Heb 7:18-28

Heb 7:18-28 Yoruba Bible (YCE)

A pa àṣẹ ti àkọ́kọ́ tì nítorí kò lágbára, kò sì wúlò. Nítorí kò sí ohun tí òfin sọ di pípé. A wá ṣe ètò ìrètí tí ó dára ju òfin lọ nípa èyí tí a lè fi súnmọ́ Ọlọrun. Ìrètí yìí ní ìbúra ninu. Àwọn ọmọ Lefi di alufaa láìsí ìbúra. Ṣugbọn pẹlu ìbúra ni, nígbà tí Ọlọrun sọ fún un pé, “Oluwa ti búra, kò ní yí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pada: ‘Ìwọ máa jẹ́ alufaa títí lae.’ ” Báyìí ni Jesu ṣe di onígbọ̀wọ́ majẹmu tí ó dára ju ti àtijọ́ lọ. Àwọn alufaa ìdílé Lefi pọ̀ nítorí ikú kò jẹ́ kí èyíkéyìí ninu wọn lè wà títí ayé. Ṣugbọn ní ti Jesu, ó wà títí. Nítorí náà kò sí ìdí tí a óo fi tún yan alufaa mìíràn dípò rẹ̀. Ìdí nìyí tí ó fi lè gba àwọn tí wọ́n bá súnmọ́ Ọlọrun nípasẹ̀ rẹ̀ là, lọ́nà gbogbo títí lae nítorí pé ó wà láàyè títí láti máa bẹ̀bẹ̀ fún wọn. Irú olórí alufaa bẹ́ẹ̀ ni ó yẹ wá. Ẹni mímọ́; tí kò ní ẹ̀tàn, tí kò ní àbùkù, tí kò bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kẹ́gbẹ́, tí a gbé ga kọjá àwọn ọ̀run. Òun kì í ṣe ẹni tí ó níláti kọ́kọ́ rúbọ lojoojumọ fún ẹ̀ṣẹ̀ ti ara rẹ̀, kí ó tó wá rúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan, bí àwọn olórí alufaa ti ìdílé Lefi ti ń ṣe. Nítorí lẹ́ẹ̀kan náà ni ó ti ṣe èyí, nígbà tí ó fi ara rẹ̀ rúbọ. Nítorí àwọn tí à ń yàn bí olórí alufaa lábẹ́ òfin Mose jẹ́ eniyan, wọ́n sì ní àìlera. Ṣugbọn olórí alufaa tí a yàn nípa ọ̀rọ̀ ìbúra tí ó dé lẹ́yìn òfin ni Ọmọ Ọlọrun tí a ṣe ní àṣepé títí lae.

Heb 7:18-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nítorí a mú òfin ìṣáájú kúrò nítorí àìlera àti àìlérè rẹ̀. (Nítorí òfin kò mú ohunkóhun pé), a sì mú ìrètí tí ó dára jù wá nípa èyí tí àwa ń súnmọ́ Ọlọ́run. Níwọ́n bí ó sì ti ṣe pé kì í ṣe ní àìbúra ni. Nítorí àwọn àlùfáà tẹ́lẹ̀ jẹ oyè láìsí ìbúra, ṣùgbọ́n ti òun jẹ́ pẹ̀lú ìbúra nígbà tí Ọlọ́run wí fún un pé, “Olúwa búra, kí yóò sì yí padà: ‘Ìwọ ni àlùfáà kan títí láé ni ipasẹ̀ ti Mekisédékì.’ ” Níwọ́n bẹ́ẹ̀ ni Jesu ti di onígbọ̀wọ́ májẹ̀mú tí ó dára jù. Àti nítòótọ́ àwọn púpọ̀ ní a ti fi jẹ àlùfáà, nítorí wọn kò lè wà títí nítorí ikú. Ṣùgbọ́n òun, nítorí tí o wà títí láé, ó ní oyè àlùfáà tí a kò lè rọ̀ ní ipò. Nítorí náà ó sì le gbà wọ́n là pẹ̀lú títí dé òpin, ẹni tí ó bá tọ Ọlọ́run wá nípasẹ̀ rẹ̀, nítorí tí o ń bẹ láààyè títí láé láti máa bẹ̀bẹ̀ fún wọn. Nítorí pé irú olórí àlùfáà bẹ́ẹ̀ ni o yẹ wá, mímọ́, àìlẹ́gàn, àìléèérí, tí a yà sọ́tọ̀ kúrò láàrín àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, tí a sì gbéga ju àwọn ọ̀run lọ; Ẹni tí kò ní láti máa rú ẹbọ lójoojúmọ́, bí àwọn olórí àlùfáà, fún ẹ̀ṣẹ̀ ti ara rẹ̀ náà, àti lẹ́yìn náà fún tí àwọn ènìyàn; nítorí èyí ni tí ó ṣe lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, nígbà tí ó fi ara rẹ̀ rú ẹbọ. Nítorí pé òfin a máa fi àwọn ènìyàn tí ó ní àìlera jẹ olórí àlùfáà; ṣùgbọ́n nípa ọ̀rọ̀ ti ìbúra, tí ó ṣe lẹ́yìn òfin, ó fi ọmọ jẹ; ẹni tí a sọ di pípé títí láé.