Hos 10:1-15

Hos 10:1-15 Bibeli Mimọ (YBCV)

ÁJARA ofo ni Israeli, o nso eso fun ara rẹ̀; gẹgẹ bi ọ̀pọ eso rẹ̀ li o mu pẹpẹ pọ̀ si i; gẹgẹ bi didara ilẹ rẹ̀ ni nwọn yá ere daradara. Ọkàn wọn dá meji; nisisiyi ni nwọn o jẹbi; on o wó pẹpẹ wọn lulẹ, on o si ba ere wọn jẹ. Nitori nisisiyi ni nwọn o wipe, Awa kò li ọba, nitoriti awa kò bẹ̀ru Oluwa; njẹ kili ọba o ṣe fun wa? Nwọn ti sọ ọ̀rọ, nwọn mbura eke ni didà majẹmu: bayi ni idajọ hù soke bi igi iwọ, ni aporo oko. Nitori awọn ọmọ-malu Bet-afeni, awọn ti ngbe Samaria yio bẹ̀ru: nitori awọn enia ibẹ̀ yio ṣọ̀fọ lori rẹ̀, ati awọn baba-oloriṣà ibẹ̀ ti o yọ̀ lori rẹ̀, nitori ogo rẹ̀, nitori o ti lọ kuro lọdọ rẹ̀. A o si mu u lọ si Assiria pẹlu ẹbùn fun Jarebu ọba: Efraimu yio gbà itiju, oju yio si tì Israeli nitori igbìmọ rẹ̀. Bi o ṣe ti Samaria, a ké ọba rẹ̀ kuro bi ifõfõ loju omi. Ibi giga Afeni pẹlu, ẹ̀ṣẹ Israeli, li a o parun; ẹgún ọ̀gan on oṣuṣu yio hù jade lori pẹpẹ wọn; nwọn o si wi fun awọn oke-nla pe, Bò wa mọlẹ; ati fun awọn oke kékèké pe, Wó lù wa. Lati ọjọ Gibea ni iwọ ti ṣẹ̀, Israeli: nibẹ̀ ni nwọn duro: ogun Gibea si awọn ọmọ ẹ̀ṣẹ kò ha le wọn ba? Ifẹ inu mi ni ki nle nà wọn; a o si gbá awọn enia jọ si wọn, lati di ara wọn si ẹ̀ṣẹ wọn mejeji. Efraimu si dabi ọmọ-malu ti a kọ́, ti o si fẹ́ lati ma tẹ ọkà; ṣugbọn emi rekọja li ori ọrùn rẹ̀ ti o ni ẹwà: emi o mu ki Efraimu gùn ẹṣin; Juda yio tú ilẹ, Jakobu yio si fọ́ ogulùtu rẹ̀. Ẹ furùngbin fun ara nyin li ododo, ẹ ká li ãnu: ẹ tú ilẹ nyin ti a kò ro: nitori o to akokò lati wá Oluwa, titi yio fi de, ti yio si fi rọ̀jo ododo si nyin. Ẹnyin ti tulẹ ìwa-buburu, ẹnyin ti ká aiṣedẽde; ẹnyin ti jẹ eso eke: nitori iwọ gbẹkẹ̀le ọ̀na rẹ, ninu ọ̀pọlọpọ awọn alagbara rẹ. Nitorina li ariwo yio dide ninu awọn enia rẹ, gbogbo awọn odi agbara rẹ li a o si bajẹ, bi Ṣalmani ti ba Bet-abeli jẹ li ọjọ ogun: a fọ́ iya tũtũ lori awọn ọmọ rẹ̀. Bẹ̃ni Beteli yio ṣe si nyin, nitori ìwa-buburu nla nyin; ni kùtukùtu li a o ke ọba Israeli kuro patapata.

