàbí àwọn tí í máa yí òkúta ààlà kúrò. Èmi ó tú ìbínú gbígbóná mi lé wọn lórí bí ìkún omi. A ni Efraimu lára, A sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ ní ìdájọ́ nítorí pé, ó pinnu láti tẹ̀lé òrìṣà Mo dàbí kòkòrò aṣọ sí Efraimu Mo sì dàbí ìdin ara Juda. “Nígbà ti Efraimu ri àìsàn rẹ̀, tí Juda sì rí ojú egbò rẹ̀ ni Efraimu bá tọ ará Asiria lọ, ó sì ránṣẹ́ sí ọba ńlá náà fún ìrànlọ́wọ́ Ṣùgbọ́n kò le è wò ó sàn bẹ́ẹ̀ ni kò le wo ojú egbò rẹ̀ jinná Nítorí pé, èmi ó dàbí kìnnìún sí Efraimu, bí i kìnnìún ńlá sí ilé Juda. Èmi ó fà wọ́n ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ èmi ó sì lọ; Èmi ó gbé wọn lọ, láìsí ẹni tí yóò gbà wọ́n sílẹ̀. Nígbà náà ni èmi ó padà lọ sí ààyè mi títí di ìgbà tí wọn ó fi gbà pé àwọn jẹ̀bi wọn yóò sì wá ojú mi nínú ìpọ́njú wọn, wọn ó fi ìtara wá mi.”