Hos 3:1-4
Hos 3:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA sí wi fun mi pe, Tun lọ, fẹ́ obinrin kan ti iṣe olùfẹ́ ọrẹ rẹ̀, ati panṣagà, gẹgẹ bi ifẹ Oluwa si awọn ọmọ Israeli, ti nwò awọn ọlọrun miràn, ti nwọn si nfẹ́ akàra eso àjara. Bẹ̃ni mo rà a fun ara mi ni fadakà mẹ̃dogun, ati homeri barli kan pẹlu ãbọ̀: Mo si wi fun u pe, Iwọ o ba mi gbe li ọjọ pupọ̀; iwọ kì yio si hùwa agbère, iwọ kì yio si jẹ ti ọkunrin miràn: bẹ̃li emi o jẹ tirẹ pẹlu. Nitori ọjọ pupọ̀ li awọn ọmọ Israeli yio gbe li aini ọba, ati li aini olori, ati li aini ẹbọ, li aini ere, ati li aini awòaiyà, ati li aini tẹrafimu.
Hos 3:1-4 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA tún sọ fún mi pé: “Lọ fẹ́ aya tí ń ṣe àgbèrè pada, kí o fẹ́ràn rẹ̀, bí mo ti fẹ́ràn Israẹli, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n yipada sí ọlọrun mìíràn, wọ́n sì fẹ́ràn láti máa jẹ àkàrà tí ó ní èso resini ninu.” Nítorí náà, mo rà á ní ṣekeli fadaka mẹẹdogun ati ìwọ̀n ọkà baali kan. Mo sì sọ fún un pé, “O gbọdọ̀ wà fún èmi nìkan fún ọjọ́ gbọọrọ láìṣe àgbèrè, láì sì lọ fẹ́ ọkunrin mìíràn; èmi náà yóo sì jẹ́ tìrẹ nìkan.” Nítorí náà, àwọn ọmọ Israẹli yóo wà fún ọjọ́ gbọọrọ láìní ọba tabi olórí láìsí ẹbọ tabi ère, láìsí aṣọ efodu tabi ère terafimu.
Hos 3:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA sì wí fún mi pé, “Tun lọ fẹ́ obìnrin kan tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀, àti panṣágà, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ OLúWAsì àwọn ọmọ Israẹli tí ń wo àwọn ọlọ́run mìíràn, tí wọ́n sì ń fẹ́ àkàrà èso àjàrà.” Nítorí náà, mo sì rà á padà ní ṣékélì fàdákà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àti homeri kan àti lẹ́tékì barle kan. Mo sì sọ fún un pé, “Ìwọ gbọdọ̀ máa gbé pẹ̀lú mi fún ọjọ́ pípẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe àgbèrè mọ́ tàbí kí o fẹ́ ọkùnrin mìíràn, èmi náà yóò sì gbé pẹ̀lú rẹ.” Nítorí pé àwọn ọmọ Israẹli yóò wà fún ọjọ́ pípẹ́ láìní ọba tàbí olórí, láìsí ìrúbọ tàbí pẹpẹ mímọ́, láìsí àlùfáà tàbí òrìṣà kankan.