Hos 12:1-14

Hos 12:1-14 Bibeli Mimọ (YBCV)

EFRAIMU njẹ afẹfẹ́, o si ntọ̀ afẹfẹ́ ila-õrun lẹhìn: o nmu eke ati iparun pọ̀ si i lojojumọ; nwọn si ba awọn ara Assiria da majẹmu, nwọn si nrù ororo lọ si Egipti. Oluwa ni ẹjọ kan ba Juda rò pẹlu, yio si jẹ Jakobu ni iyà gẹgẹ bi ọ̀na rẹ̀; gẹgẹ bi iṣe rẹ̀ ni yio san padà fun u. O di arakunrin rẹ̀ mu ni gigisẹ̀ ni inu, ati nipa ipá rẹ̀ o ni agbara pẹlu Ọlọrun. Nitõtọ, o ni agbara lori angeli, o si bori: o sọkun, o si bẹ̀bẹ lọdọ rẹ̀: o ri i ni Beteli, nibẹ̀ li o gbe ba wa sọ̀rọ; Ani Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun; Oluwa ni iranti rẹ̀. Nitorina, iwọ yipadà si Ọlọrun rẹ: pa ãnu ati idajọ mọ, ki o si ma duro de Ọlọrun rẹ nigbagbogbo. Kenaani ni, iwọ̀n ẹtàn mbẹ li ọwọ́ rẹ̀: o fẹ lati ninilara. Efraimu si wipe, Ṣugbọn emi di ọlọrọ̀, mo ti ri ini fun ara mi: ninu gbogbo lãlã mi nwọn kì yio ri aiṣedẽde kan ti iṣe ẹ̀ṣẹ lara mi. Ati emi, Oluwa Ọlọrun rẹ lati ilẹ̀ Egipti wá, yio si tún mu ọ gbe inu agọ, bi ọjọ ajọ-ọ̀wọ wọnni. Emi ti sọ̀rọ nipa awọn woli pẹlu, mo si ti mu iran di pupọ̀, mo ti ṣe ọ̀pọlọpọ akàwe, nipa ọwọ́ awọn woli. Aiṣedẽde mbẹ ni Gileadi bi? nitõtọ asan ni nwọn: nwọn rubọ akọ malu ni Gilgali; nitõtọ, pẹpẹ wọn dabi ebè ni aporo oko. Jakobu si salọ si ilẹ Siria: Israeli si sìn nitori aya kan; ati nitori aya kan li o ṣọ agùtan. Ati nipa woli kan ni Oluwa mu Israeli jade ni Egipti: nipa woli kan li a si pa on mọ. Efraimu mu u binu kikorò: nitorina ni yio fi ẹjẹ̀ rẹ̀ si ori rẹ̀, ẹgàn rẹ̀ li Oluwa rẹ̀ yio si san padà fun u.

Hos 12:1-14 Yoruba Bible (YCE)

“Asán ati ìbàjẹ́ ni gbogbo nǹkan tí Efuraimu ń ṣe látàárọ̀ dalẹ́. Wọ́n ń parọ́ kún irọ́, bẹ́ẹ̀ ni ìwà ipá wọn ń pọ̀ sí i. Wọ́n ń bá àwọn Asiria dá majẹmu, wọ́n sì ń ru òróró lọ sí ilẹ̀ Ijipti.” OLUWA ní ẹjọ́ tí yóo bá àwọn ọmọ Juda rò, yóo jẹ àwọn ọmọ Israẹli níyà gẹ́gẹ́ bí ìwà wọn, yóo sì san ẹ̀san iṣẹ́ ọwọ́ wọn fún wọn. Jakọbu, baba ńlá wọn di arakunrin rẹ̀ ní gìgísẹ̀ mú ninu oyún, nígbà tí ó dàgbà tán, ó bá Ọlọrun wọ̀jàkadì. Ó bá angẹli jà, ó ja àjàṣẹ́gun, ó sọkún, ó sì wá ojurere rẹ̀. Ó bá Ọlọrun pàdé ní Bẹtẹli, níbẹ̀ ni Ọlọrun sì ti bá a sọ̀rọ̀. OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, OLUWA ni orúkọ rẹ̀: Nítorí náà, ẹ yipada nípa agbára Ọlọrun yín, ẹ di ìfẹ́ ati ìdájọ́ òdodo mú, kí ẹ sì dúró de Ọlọrun yín nígbà gbogbo. OLUWA ní, “Efuraimu jẹ́ oníṣòwò tí ó gbé òṣùnwọ̀n èké lọ́wọ́, ó sì fẹ́ràn láti máa ni eniyan lára. Efuraimu ní, ‘Mo ní ọrọ̀, mo ti kó ọrọ̀ jọ fún ara mi, ṣugbọn gbogbo ọrọ̀ rẹ̀ kò lè mú ẹ̀bi rẹ̀ kúrò.’ Èmi ni OLUWA Ọlọrun rẹ láti ilẹ̀ Ijipti; n óo tún mú ọ pada gbé inú àgọ́, bí àwọn ọjọ́ àjọ ìyàsọ́tọ̀. “Mo bá àwọn wolii sọ̀rọ̀; èmi ni mo fi ọpọlọpọ ìran hàn wọ́n, tí mo sì tipasẹ̀ wọn pa ọpọlọpọ òwe. Ẹ̀ṣẹ̀ ìbọ̀rìṣà wà ní Gileadi, dájúdájú yóo parun; bí wọ́n bá fi akọ mààlúù rúbọ ní Giligali, pẹpẹ wọn yóo dàbí òkúta tí a kójọ ní poro oko.” Jakọbu sálọ sí ilẹ̀ Aramu, níbẹ̀ ni ó ti singbà, tí ó ṣiṣẹ́ darandaran, nítorí iyawo tí ó fẹ́. Nípasẹ̀ wolii kan ni OLUWA ti mú Israẹli jáde kúrò ní Ijipti, nípasẹ̀ wolii kan ni a sì ti pa á mọ́. Efuraimu ti mú èmi, OLUWA rẹ̀ bínú lọpọlọpọ, nítorí náà, n óo da ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ lé e lórí, òun tí ó gàn mí ni yóo di ẹni ẹ̀gàn.

