Hos 11:1-5
Hos 11:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBATI Israeli wà li ọmọde, nigbana ni mo fẹ́ ẹ, mo si pè ọmọ mi lati Egipti jade wá. Bi nwọn ti pè wọn, bẹ̃ni nwọn lọ kuro lọdọ wọn: nwọn rubọ si Baalimu, nwọn si fi turari joná si ere fifin. Mo kọ́ Efraimu pẹlu lati rìn, mo dì wọn mu li apa, ṣugbọn nwọn kò mọ̀ pe mo ti mu wọn lara dá. Mo fi okùn enia fà wọn, ati idè ifẹ: mo si ri si wọn bi awọn ti o mu ajàga kuro li ẹrẹkẹ wọn, mo si gbe onjẹ kalẹ niwaju wọn. On kì yio yipadà si ilẹ Egipti, ṣugbọn ara Assiria ni yio jẹ ọba rẹ̀, nitori nwọn kọ̀ lati yipadà.
Hos 11:1-5 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA ní, “Nígbà tí Israẹli wà ní ọmọde, mo fẹ́ràn rẹ̀, láti ilẹ̀ Ijipti ni mo sì ti pe ọmọ mi jáde. Ṣugbọn bí mo ti ń pè wọ́n tó, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ń sá fún mi, wọ́n ń rúbọ sí àwọn oriṣa Baali, wọ́n ń sun turari sí ère. Bẹ́ẹ̀ ni èmi ni mo kọ́ Efuraimu ní ìrìn, mo gbé wọn lé ọwọ́ mi, ṣugbọn wọn kò mọ̀ pé èmi ni mo wo àwọn sàn. Mo fà wọ́n mọ́ra pẹlu okùn àánú ati ìdè ìfẹ́, mo dàbí ẹni tí ó tú àjàgà kúrò ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ wọn, mo sì bẹ̀rẹ̀, mo gbé oúnjẹ kalẹ̀ níwájú wọn. “Wọn óo pada sí ilẹ̀ Ijipti, Asiria óo sì jọba lé wọn lórí, nítorí pé wọ́n kọ̀, wọn kò pada sọ́dọ̀ mi.
Hos 11:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Nígbà tí Israẹli wà ní ọmọdé mo fẹ́ràn rẹ̀, mo sì pe ọmọ mi jáde láti Ejibiti wá. Bí a ti ń pe wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ń sá kúrò lọ́dọ̀ mi, wọn rú ẹbọ sí Baali, wọn sì fi tùràrí jóná sí ère fínfín. Lóòtítọ́ mo kọ́ Efraimu pẹ̀lú ní ìrìn mo di wọ́n mú ní apá, ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀ pé mo ti mú wọn láradá. Mo fi okùn ènìyàn fà wọ́n àti ìdè ìfẹ́. Mo mú àjàgà kúrò ni ọrùn wọn Mo sì fi ara balẹ̀ fún wọn ni oúnjẹ. “Ṣé wọn ò wá ní padà sí Ejibiti bí Ṣé Asiria kò sì ní jẹ ọba lé wọn lórí bí nítorí pé wọ́n kọ̀ jálẹ̀ láti ronúpìwàdà?