Hos 2:2-7
Hos 2:2-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ ba iya nyin wijọ, ẹ wijọ; nitori on kì iṣe aya mi, bẹ̃ni emi kì iṣe ọkọ rẹ̀: nitori na jẹ ki on ki o mu gbogbo agberè rẹ̀ kuro ni iwaju rẹ̀, ati gbogbo panṣaga rẹ̀ kuro larin ọyàn rẹ̀. Ki emi má ba tú u si ihòho, emi o si gbe e kalẹ bi ọjọ ti a bi i, emi o si ṣe e bi ijù, emi o si gbe e kalẹ bi ilẹ gbigbẹ, emi o si fi ongbẹ pa a kú. Emi kì yio si ṣãnu fun awọn ọmọ rẹ̀; nitoriti nwọn jẹ́ ọmọ agbère. Nitoriti iya wọn ti hùwa agbère: ẹniti o loyun wọn ti ṣe ohun itiju: nitori ti o wipe, Emi o tun tọ̀ awọn ayànfẹ́ mi lẹhìn, ti nfun mi ni onjẹ mi ati omi mi, irun agùtan mi ati ọgbọ̀ mi, ororo mi, ati ohun mimu mi. Nitorina kiyesi i, emi o fi ẹgún sagbàra yi ọ̀na rẹ̀ ka, emi o si mọ odi, ti on kì yio fi ri ọ̀na rẹ̀ mọ. On o si lepa awọn ayànfẹ́ rẹ̀, ṣugbọn kì yio le ba wọn; on o si wá wọn, ṣugbọn kì yio ri wọn: nigbana ni yio wipe, Emi o padà tọ̀ ọkọ mi iṣãju lọ; nitoriti o sàn fun mi nigbana jù ti isisiyi lọ.
Hos 2:2-7 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ bá ìyá yín sọ̀rọ̀; nítorí pé kì í ṣe aya mi mọ́, ati pé èmi náà kì í sì í ṣe ọkọ rẹ̀ mọ́. Ẹ sọ fún un pé kí ó má ṣe àgbèrè mọ́, kí ó sì fi ìṣekúṣe rẹ̀ sílẹ̀. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, n óo tú u sí ìhòòhò, n óo ṣe é bí ìgbà tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí i. N óo ṣe é bí aṣálẹ̀, àní, bí ilẹ̀ tí ó gbẹ, n óo sì fi òùngbẹ gbẹ ẹ́ pa. N kò ní ṣàánú àwọn ọmọ rẹ̀, nítorí ọmọ àgbèrè ni wọ́n. Nítorí alágbèrè ni ìyá wọn, ẹni tí ó bí wọn sì ti hùwà ainitiju. Òun fúnrarẹ̀ sọ pé, “N óo sá tẹ̀lé àwọn olólùfẹ́ mi, àwọn tí wọn ń fún mi ní oúnjẹ ati omi, ati aṣọ òtútù, ati aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ funfun, ati òróró olifi ati ọtí.” Nítorí náà, n óo fi ẹ̀gún ṣe ọgbà yí i ká; n óo mọ odi yí i ká, tí kò fi ní rí ọ̀nà jáde. Yóo sá tẹ̀lé àwọn olólùfẹ́ rẹ̀, ṣugbọn kò ní lè bá wọn; yóo wá wọn káàkiri pẹlu ìtara, ṣugbọn kò ní rí wọn. Yóo wá wí nígbà náà pé, “N óo pada sọ́dọ̀ ọkọ mi àárọ̀, nítorí ó dára fún mi lọ́dọ̀ rẹ̀ ju ti ìsinsìnyìí lọ.”
Hos 2:2-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ẹ bá ìyá yín wí, ẹ bá a wí, nítorí pé kì í ṣe ìyàwó mi, Èmi náà kì í sì í ṣe ọkọ rẹ̀. Jẹ́ kí ó yọ àgbèrè rẹ̀ kúrò lójú rẹ̀ àti àìṣòótọ́ kúrò ní àyà rẹ̀. Àìṣe bẹ́ẹ̀ èmi yóò tú u sí ìhòhò Èmi yóò sì gbé e kalẹ̀ bí ọjọ́ tí a bí i. Èmi yóò ṣe ọ́ bí i aṣálẹ̀ ilẹ̀, Èmi yóò sì sọ ọ́ di ìyàngbẹ ilẹ̀ Èmi yóò sì fi òǹgbẹ gbẹ ẹ́. Èmi kò ní fi àánú mi hàn sí àwọn ọmọ rẹ̀ nítorí ọmọ àgbèrè ni wọ́n jẹ́ Nítorí ìyá wọn ti hùwà àgbèrè, ó sì lóyún wọn nínú ìtìjú. Ó wí pé, ‘èmi ó tún tọ́ àwọn àyànfẹ́ mi lẹ́yìn, tó ń fún mi ní oúnjẹ àti omi, ní irun àgùntàn mi àti ọ̀gbọ̀ mi, òróró mi àti ohun mímu mi.’ Nítorí náà, èmi ó fi ẹ̀gún dì í lọ́nà Èmi ó mọ odi yí i ká kí ó má ba à rọ́nà lọ. Yóò sáré lé àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ ṣùgbọ́n kò ní bá wọn; Yóò wá wọn ṣùgbọ́n kò ní rí wọn. Nígbà náà ni yóò sọ pé, ‘Èmi ó padà sí ọ̀dọ̀ ọkọ mi àkọ́kọ́ nítorí pé ó dára fún mi nígbà náà ju ìsinsin yìí lọ.’