Hos 4:1-17
Hos 4:1-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin ọmọ Israeli; nitori Oluwa ni ẹjọ kan ba awọn ara ilẹ na wi, nitoriti kò si otitọ, tabi ãnu, tabi ìmọ Ọlọrun ni ilẹ na. Nipa ibura, ati eke, ati ipani, ati olè, ati iṣe panṣaga, nwọn gbìjà, ẹ̀jẹ si nkàn ẹ̀jẹ. Nitorina ni ilẹ na yio ṣe ṣọ̀fọ, ati olukuluku ẹniti ngbé inu rẹ̀ yio rọ, pẹlu awọn ẹranko igbẹ, ati pẹlu awọn ẹiyẹ oju ọrun; a o si mu awọn ẹja inu okun kuro pẹlu. Ṣugbọn má jẹ ki ẹnikẹni ki o jà, tabi ki o ba ẹnikeji rẹ̀ wi: nitori awọn enia rẹ dabi awọn ti mba alufa jà. Iwọ o si ṣubu li ọ̀san, woli yio si ṣubu pẹlu rẹ li alẹ, emi o si ké iya rẹ kuro. A ké awọn enia mi kuro nitori aini ìmọ: nitori iwọ ti kọ̀ ìmọ silẹ, emi o si kọ̀ ọ, ti iwọ kì yio ṣe alufa mi mọ: niwọ̀n bi iwọ ti gbagbe ofin Ọlọrun rẹ, emi pẹlu o gbagbe awọn ọmọ rẹ. Bi a ti mu wọn pọ̀ si i to, bẹ̃ na ni nwọn si dẹ̀ṣẹ si mi to: nitorina emi o yi ogo wọn padà si itìju. Nwọn jẹ ẹ̀ṣẹ awọn enia mi, nwọn si gbe ọkàn wọn si aiṣedẽde wọn. Yio si ṣe, gẹgẹ bi enia, bẹ̃li alufa: emi o si bẹ̀ wọn wò nitori ọ̀na wọn, emi o si san èrè iṣẹ wọn padà fun wọn. Nwọn o si jẹ, nwọn kì o si yó: nwọn o ṣe agbère, nwọn kì o si rẹ̀: nitori nwọn ti fi ati-kiyesi Oluwa silẹ. Agbère ati ọti-waini, ati ọti-waini titun a ma gbà enia li ọkàn. Awọn enia mi mbère ìmọ lọwọ igi wọn, ọpá wọn si nfi hàn fun wọn: nitori ẹmi agbère ti mu wọn ṣìna, nwọn si ti ṣe agbère lọ kuro labẹ Ọlọrun wọn. Nwọn rubọ lori awọn oke-nla, nwọn si sun turari lori awọn oke kékèké, labẹ igi oaku ati igi poplari ati igi ẹlmu, nitoriti ojìji wọn dara: nitorina awọn ọmọbinrin nyin yio ṣe agbère, ati awọn afẹ́sọnà nyin yio ṣe panṣagà. Emi kì yio ba awọn ọmọbinrin nyin wi nigbati nwọn ba ṣe agbère, tabi awọn afẹ́sọnà nyin nigbati nwọn ba ṣe panṣagà: nitori nwọn yà si apakan pẹlu awọn agbère, nwọn si mba awọn panṣagà rubọ̀: nitorina awọn enia ti kò ba moye yio ṣubu. Bi iwọ, Israeli, ba ṣe agbère, máṣe jẹ ki Juda ṣẹ̀; ẹ má si wá si Gilgali, bẹ̃ni ki ẹ má si goke lọ si Bet-afeni, bẹ̃ni ki ẹ má si bura pe, Oluwa mbẹ. Nitori Israeli ṣe agidi bi ọmọ malu alagidi; nisisiyi Oluwa yio bọ́ wọn bi ọdọ-agùtan ni ibi ayè nla. Efraimu dapọ̀ mọ òriṣa: jọwọ rẹ̀ si.
