Hos 2:18-20
Hos 2:18-20 Bibeli Mimọ (YBCV)
Li ọjọ na li emi o si fi awọn ẹranko igbẹ, ati ẹiyẹ oju ọrun, ati ohun ti nrakò lori ilẹ da majẹmu fun wọn, emi o si ṣẹ́ ọrun ati idà ati ogun kuro ninu aiye, emi o si mu wọn dubulẹ li ailewu. Emi o si fẹ́ ọ fun ara mi titi lai; nitõtọ, emi o si fẹ́ ọ fun ara mi ni ododo, ni idajọ, ati ni iyọ́nu, ati ni ãnu. Emi o tilẹ fẹ́ ọ fun ara mi ni otitọ, iwọ o si mọ̀ Oluwa.
Hos 2:18-20 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà náà ni n óo tìtorí tirẹ̀ bá àwọn ẹranko, àwọn ẹyẹ, ati àwọn nǹkan tí ń fi àyà fà lórí ilẹ̀ dá majẹmu, n óo sì mú ọfà, idà, ati ogun kúrò ní ilẹ̀ náà. N óo jẹ́ kí ẹ máa gbé ní alaafia ati ní àìléwu. Ìwọ Israẹli, n óo sọ ọ́ di iyawo mi títí lae; n óo sọ ọ́ di iyawo mi lódodo ati lótìítọ́, ninu ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ati àánú. N óo sọ ọ́ di iyawo mi, lótìítọ́, o óo sì mọ̀ mí ní OLUWA.
Hos 2:18-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ọjọ́ náà, èmi yóò ṣe májẹ̀mú fún wọn àti àwọn ẹranko igbó àti ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ẹ̀dá tí ń rìn lórí ilẹ̀. Kí wọn má bà á bẹ̀rù ara wọn mọ́ Ọfà, idà àti ogun jíjà ni èmi ó parun ní ilẹ̀ náà kí gbogbo ènìyàn bá a lè wà ní àìléwu. Èmi yóò fẹ́ ọ fún ara mi títí láé. Èmi ó fẹ́ ọ ní ìwà òdodo àti òtítọ́, ní ìfẹ́ àti àánú. Èmi yóò fẹ́ ọ fún ara mi ní òtítọ́ ìwọ yóò sì mọ OLúWA.