Hos 3:4-5
Hos 3:4-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori ọjọ pupọ̀ li awọn ọmọ Israeli yio gbe li aini ọba, ati li aini olori, ati li aini ẹbọ, li aini ere, ati li aini awòaiyà, ati li aini tẹrafimu. Lẹhìn na awọn ọmọ Israeli yio padà, nwọn o si wá Oluwa Ọlọrun wọn, ati Dafidi ọba wọn; nwọn o si bẹ̀ru Oluwa, ati ore rẹ̀ li ọjọ ikẹhìn.
Hos 3:4-5 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí náà, àwọn ọmọ Israẹli yóo wà fún ọjọ́ gbọọrọ láìní ọba tabi olórí láìsí ẹbọ tabi ère, láìsí aṣọ efodu tabi ère terafimu. Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Israẹli yóo pada tọ OLUWA Ọlọrun wọn, ati Dafidi, ọba wọn lọ. Wọn yóo fi ìbẹ̀rù wá sọ́dọ̀ OLUWA, wọn yóo sì gba oore rẹ̀ ní ọjọ́ ìkẹyìn.
Hos 3:4-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí pé àwọn ọmọ Israẹli yóò wà fún ọjọ́ pípẹ́ láìní ọba tàbí olórí, láìsí ìrúbọ tàbí pẹpẹ mímọ́, láìsí àlùfáà tàbí òrìṣà kankan. Lẹ́yìn èyí ni àwọn ọmọ Israẹli yóò padà láti wá OLúWA Ọlọ́run wọn àti Dafidi ọba wọn. Wọn yóò sì wá síwájú OLúWA pẹ̀lú ẹ̀rù, wọn ó sì jọ̀wọ́ ara wọn fún OLúWA àti ìbùkún rẹ̀ ní ọjọ́ ìkẹyìn.