Hos 10:1-15 Yoruba Bible (YCE)

Àwọn ọmọ Israẹli dàbí àjàrà dáradára tí ń so èso pupọ. Bí èso rẹ̀ tí ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ni pẹpẹ oriṣa wọn ń pọ̀ sí i. Bí àwọn ìlú wọn tí ń dára sí i ni àwọn ọ̀wọ̀n oriṣa wọn náà ń dára sí i. Èké ni wọ́n, nítorí náà wọn óo jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn, OLUWA yóo wó pẹpẹ wọn lulẹ̀, yóo sì fọ́ àwọn ọ̀wọ̀n oriṣa wọn. Wọn óo máa wí nisinsinyii pé, “A kò ní ọba, nítorí pé a kò bẹ̀rù OLUWA; kí ni ọba kan fẹ́ ṣe fún wa?” Wọ́n ń fọ́nnu lásán; wọ́n ń fi ìbúra asán dá majẹmu; nítorí náà ni ìdájọ́ ṣe dìde sí wọn bíi koríko olóró, ní poro oko. Àwọn ará Samaria wárìrì fún ère ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù, oriṣa ìlú Betafeni. Àwọn eniyan ibẹ̀ yóo ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, àwọn babalóòṣà rẹ̀ yóo pohùnréré ẹkún lé e lórí, nítorí ògo rẹ̀ tí ó ti fò lọ. Dájúdájú, a óo gbé ère oriṣa náà lọ sí Asiria, a óo fi ṣe owó ìṣákọ́lẹ̀ fún ọba ńlá ibẹ̀. Ojú yóo ti Efuraimu, ojú yóo sì ti Israẹli nítorí ère oriṣa rẹ̀. Ọba Samaria yóo parun bí ẹ̀ẹ́rún igi tí ó léfòó lórí omi. A óo pa ibi pẹpẹ ìrúbọ Afeni, tíí ṣe ẹ̀ṣẹ̀ fún Israẹli run; ẹ̀gún ati òṣùṣú yóo hù jáde lórí àwọn pẹpẹ wọn. Wọn yóo sì sọ fún àwọn òkè gíga pé kí wọ́n bo àwọn mọ́lẹ̀, wọn óo sì sọ fún àwọn òkè kéékèèké pé kí wọ́n wó lu àwọn. Láti ìgbà Gibea ni Israẹli ti ń dẹ́ṣẹ̀; sibẹ wọn kò tíì jáwọ́ ninu ẹ̀ṣẹ̀. Ṣé ogun kò ní pa wọ́n ní Gibea? N óo dojú kọ àwọn tí ń ṣe ségesège n óo jẹ wọ́n níyà. Àwọn orílẹ̀-èdè yóo parapọ̀ láti kojú wọn, nígbà tí wọ́n bá ń jìyà fún ọpọlọpọ ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Efuraimu dàbí ọmọ mààlúù tí a ti fi iṣẹ́ ṣíṣe kọ́, tí ó sì fẹ́ràn láti máa pa ọkà, mo fi ọrùn rẹ̀ tí ó lẹ́wà sílẹ̀; ṣugbọn nisinsinyii, n óo gbé àjàgà bọ̀ ọ́ lọ́rùn, ó di dandan kí Juda kọ ilẹ̀, kí Israẹli sì máa ro oko fún ara rẹ̀. Ẹ gbin òdodo fún ara yín, kí ẹ sì ká èso ìfẹ́ tí kì í yẹ̀; ẹ lọ dá oko sí ilẹ̀ tí ẹ ti kọ̀ sílẹ̀, nítorí ó tó àkókò láti wá OLUWA, kí ó lè wá rọ ìgbàlà le yín lórí bí òjò. Ẹ ti gbin ẹ̀ṣẹ̀, ẹ sì ti ká aiṣododo, ẹ ti jẹ èso ẹ̀tàn. “Nítorí pé ẹ gbẹ́kẹ̀lé kẹ̀kẹ́ ogun ati ọpọlọpọ ọmọ ogun yín, nítorí náà, ogun yóo bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn eniyan yín, gbogbo ibi ààbò yín ni yóo parun. Bí Ṣalimani ti pa Betabeli run, ní ọjọ́ ogun, ní ọjọ́ tí wọ́n pa ìyá tòun tọmọ; bẹ́ẹ̀ ni a óo ṣe si yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, nítorí ìwà burúkú yín. Bí ogun bá tí ń bẹ̀rẹ̀ ni a óo ti pa ọba Israẹli run.”

