Ṣe àfiwé gbogbo èyà
Hos 3:4YBCV(Bibeli Mimọ)
Nitori ọjọ pupọ̀ li awọn ọmọ Israeli yio gbe li aini ọba, ati li aini olori, ati li aini ẹbọ, li aini ere, ati li aini awòaiyà, ati li aini tẹrafimu.
Hos 3:4BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí pé àwọn ọmọ Israẹli yóò wà fún ọjọ́ pípẹ́ láìní ọba tàbí olórí, láìsí ìrúbọ tàbí pẹpẹ mímọ́, láìsí àlùfáà tàbí òrìṣà kankan.
Hos 3:4YCE(Yoruba Bible)
Nítorí náà, àwọn ọmọ Israẹli yóo wà fún ọjọ́ gbọọrọ láìní ọba tabi olórí láìsí ẹbọ tabi ère, láìsí aṣọ efodu tabi ère terafimu.