Hos 4:1-17 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA, ẹ̀yin ọmọ Israẹli; OLUWA fi ẹ̀sùn kan gbogbo àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ Israẹli pé, “Kò sí òtítọ́, tabi àánú, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìmọ̀ Ọlọrun ní ilẹ̀ náà, àfi ìbúra èké ati irọ́ pípa; ìpànìyàn, olè jíjà ati àgbèrè ni ó pọ̀ láàrin wọn. Wọ́n ń yẹ àdéhùn, wọ́n ń paniyan léraléra. Nítorí náà, ilẹ̀ náà ń ṣọ̀fọ̀, gbogbo àwọn tí wọn ń gbé ibẹ̀ ń jìyà, àwọn ẹranko, àwọn ẹyẹ, ati àwọn ẹja sì ń ṣègbé.” Ọlọrun ní, Kí ẹnikẹ́ni má ṣe jiyàn, ẹ kò sì gbọdọ̀ ka ẹ̀sùn sí ẹnikẹ́ni lẹ́sẹ̀, nítorí pé ẹ̀yin alufaa gan-an ni mò ń fi ẹ̀sùn kàn. Nítorí ẹ óo fẹsẹ̀ kọ lojumọmọ, ẹ̀yin wolii pàápàá yóo kọsẹ̀ lóru, n óo sì pa Israẹli, ìyá yín run. Àwọn eniyan mi ń ṣègbé nítorí àìsí ìmọ̀; nítorí pé ẹ̀yin alufaa ti kọ ìmọ̀ mi sílẹ̀, èmi náà yóo kọ̀ yín ní alufaa mi. Nítorí pé ẹ ti gbàgbé òfin Ọlọrun yín, èmi náà yóo gbàgbé àwọn ọmọ yín. “Bí ẹ̀yin alufaa ti ń pọ̀ sí i, ni ẹ̀ṣẹ̀ yín náà ń pọ̀ sí i, n óo yí ògo wọn pada sí ìtìjú. Ẹ̀ ń fi ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan mi wá oúnjẹ fún ara yín, ẹ sì ń mú kí wọ́n máa dá ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀ Ìyà kan náà ni ẹ̀yin alufaa ati àwọn eniyan yóo jẹ, n óo jẹ yín níyà nítorí ìwà burúkú yín, n óo sì gbẹ̀san lára yín nítorí ìṣe yín. Ẹ óo máa jẹun, ṣugbọn ẹ kò ní yó; Ẹ óo máa ṣe àgbèrè ẹ̀sìn, ṣugbọn ẹ kò ní pọ̀ sí i; nítorí ẹ ti kọ èmi Ọlọrun sílẹ̀ ẹ sì yipada sí ìwà ìbọkúbọ.” OLUWA ní, “Ọtí waini ati waini tuntun ti ra àwọn eniyan mi níyè. Wọ́n ń wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ igi gbígbẹ́, ọ̀pá wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún wọn. Ẹ̀mí àgbèrè ẹ̀sìn ti mú wọn ṣáko, wọ́n ti kọ Ọlọrun wọn sílẹ̀ láti máa bọ ìbọkúbọ. Wọ́n ń rúbọ lórí òkè gíga, wọ́n ń sun turari lórí òkè kéékèèké, ati lábẹ́ igi oaku, ati igi populari ati igi terebinti, nítorí òjìji abẹ́ wọn tutù. Nítorí náà ni àwọn ọmọbinrin yín ṣe di aṣẹ́wó, àwọn aya yín sì di alágbèrè. Ṣugbọn n kò ní jẹ àwọn ọmọbinrin yín níyà nígbà tí wọ́n bá ń ṣe aṣẹ́wó, tabi kí n jẹ àwọn aya yín níyà nígbà tí wọ́n bá ṣe àgbèrè; nítorí pé, àwọn ọkunrin yín pàápàá ń bá àwọn aṣẹ́wó lòpọ̀, wọ́n sì ń bá àwọn aṣẹ́wó ilé oriṣa rúbọ. Àwọn tí wọn kò bá ní ìmọ̀ yóo sì parun. “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ò ń ṣe àgbèrè ẹ̀sìn, ìwọ Israẹli, má kó ẹ̀bi bá Juda. Má wọ Giligali lọ bọ̀rìṣà, má sì gòkè lọ sí Betafeni, má sì lọ búra níbẹ̀ pé, ‘Bí OLUWA tí ń bẹ.’ Israẹli ń ṣe agídí bí ọ̀dọ́ mààlúù tí ó ya olóríkunkun; ṣe OLUWA lè máa bọ́ wọn bí aguntan nisinsinyii lórí pápá tí ó tẹ́jú. Ìbọ̀rìṣà ti wọ Efuraimu lẹ́wù, ẹ fi wọ́n sílẹ̀.
