Hos 10:13-15
Hos 10:13-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹnyin ti tulẹ ìwa-buburu, ẹnyin ti ká aiṣedẽde; ẹnyin ti jẹ eso eke: nitori iwọ gbẹkẹ̀le ọ̀na rẹ, ninu ọ̀pọlọpọ awọn alagbara rẹ. Nitorina li ariwo yio dide ninu awọn enia rẹ, gbogbo awọn odi agbara rẹ li a o si bajẹ, bi Ṣalmani ti ba Bet-abeli jẹ li ọjọ ogun: a fọ́ iya tũtũ lori awọn ọmọ rẹ̀. Bẹ̃ni Beteli yio ṣe si nyin, nitori ìwa-buburu nla nyin; ni kùtukùtu li a o ke ọba Israeli kuro patapata.
Hos 10:13-15 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ ti gbin ẹ̀ṣẹ̀, ẹ sì ti ká aiṣododo, ẹ ti jẹ èso ẹ̀tàn. “Nítorí pé ẹ gbẹ́kẹ̀lé kẹ̀kẹ́ ogun ati ọpọlọpọ ọmọ ogun yín, nítorí náà, ogun yóo bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn eniyan yín, gbogbo ibi ààbò yín ni yóo parun. Bí Ṣalimani ti pa Betabeli run, ní ọjọ́ ogun, ní ọjọ́ tí wọ́n pa ìyá tòun tọmọ; bẹ́ẹ̀ ni a óo ṣe si yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, nítorí ìwà burúkú yín. Bí ogun bá tí ń bẹ̀rẹ̀ ni a óo ti pa ọba Israẹli run.”
Hos 10:13-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
Ṣùgbọ́n ẹ tí gbin búburú ẹ si ka ibi, ẹ ti jẹ èso èké nítorí ẹ tí gbẹ́kẹ̀lé agbára yín àti àwọn ọ̀pọ̀ jagunjagun yín, ariwo ogun yóò bo àwọn ènìyàn yín kí gbogbo odi agbára yín ba le parun. Gẹ́gẹ́ bí Ṣalmani ṣe pa Beti-Arbeli run lọ́jọ́ ogun, nígbà tí a gbé àwọn ìyá ṣánlẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn. Báyìí ni a o sì ṣe sí ọ, ìwọ Beteli, nítorí pé ìwà búburú yín ti pọ̀jù. Ní àfẹ̀mọ́júmọ́ ọjọ́ náà, a o pa ọba Israẹli run pátápátá.