Hos 14:4-8
Hos 14:4-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Emi o wo ifàsẹhìn wọn sàn, emi o fẹ wọn lọfẹ: nitori ibinu mi yí kuro lọdọ rẹ̀. Emi o dabi ìri si Israeli: on o tanná bi eweko lili; yio si ta gbòngbo rẹ̀ bi Lebanoni. Ẹka rẹ̀ yio tàn, ẹwà rẹ̀ yio si dabi igi olifi, ati õrùn rẹ̀ bi Lebanoni. Awọn ti o ngbe abẹ ojiji rẹ̀ yio padà wá; nwọn o sọji bi ọkà: nwọn o si tanná bi àjara: õrun rẹ̀ yio dabi ọti-waini ti Lebanoni. Efraimu yio wipe, Kili emi ni fi òriṣa ṣe mọ? Emi ti gbọ́, mo si ti kiyesi i: emi dabi igi firi tutù. Lati ọdọ mi li a ti ri èso rẹ.
Hos 14:4-8 Yoruba Bible (YCE)
Ọlọrun ní, “N óo gba ìwà aiṣootọ lọ́wọ́ wọn, n óo fẹ́ wọn tọkàntọkàn, nítorí n kò bínú sí wọn mọ́. Bí ìrì ni n óo máa sẹ̀ sí Israẹli, ẹwà rẹ̀ yóo yọ bí òdòdó lílì, gbòǹgbò rẹ̀ yóo sì múlẹ̀ bíi gbòǹgbò igi kedari Lẹbanoni. Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ yóo tàn kálẹ̀; ẹwà rẹ̀ yóo yọ bíi ti igi olifi, òórùn rẹ̀ yóo sì dàbí ti igi Lẹbanoni. Wọn óo pada sábẹ́ ààbò mi, wọn óo rúwé bí igi inú ọgbà; wọn óo sì tanná bí àjàrà, òórùn wọn óo dàbí ti waini Lẹbanoni. Efuraimu yóo sọ pé, ‘kí ni mo ní ṣe pẹlu àwọn oriṣa?’ Nítorí èmi ni n óo máa gbọ́ adura rẹ̀, tí n óo sì máa tọ́jú rẹ̀. Mo dàbí igi sipirẹsi tí kì í wọ́wé tòjò tẹ̀ẹ̀rùn. Lọ́dọ̀ mi ni èso rẹ̀ ti ń wá.”
Hos 14:4-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Èmi wo àgàbàgebè wọn sàn, Èmi ó sì fẹ́ràn wọn, lọ́fẹ̀ẹ́, nítorí ìbínú mi ti yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn. Èmi o dàbí ìrì sí Israẹli wọn o sì yọ ìtànná bi ewéko lílì Bi kedari ti Lebanoni yóò si ta gbòǹgbò Àṣẹ̀ṣẹ̀yọ ẹ̀ka rẹ̀ yóò dàgbà, Dídán ẹwà yóò rẹ̀ dànù bí igi olifi Òórùn rẹ yóò sì dàbí igi kedari ti Lebanoni. Àwọn ènìyàn yóò tún padà gbé lábẹ́ òjijì rẹ̀. Yóò rúwé bi ọkà. Yóò sì yọ ìtànná bi àjàrà, òórùn rẹ yóò dàbí ti wáìnì Lebanoni. Ìwọ Efraimu; Kín ló tún kù tí mo ní ṣe pẹ̀lú ère òrìṣà? Èmi ó dá a lóhùn, èmi ó sì ṣe ìtọ́jú rẹ. Mo dàbí igi junifa tó ń fi gbogbo ìgbà tutù, èso tí ìwọ ń so si ń wá láti ọ̀dọ̀ mi.”