Hos 10:1-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)

Israẹli jẹ́ igi àjàrà tó gbilẹ̀ ó ń so èso fún ara rẹ̀. Bí èso rẹ̀ ṣe ń pọ̀ bẹ́ẹ̀ ni ó ń kọ́ pẹpẹ sí i bí ilẹ̀ rẹ̀ ṣe ń ṣe rere o bu ọlá fún òkúta ìyàsọ́tọ̀ ère rẹ̀. Ọkàn wọn kún fún ìtànjẹ báyìí wọ́n gbọdọ̀ ru ẹ̀bi wọn. OLúWA yóò wó pẹpẹ wọn palẹ̀ yóò sì pa gbogbo òkúta ìyàsọ́tọ̀ wọn run. Nígbà náà ni wọn yóò wí pé, “A kò ní ọba nítorí tí a kò bọ̀wọ̀ fún OLúWA ṣùgbọ́n bí a tilẹ̀ ní ọba, kí ni yóò ṣe fún wa?” Wọ́n ṣe ìlérí púpọ̀, wọ́n ṣe ìbúra èké, wọ́n da májẹ̀mú; báyìí ni ìdájọ́ hù sókè bí igi ìwọ̀ ni aporo oko, bi i koríko májèlé láàrín oko tí a ro. Àwọn ènìyàn tí ń gbé Samaria bẹ̀rù nítorí ère abo màlúù tó wà ní Beti-Afeni. Àwọn ènìyàn rẹ̀ yóò ṣọ̀fọ̀ le e lórí bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà abọ̀rìṣà rẹ̀. Gbogbo àwọn tó láyọ̀ sì dídán rẹ̀, nítorí tí a ti mú lọ sí ìgbèkùn. A ó gbé lọ sí Asiria gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn fún ọba ńlá a ó dójútì Efraimu; ojú yóò ti Israẹli nítorí ìgbìmọ̀ rẹ̀. Bí igi tó léfòó lórí omi ni Samaria àti àwọn ọba rẹ yóò sàn lọ. Àwọn ibi gíga tí ẹ tí ń hùwà búburú ni a o parun, èyí ni ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli. Ẹ̀gún ọ̀gàn àti ẹ̀gún òṣùṣú yóò hù jáde, yóò sì bo àwọn pẹpẹ wọn. Wọn yóò sọ fún àwọn òkè gíga pé, “Bò wá mọ́lẹ̀!” àti fún àwọn òkè kéékèèké pé, “Ṣubú lù wá!” “Láti ìgbà Gibeah, ni ó ti ṣẹ̀, ìwọ Israẹli, ìwọ sì tún wà níbẹ̀. Ǹjẹ́ ogun kò lé ẹ̀yin aṣebi ni Gibeah bá bí? Nígbà tó bá tẹ́ mi lọ́rùn, èmi yóò fi ìyà jẹ wọ́n; Orílẹ̀-èdè yóò kó ra wọn jọ, wọ́n ó sì dojúkọ wọn, láti fi wọn sínú ìdè nítorí ìlọ́po ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Efraimu jẹ́ ọmọ abo màlúù tí a tí kọ́, to si fẹ́ràn láti máa pa ọkà; lórí ọrun rẹ̀ tó lẹ́wà ni èmi ó dí ẹrù wúwo lé. Èmi yóò mú kí a gun Efraimu bí ẹṣin Juda yóò tú ilẹ̀, Jakọbu yóò sì fọ́ ògúlùtu rẹ̀. Ẹ gbin òdòdó fún ara yín, kí ẹ sì ká èso ìfẹ́ àìlópin. Ẹ tu ilẹ̀ yín tí a kò ro, nítorí pé ó ti tó àsìkò láti wá OLúWA, títí tí yóò fi dé, tí yóò sì rọ òjò òdodo lé yín lórí. Ṣùgbọ́n ẹ tí gbin búburú ẹ si ka ibi, ẹ ti jẹ èso èké nítorí ẹ tí gbẹ́kẹ̀lé agbára yín àti àwọn ọ̀pọ̀ jagunjagun yín, ariwo ogun yóò bo àwọn ènìyàn yín kí gbogbo odi agbára yín ba le parun. Gẹ́gẹ́ bí Ṣalmani ṣe pa Beti-Arbeli run lọ́jọ́ ogun, nígbà tí a gbé àwọn ìyá ṣánlẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn. Báyìí ni a o sì ṣe sí ọ, ìwọ Beteli, nítorí pé ìwà búburú yín ti pọ̀jù. Ní àfẹ̀mọ́júmọ́ ọjọ́ náà, a o pa ọba Israẹli run pátápátá.