Hos 4:1-5
Hos 4:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin ọmọ Israeli; nitori Oluwa ni ẹjọ kan ba awọn ara ilẹ na wi, nitoriti kò si otitọ, tabi ãnu, tabi ìmọ Ọlọrun ni ilẹ na. Nipa ibura, ati eke, ati ipani, ati olè, ati iṣe panṣaga, nwọn gbìjà, ẹ̀jẹ si nkàn ẹ̀jẹ. Nitorina ni ilẹ na yio ṣe ṣọ̀fọ, ati olukuluku ẹniti ngbé inu rẹ̀ yio rọ, pẹlu awọn ẹranko igbẹ, ati pẹlu awọn ẹiyẹ oju ọrun; a o si mu awọn ẹja inu okun kuro pẹlu. Ṣugbọn má jẹ ki ẹnikẹni ki o jà, tabi ki o ba ẹnikeji rẹ̀ wi: nitori awọn enia rẹ dabi awọn ti mba alufa jà. Iwọ o si ṣubu li ọ̀san, woli yio si ṣubu pẹlu rẹ li alẹ, emi o si ké iya rẹ kuro.
Hos 4:1-5 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA, ẹ̀yin ọmọ Israẹli; OLUWA fi ẹ̀sùn kan gbogbo àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ Israẹli pé, “Kò sí òtítọ́, tabi àánú, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìmọ̀ Ọlọrun ní ilẹ̀ náà, àfi ìbúra èké ati irọ́ pípa; ìpànìyàn, olè jíjà ati àgbèrè ni ó pọ̀ láàrin wọn. Wọ́n ń yẹ àdéhùn, wọ́n ń paniyan léraléra. Nítorí náà, ilẹ̀ náà ń ṣọ̀fọ̀, gbogbo àwọn tí wọn ń gbé ibẹ̀ ń jìyà, àwọn ẹranko, àwọn ẹyẹ, ati àwọn ẹja sì ń ṣègbé.” Ọlọrun ní, Kí ẹnikẹ́ni má ṣe jiyàn, ẹ kò sì gbọdọ̀ ka ẹ̀sùn sí ẹnikẹ́ni lẹ́sẹ̀, nítorí pé ẹ̀yin alufaa gan-an ni mò ń fi ẹ̀sùn kàn. Nítorí ẹ óo fẹsẹ̀ kọ lojumọmọ, ẹ̀yin wolii pàápàá yóo kọsẹ̀ lóru, n óo sì pa Israẹli, ìyá yín run.
Hos 4:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLúWA ẹ̀yin ọmọ Israẹli, nítorí pé OLúWA fi ẹ̀sùn kan ẹ̀yin tí ń gbé ní ilẹ̀ náà. “Kò sí ìwà òtítọ́, kò sí ìfẹ́ Kò sí ìmọ̀ Ọlọ́run ní ilẹ̀ náà Àfi èpè, irọ́ pípa àti ìpànìyàn olè jíjà àti panṣágà. Wọ́n rú gbogbo òfin, ìtàjẹ̀ sílẹ̀ sì ń gorí ìtàjẹ̀ sílẹ̀. Nítorí èyí, ilẹ̀ náà ń ṣọ̀fọ̀, gbogbo olùgbé ibẹ̀ sì ń ṣòfò dànù. Ẹranko igbó àti ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹja inú omi ló ń kú. “Ṣùgbọ́n kí ẹnikẹ́ni má ṣe mú ẹ̀sùn wá, kí ẹnìkan má sì ṣe fi ẹ̀sùn kan ẹnìkejì nítorí àwọn ènìyàn rẹ̀ dàbí àwọn ti ń fi ẹ̀sùn kan àlùfáà Ẹ ń ṣubú lọ́sàn án àti lóru àwọn wòlíì yín sì ń ṣubú pẹ̀lú yín Èmi ó pa ìyá rẹ run