Hos 12:1-8 - Compare All Versions

Hos 12:1-8 YBCV (Bibeli Mimọ)

EFRAIMU njẹ afẹfẹ́, o si ntọ̀ afẹfẹ́ ila-õrun lẹhìn: o nmu eke ati iparun pọ̀ si i lojojumọ; nwọn si ba awọn ara Assiria da majẹmu, nwọn si nrù ororo lọ si Egipti. Oluwa ni ẹjọ kan ba Juda rò pẹlu, yio si jẹ Jakobu ni iyà gẹgẹ bi ọ̀na rẹ̀; gẹgẹ bi iṣe rẹ̀ ni yio san padà fun u. O di arakunrin rẹ̀ mu ni gigisẹ̀ ni inu, ati nipa ipá rẹ̀ o ni agbara pẹlu Ọlọrun. Nitõtọ, o ni agbara lori angeli, o si bori: o sọkun, o si bẹ̀bẹ lọdọ rẹ̀: o ri i ni Beteli, nibẹ̀ li o gbe ba wa sọ̀rọ; Ani Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun; Oluwa ni iranti rẹ̀. Nitorina, iwọ yipadà si Ọlọrun rẹ: pa ãnu ati idajọ mọ, ki o si ma duro de Ọlọrun rẹ nigbagbogbo. Kenaani ni, iwọ̀n ẹtàn mbẹ li ọwọ́ rẹ̀: o fẹ lati ninilara. Efraimu si wipe, Ṣugbọn emi di ọlọrọ̀, mo ti ri ini fun ara mi: ninu gbogbo lãlã mi nwọn kì yio ri aiṣedẽde kan ti iṣe ẹ̀ṣẹ lara mi.

Hos 12:1-8 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Efraimu ń jẹ afẹ́fẹ́; o ń lépa afẹ́fẹ́ ìwọ̀-oòrùn ní gbogbo ọjọ́. O sì ń gbèrú nínú irọ́ o dá májẹ̀mú pẹ̀lú Asiria o sì fi òróró olifi ránṣẹ́ sí Ejibiti. OLúWA ní ẹjọ́ kan tí yóò bá Juda rò, yóò fì ìyà jẹ Jakọbu gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀ yóò sì sán fún un gẹ́gẹ́ bí i ìṣe rẹ̀. Láti inú oyún ni ó ti di arákùnrin rẹ̀ mú ni gìgísẹ̀, àti nípa ipá rẹ̀ ó ni agbára pẹ̀lú Ọlọ́run Ó bá angẹli ja ìjàkadì, ó sì borí rẹ̀, o sọkún, ó sì bẹ̀bẹ̀ fún ojúrere rẹ̀. Ó bá OLúWA ní Beteli, Ó sì bá a sọ̀rọ̀ níbẹ̀, àní OLúWA Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun; OLúWA ni orúkọ ìrántí rẹ̀. Ṣùgbọ́n ìwọ gbọdọ̀ padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run rẹ̀; di ìfẹ́ àti ìdájọ́ òdodo mú kí ẹ sì dúró de Ọlọ́run yín nígbà gbogbo. Oníṣòwò ń lo òsùwọ̀n èké o fẹ́ràn láti rẹ́ ni jẹ. Efraimu gbéraga, “Èmi ní ìní fún ara mi, mo sì ti di ọlọ́rọ̀, pẹ̀lú gbogbo ọrọ̀ mi yìí, wọn kò le ká àìṣedéédéé tàbí ẹ̀ṣẹ̀ kankan mọ́ mi lọ́wọ́.”

Hos 12:1-8 YCE (Yoruba Bible)

“Asán ati ìbàjẹ́ ni gbogbo nǹkan tí Efuraimu ń ṣe látàárọ̀ dalẹ́. Wọ́n ń parọ́ kún irọ́, bẹ́ẹ̀ ni ìwà ipá wọn ń pọ̀ sí i. Wọ́n ń bá àwọn Asiria dá majẹmu, wọ́n sì ń ru òróró lọ sí ilẹ̀ Ijipti.” OLUWA ní ẹjọ́ tí yóo bá àwọn ọmọ Juda rò, yóo jẹ àwọn ọmọ Israẹli níyà gẹ́gẹ́ bí ìwà wọn, yóo sì san ẹ̀san iṣẹ́ ọwọ́ wọn fún wọn. Jakọbu, baba ńlá wọn di arakunrin rẹ̀ ní gìgísẹ̀ mú ninu oyún, nígbà tí ó dàgbà tán, ó bá Ọlọrun wọ̀jàkadì. Ó bá angẹli jà, ó ja àjàṣẹ́gun, ó sọkún, ó sì wá ojurere rẹ̀. Ó bá Ọlọrun pàdé ní Bẹtẹli, níbẹ̀ ni Ọlọrun sì ti bá a sọ̀rọ̀. OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, OLUWA ni orúkọ rẹ̀: Nítorí náà, ẹ yipada nípa agbára Ọlọrun yín, ẹ di ìfẹ́ ati ìdájọ́ òdodo mú, kí ẹ sì dúró de Ọlọrun yín nígbà gbogbo. OLUWA ní, “Efuraimu jẹ́ oníṣòwò tí ó gbé òṣùnwọ̀n èké lọ́wọ́, ó sì fẹ́ràn láti máa ni eniyan lára. Efuraimu ní, ‘Mo ní ọrọ̀, mo ti kó ọrọ̀ jọ fún ara mi, ṣugbọn gbogbo ọrọ̀ rẹ̀ kò lè mú ẹ̀bi rẹ̀ kúrò.’