Heb 6:4-6
Heb 6:4-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori awọn ti a ti là loju lẹ̃kan, ti nwọn si ti tọ́ ẹ̀bùn ọ̀run wò, ti nwọn si ti di alabapin Ẹmí Mimọ́, Ti nwọn si ti tọ́ ọ̀rọ rere Ọlọrun wò, ati agbara aiye ti mbọ̀, Ti nwọn si ti ṣubu kuro, ko le ṣe iṣe lati sọ wọn di ọtun si ironupiwada, nitori nwọn tún kàn Ọmọ Ọlọrun mọ agbelebu si ara wọn li ọtun, nwọn si dojutì i ni gbangba.
Heb 6:4-6 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí àwọn tí a bá ti là lójú, tí wọ́n ti tọ́wò ninu ẹ̀bùn tí ó ti ọ̀run wá, àwọn tí wọ́n ti ní ìpín ninu ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́, tí wọ́n ti tọ́ ire tí ó wà ninu ọ̀rọ̀ Ọlọrun wò, ati agbára ayé tí ó ń bọ̀, tí wọ́n bá wá yipada kúrò ninu ìsìn igbagbọ, kò sí ohun tí a lè ṣe tí wọ́n fi lè tún ronupiwada mọ́, nítorí wọ́n ti tún fi ọwọ́ ara wọn kan Ọmọ Ọlọrun mọ́ agbelebu, wọ́n sọ ikú rẹ̀ di nǹkan àwàdà.
Heb 6:4-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí pé, kò ṣe é ṣe fún àwọn tí a ti là lójú lẹ́ẹ̀kan, tí wọ́n sì ti tọ́ ẹ̀bùn ọ̀run wò, tí wọn sì ti di alábápín Ẹ̀mí Mímọ́, tí wọn sì tọ́ ọ̀rọ̀ rere Ọlọ́run wò, àti agbára ayé tí ń bọ̀, láti tún sọ wọ́n di ọ̀tun sí ìrònúpìwàdà bí wọn bá ṣubú kúrò; nítorí tí wọ́n tún kan ọmọ Ọlọ́run mọ́ àgbélébùú sí ara wọn lọ́tun, wọ́n sì dójútì í ní gbangba.