Hos 2:14-23

Hos 2:14-23 Yoruba Bible (YCE)

Nítorí náà, n óo tàn án lọ sinu aṣálẹ̀, n óo bá a sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́. N óo sì fún un ní àwọn ọgbà àjàrà rẹ̀ pada níbẹ̀, n óo sì sọ àfonífojì Akori di Ẹnu Ọ̀nà Ìrètí. Yóo kọrin fún mi bí ó tí ń ṣe ní ìgbà èwe rẹ̀, nígbà tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ti ilẹ̀ Ijipti dé. OLUWA ní, nígbà tí ó bá yá, yóo máa pè mí ní ọkọ rẹ̀, kò ní pè mí ní Baali rẹ̀ mọ́. Nítorí pé, n óo gba orúkọ Baali kúrò lẹ́nu rẹ̀, kò sì ní dárúkọ rẹ̀ mọ́. Nígbà náà ni n óo tìtorí tirẹ̀ bá àwọn ẹranko, àwọn ẹyẹ, ati àwọn nǹkan tí ń fi àyà fà lórí ilẹ̀ dá majẹmu, n óo sì mú ọfà, idà, ati ogun kúrò ní ilẹ̀ náà. N óo jẹ́ kí ẹ máa gbé ní alaafia ati ní àìléwu. Ìwọ Israẹli, n óo sọ ọ́ di iyawo mi títí lae; n óo sọ ọ́ di iyawo mi lódodo ati lótìítọ́, ninu ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ati àánú. N óo sọ ọ́ di iyawo mi, lótìítọ́, o óo sì mọ̀ mí ní OLUWA. OLUWA ní, “Ní ọjọ́ náà, n óo dáhùn adura ojú ọ̀run, ojú ọ̀run yó sì dáhùn adura ilẹ̀. Ilẹ̀ yóo sì dáhùn adura ọkà, ati ti waini ati ti òróró. Àwọn náà óo sì dáhùn adura Jesireeli. N óo fi ìdí àwọn eniyan mi múlẹ̀ ní ilẹ̀ náà, wọn yóo sì máa bí sí i. N óo ṣàánú ẹni tí a tí ń pè ní ‘Kò sí àánú’, n óo sì sọ fún ẹni tí a tí ń pè ní ‘Kì í ṣe eniyan mi’ pé eniyan mi ni; òun náà yóo sì dá mi lóhùn pé, ‘Ìwọ ni Ọlọrun mi.’ ”

Hos 2:14-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Nítorí náà, èmi yóò tàn án Èmi ó sì mú u lọ sí ilẹ̀ aṣálẹ̀ Èmi ó fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ bá a sọ̀rọ̀ Níbẹ̀ ni èmi yóò ti dá ọgbà àjàrà rẹ̀ padà fún un, Èmi yóò fi Àfonífojì Akori ṣe ìlẹ̀kùn ìrètí fún un. Yóò sì kọrin níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbà èwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbà tó kúrò ní Ejibiti. “Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà, Ìwọ yóò pè mí ní ‘ọkọ mi’; Ìwọ kò sì ní pè mí ní ‘olúwa à mi mọ́,’ ni OLúWA wí. Èmi yóò mú orúkọ, àwọn òrìṣà Baali kúrò lẹ́nu rẹ̀; ìwọ kò sì ní rí orúkọ òrìṣà Baali pè mọ́ Ní ọjọ́ náà, èmi yóò ṣe májẹ̀mú fún wọn àti àwọn ẹranko igbó àti ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ẹ̀dá tí ń rìn lórí ilẹ̀. Kí wọn má bà á bẹ̀rù ara wọn mọ́ Ọfà, idà àti ogun jíjà ni èmi ó parun ní ilẹ̀ náà kí gbogbo ènìyàn bá a lè wà ní àìléwu. Èmi yóò fẹ́ ọ fún ara mi títí láé. Èmi ó fẹ́ ọ ní ìwà òdodo àti òtítọ́, ní ìfẹ́ àti àánú. Èmi yóò fẹ́ ọ fún ara mi ní òtítọ́ ìwọ yóò sì mọ OLúWA. “Èmi yóò sì dáhùn ní ọjọ́ náà” ni OLúWA wí. “Èmi yóò dá àwọn ọ̀run lóhùn àwọn ọ̀run yóò sì dá ilẹ̀ lóhùn; Ilẹ̀ náà yóò sì dá ọkà, wáìnì tuntun àti òróró lóhùn Gbogbo wọn ó sì dá Jesreeli lóhùn. Èmi ó sì gbìn ín fún ara mi lórí ilẹ̀ náà Èmi yóò ṣàánú fún ẹni tí kò tì í ri ‘àánú Gbà.’ Èmi yóò sọ fún àwọn tí ‘Kì í ṣe ènìyàn mi pé,’ ‘Ẹ̀yin ni ènìyàn mi’; àwọn náà yóò sì wí pé, ‘Ìwọ ni Ọlọ́run mi.’ ”