Hos 12:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Efraimu ń jẹ afẹ́fẹ́; o ń lépa afẹ́fẹ́ ìwọ̀-oòrùn ní gbogbo ọjọ́. O sì ń gbèrú nínú irọ́ o dá májẹ̀mú pẹ̀lú Asiria o sì fi òróró olifi ránṣẹ́ sí Ejibiti. OLúWA ní ẹjọ́ kan tí yóò bá Juda rò, yóò fì ìyà jẹ Jakọbu gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀ yóò sì sán fún un gẹ́gẹ́ bí i ìṣe rẹ̀. Láti inú oyún ni ó ti di arákùnrin rẹ̀ mú ni gìgísẹ̀, àti nípa ipá rẹ̀ ó ni agbára pẹ̀lú Ọlọ́run Ó bá angẹli ja ìjàkadì, ó sì borí rẹ̀ o sọkún, ó sì bẹ̀bẹ̀ fún ojúrere rẹ̀ Ó bá OLúWA ní Beteli Ó sì bá a sọ̀rọ̀ níbẹ̀, àní OLúWA Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun; OLúWA ni orúkọ ìrántí rẹ̀ Ṣùgbọ́n ìwọ gbọdọ̀ padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run rẹ̀; di ìfẹ́ àti ìdájọ́ òdodo mú kí ẹ sì dúró de Ọlọ́run yín nígbà gbogbo. Oníṣòwò ń lo òṣùwọ̀n èké o fẹ́ràn láti rẹ́ ni jẹ. Efraimu gbéraga, “Èmi ní ìní fún ara mi, mo sì ti di ọlọ́rọ̀, pẹ̀lú gbogbo ọrọ̀ mi yìí, wọn kò le ká àìṣedéédéé tàbí ẹ̀ṣẹ̀ kankan mọ́ mi lọ́wọ́.” “Èmi ni OLúWA Ọlọ́run rẹ; ẹni tí ó mu ọ jáde wá láti ilẹ̀ Ejibiti; èmi yóò tún mú yín gbé nínú àgọ́ bí i ọjọ́ àjọ̀dún tí a yàn wọ̀n-ọn-nì Mo sọ fún àwọn wòlíì, mo fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìran hàn wọ́n mo sì pa òwe láti ẹnu wòlíì wọn.” Gileadi ha burú bí? Àwọn ènìyàn rẹ̀ jẹ́ asán. Ǹjẹ́ wọ́n ń fi akọ màlúù rú ẹbọ ní Gilgali? Gbogbo pẹpẹ wọ́n sì dàbí ebè nínú aporo oko. Jakọbu sálọ si orílẹ̀-èdè Aramu; Israẹli sìn kí o tó fẹ́ ìyàwó ó ṣe ìtọ́jú ẹran láti fi san owó ìyàwó. OLúWA lo wòlíì kan láti mú Israẹli jáde wá láti Ejibiti, nípasẹ̀ wòlíì kan ó ṣe ìtọ́jú rẹ̀. Ṣùgbọ́n Efraimu ti mú un bínú gidigidi; Olúwa rẹ̀ yóò sì fi ẹ̀bi ìtàjẹ̀ sílẹ̀ sí orí rẹ̀ òun yóò sì san án padà fún un nítorí ìwà ẹ̀gàn an rẹ̀.