Hos 4:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLúWA ẹ̀yin ọmọ Israẹli, nítorí pé OLúWA fi ẹ̀sùn kan ẹ̀yin tí ń gbé ní ilẹ̀ náà. “Kò sí ìwà òtítọ́, kò sí ìfẹ́ Kò sí ìmọ̀ Ọlọ́run ní ilẹ̀ náà Àfi èpè, irọ́ pípa àti ìpànìyàn olè jíjà àti panṣágà. Wọ́n rú gbogbo òfin, ìtàjẹ̀ sílẹ̀ sì ń gorí ìtàjẹ̀ sílẹ̀. Nítorí èyí, ilẹ̀ náà ń ṣọ̀fọ̀, gbogbo olùgbé ibẹ̀ sì ń ṣòfò dànù. Ẹranko igbó àti ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹja inú omi ló ń kú. “Ṣùgbọ́n kí ẹnikẹ́ni má ṣe mú ẹ̀sùn wá, kí ẹnìkan má sì ṣe fi ẹ̀sùn kan ẹnìkejì nítorí àwọn ènìyàn rẹ̀ dàbí àwọn ti ń fi ẹ̀sùn kan àlùfáà Ẹ ń ṣubú lọ́sàn án àti lóru àwọn wòlíì yín sì ń ṣubú pẹ̀lú yín Èmi ó pa ìyá rẹ run Àwọn ènìyàn mi ń ṣègbé nítorí pé wọn kò ní ìmọ̀. “Nítorí pé ẹ ti kọ ìmọ̀ sílẹ̀. Èmi náà kọ̀ yín ní àlùfáà mi; nítorí pé ẹ ti kọ òfin Ọlọ́run yín sílẹ̀ Èmi náà yóò gbàgbé àwọn ọmọ yín. Bí àwọn àlùfáà ṣe ń pọ̀ sí i bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ń dẹ́ṣẹ̀ sí mi. Wọ́n yí ògo mi padà sí ohun ìtìjú wọ́n ń jẹun nípa ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn mi Wọ́n sì ń gbádùn nínú ìwà búburú wọn. Yóò sì ṣe gẹ́gẹ́: bí ènìyàn ṣe rí náà ni àwọn àlùfáà rí Èmi ó jẹ gbogbo wọn ní yà nítorí ọ̀nà wọn. Èmi ó sì san án fún wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn. “Wọn ó máa jẹun ṣùgbọ́n wọn kò ní yó; wọn ó ṣe àgbèrè ṣùgbọ́n, wọn kò ni pọ̀ sí i, nítorí pé wọ́n ti kọ OLúWA sílẹ̀ ‘Wọ́n sì ti fi ara wọn’ fún àgbèrè, wọ́n fi ara wọn fún wáìnì àtijọ́ àti tuntun èyí tó gba òye àwọn ènìyàn mi sọnù Wọ́n ń gba ìmọ̀ràn lọ́wọ́ ère igi ọ̀pá igi sì ń dá wọn lóhùn. Ẹ̀mí àgbèrè ti mú wọn ṣìnà wọ́n sì jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run wọn. Wọ́n ń rú ẹbọ lórí àwọn òkè ńlá, Wọ́n sì ń sun ọrẹ tùràrí lórí àwọn òkè kékeré Lábẹ́ igi óákù, àti igi Poplari àti igi ẹlimuati onírúurú igi tí ìbòjú rẹ̀ dára Nítorí náà àwọn ọmọbìnrin yín yóò ṣe àgbèrè àti àwọn àfẹ́sọ́nà yín yóò ṣe àgbèrè. “Èmi kò ní jẹ àwọn ọmọbìnrin yín ní yà nígbà tí wọ́n bá ṣe àgbèrè tàbí àwọn àfẹ́sọ́nà ọmọ yín, nígbà tí wọ́n bá ṣe àgbèrè nítorí pé àwọn ọkùnrin pàápàá ń bá alágbèrè kẹ́gbẹ́. Wọ́n sì ń rú ẹbọ pẹ̀lú àwọn alágbèrè ojúbọ òrìṣà. Nítorí náà, ènìyàn tí kò bá ní òye yóò parun! “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o ṣe àgbèrè ìwọ Israẹli Ìdájọ́ yìí wà fún un yín Ẹ má ṣe jẹ́ kí Juda di ẹlẹ́bi. “Ẹ má ṣe lọ sí Gilgali. Ẹ má sì ṣe gòkè lọ sí Beti-Afeni ẹ má sì búra pé, ‘Bí OLúWA ti wà láààyè nítòótọ́!’ Àwọn ọmọ Israẹli ṣe agídí bí alágídí ọmọ màlúù Báwo wá ni OLúWA ṣe fẹ́ bọ́ wọn bí àgùntàn ní pápá oko tútù? Efraimu ti darapọ̀ mọ́ òrìṣà Ẹ fi sílẹ̀!