Hos 1:1-7
Hos 1:1-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọ̀RỌ Oluwa ti o tọ̀ Hosea, ọmọ Beeri wá, li ọjọ Ussiah, Jotamu, Ahasi, ati Hesekiah, awọn ọba Juda, ati li ọjọ Jeroboamu ọmọ Joaṣi, ọba Israeli. Ibẹ̀rẹ ọ̀rọ Oluwa si Hosea. Oluwa si wi fun Hosea, pe, Lọ, fẹ́ agbère obinrin kan fun ara rẹ, ati awọn ọmọ agbère; nitori ilẹ yi ti ṣe agbère gidigidi, kuro lẹhin Oluwa. O si lọ o si fẹ́ Gomeri ọmọbinrin Diblaimu; ẹniti o loyún, ti o si bi ọmọkunrin kan fun u. Oluwa si wi fun u pe, Pè orukọ rẹ̀ ni Jesreeli; nitori niwọ̀n igbà diẹ, emi o bẹ̀ ẹ̀jẹ Jesreeli wò li ara ile Jehu, emi o si mu ki ijọba ile Israeli kasẹ̀. Yio si ṣe li ọjọ na, li emi o ṣẹ́ ọrun Israeli ni afonifojì Jesreeli. O si tún loyún, o si bi ọmọbinrin kan. Ọlọrun si wi fun u pe, Pè orukọ rẹ̀ li Loruhama: nitori emi kì yio tún ma ṣãnu fun ile Israeli mọ, nitoriti emi o mu wọn kuro. Ṣugbọn emi o ṣãnu fun ile Juda, emi o si fi Oluwa Ọlọrun wọn gbà wọn là, emi kì yio si fi ọrun, tabi idà, tabi ogun, ẹṣin, tabi ẹlẹṣin gbà wọn là.
Hos 1:1-7 Yoruba Bible (YCE)
Ọ̀rọ̀ tí OLUWA sọ fún Hosia, ọmọ Beeri nìyí, ní àkókò tí Usaya ati Jotamu, ati Ahasi, ati Hesekaya jọba ní ilẹ̀ Juda; tí Jeroboamu, ọmọ Joaṣi, sì jọba ní ilẹ̀ Israẹli. Nígbà tí Ọlọrun kọ́kọ́ bá Israẹli sọ̀rọ̀ láti ẹnu Hosia, Ọlọrun ní, “Lọ fẹ́ obinrin alágbèrè kan, kí o sì bí àwọn ọmọ alágbèrè; nítorí pé àwọn eniyan mi ti ṣe àgbèrè pupọ nípa pé, wọ́n kọ̀ mí sílẹ̀.” Hosia bá lọ fẹ́ iyawo kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Gomeri, ọmọ Dibulaimu. Gomeri lóyún, ó sì bí ọmọkunrin kan fún un. OLUWA sọ fún Hosia pé, “Sọ ọmọ náà ní Jesireeli; nítorí láìpẹ́ yìí ni n óo jẹ ìdílé Jehu níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ìpànìyàn tí ó dá ní Jesireeli, n óo sì fi òpin sí ìjọba Israẹli. Ní ọjọ́ náà, n óo run àwọn ọmọ ogun Israẹli ní àfonífojì Jesireeli.” Gomeri tún lóyún, ó sì bí ọmọbinrin kan. OLUWA tún sọ fún Hosia pé, “Sọ ọmọ náà ní, ‘Kò sí Àánú’; nítorí n kò ní ṣàánú àwọn eniyan Israẹli mọ́, n kò sì ní dáríjì wọ́n mọ́, ṣugbọn n óo fẹ́ràn ilé Juda, n óo sì ṣàánú wọn, èmi OLUWA Ọlọrun wọn yóo gbà wọ́n là, láìlo ọfà ati ọrun, idà tabi ogun, tabi ẹṣin ati àwọn ẹlẹ́ṣin.”
Hos 1:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọ̀rọ̀ OLúWA tí ó tọ Hosea ọmọ Beeri wá ní àkókò ìjọba Ussiah, Jotamu, Ahasi àti Hesekiah; àwọn ọba Juda àti ní àkókò ọba Jeroboamu ọmọ Jehoaṣi ní Israẹli: Nígbà tí OLúWA bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ̀rọ̀ láti ẹnu Hosea, OLúWA wí fún un pé, “Lọ, fẹ́ àgbèrè obìnrin kan fún ara rẹ, kí ó sì bí ọmọ àgbèrè fún ọ nípasẹ̀ àwọn ọkùnrin mìíràn, nítorí ilẹ̀ ti ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè púpọ̀ nípa yíyapa kúrò lọ́dọ̀ OLúWA.” Nígbà náà ni ó sì lọ, ó sì fẹ́ Gomeri ọmọbìnrin Diblaimu, ọmọbìnrin náà sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan fún un. Nígbà náà ni OLúWA sọ fún Hosea pé, “Pe orúkọ ọmọ náà ní Jesreeli, nítorí pé láìpẹ́ ni èmi yóò jẹ ìdílé Jehu ní ìyà fún ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn tó pa ní ìpakúpa ní Jesreeli, Èmi yóò sì mú ìjọba Israẹli wá sí òpin. Ní ọjọ́ náà ni Èmi yóò ṣẹ́ ọrun Israẹli ní Àfonífojì Jesreeli.” Gomeri sì tún lóyún, ó sì bí ọmọbìnrin kan. OLúWA sọ fún un pé, “Pe orúkọ rẹ̀ ní Lo-rúhámà, nítorí pé Èmi kò ní ṣàánú fún ilé Israẹli mọ́, Èmi kò sì ní dáríjì wọ́n. Síbẹ̀, èmi yóò ṣàánú fún ilé Juda, èmi ó gbà wọ́n—kì í ṣe nípa ọfà, idà tàbí ogun, ẹṣin tàbí kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́ṣin bí kò ṣe nípa OLúWA Ọlọ́run wọn.”