Hos 10:1-8

Hos 10:1-8 Yoruba Bible (YCE)

Àwọn ọmọ Israẹli dàbí àjàrà dáradára tí ń so èso pupọ. Bí èso rẹ̀ tí ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ni pẹpẹ oriṣa wọn ń pọ̀ sí i. Bí àwọn ìlú wọn tí ń dára sí i ni àwọn ọ̀wọ̀n oriṣa wọn náà ń dára sí i. Èké ni wọ́n, nítorí náà wọn óo jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn, OLUWA yóo wó pẹpẹ wọn lulẹ̀, yóo sì fọ́ àwọn ọ̀wọ̀n oriṣa wọn. Wọn óo máa wí nisinsinyii pé, “A kò ní ọba, nítorí pé a kò bẹ̀rù OLUWA; kí ni ọba kan fẹ́ ṣe fún wa?” Wọ́n ń fọ́nnu lásán; wọ́n ń fi ìbúra asán dá majẹmu; nítorí náà ni ìdájọ́ ṣe dìde sí wọn bíi koríko olóró, ní poro oko. Àwọn ará Samaria wárìrì fún ère ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù, oriṣa ìlú Betafeni. Àwọn eniyan ibẹ̀ yóo ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, àwọn babalóòṣà rẹ̀ yóo pohùnréré ẹkún lé e lórí, nítorí ògo rẹ̀ tí ó ti fò lọ. Dájúdájú, a óo gbé ère oriṣa náà lọ sí Asiria, a óo fi ṣe owó ìṣákọ́lẹ̀ fún ọba ńlá ibẹ̀. Ojú yóo ti Efuraimu, ojú yóo sì ti Israẹli nítorí ère oriṣa rẹ̀. Ọba Samaria yóo parun bí ẹ̀ẹ́rún igi tí ó léfòó lórí omi. A óo pa ibi pẹpẹ ìrúbọ Afeni, tíí ṣe ẹ̀ṣẹ̀ fún Israẹli run; ẹ̀gún ati òṣùṣú yóo hù jáde lórí àwọn pẹpẹ wọn. Wọn yóo sì sọ fún àwọn òkè gíga pé kí wọ́n bo àwọn mọ́lẹ̀, wọn óo sì sọ fún àwọn òkè kéékèèké pé kí wọ́n wó lu àwọn.

Hos 10:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Israẹli jẹ́ igi àjàrà tó gbilẹ̀ ó ń so èso fún ara rẹ̀ Bí èso rẹ̀ ṣe ń pọ̀ bẹ́ẹ̀ ni ó ń kọ́ pẹpẹ sí i bí ilẹ̀ rẹ̀ ṣe ń ṣe rere o bu ọlá fún òkúta ìyàsọ́tọ̀ ère rẹ̀. Ọkàn wọn kún fún ìtànjẹ báyìí wọ́n gbọdọ̀ ru ẹ̀bi wọn. OLúWA yóò wó pẹpẹ wọn palẹ̀ yóò sì pa gbogbo òkúta ìyàsọ́tọ̀ wọn run. Nígbà náà ni wọn yóò wí pé, “A kò ní ọba nítorí tí a kò bọ̀wọ̀ fún OLúWA ṣùgbọ́n bí a tilẹ̀ ní ọba, kí ni yóò ṣe fún wa?” Wọ́n ṣe ìlérí púpọ̀, wọ́n ṣe ìbúra èké, wọ́n da májẹ̀mú; báyìí ni ìdájọ́ hù sókè bí igi ìwọ̀ ni aporo oko, bi i koríko májèlé láàrín oko tí a ro. Àwọn ènìyàn tí ń gbé Samaria bẹ̀rù nítorí ère abo màlúù tó wà ní Beti-Afeni Àwọn ènìyàn rẹ̀ yóò ṣọ̀fọ̀ le e lórí bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà abọ̀rìṣà rẹ̀ Gbogbo àwọn tó láyọ̀ sì dídán rẹ̀, nítorí tí a ti mú lọ sí ìgbèkùn. A ó gbé lọ sí Asiria gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn fún ọba ńlá a ó dójútì Efraimu; ojú yóò ti Israẹli nítorí ìgbìmọ̀ rẹ̀ Bí igi tó léfòó lórí omi ni Samaria àti àwọn ọba rẹ yóò sàn lọ. Àwọn ibi gíga tí ẹ tí ń hùwà búburú ni a o parun— èyí ni ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli. Ẹ̀gún ọ̀gàn àti ẹ̀gún òṣùṣú yóò hù jáde, yóò sì bo àwọn pẹpẹ wọn. Wọn yóò sọ fún àwọn òkè gíga pé, “Bò wá mọ́lẹ̀!” àti fún àwọn òkè kéékèèkéé pé, “Ṣubú lù wá!”