Heb 6:1-3
Heb 6:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
NITORINA ki a fi ipilẹṣẹ ẹkọ́ Kristi silẹ, ki a lọ si pipé; li aitún fi ipilẹ ironupiwada kuro ninu okú iṣẹ lelẹ, ati ti igbagbọ́ sipa ti Ọlọrun, Ati ti ẹkọ́ ti iwẹnu, ati ti igbọwọle-ni, ati ti ajinde okú, ati ti idajọ ainipẹkun. Eyi li awa ó si ṣe, bi Ọlọrun fẹ.

Heb 6:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á pa ẹ̀kọ́ alakọọbẹrẹ ti ìsìn igbagbọ tì, kí á tẹ̀síwájú láti kọ́ ẹ̀kọ́ tí ó jinlẹ̀. Kí á má tún máa fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ mọ́, ìpìlẹ̀ bí ẹ̀kọ́ nípa ìrònúpìwàdà kúrò ninu àwọn iṣẹ́ tí ó yọrí sí ikú, ẹ̀kọ́ nípa igbagbọ ninu Ọlọrun; ẹ̀kọ́ nípa ìrìbọmi, ìgbé-ọwọ́-lé eniyan lórí, ajinde kúrò ninu òkú, ati ìdájọ́ ìkẹyìn. Ẹ jẹ́ kí á tẹ̀síwájú nípa kíkọ́ ẹ̀kọ́ tí ó jinlẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni a óo sì ṣe, bí Ọlọrun bá fẹ́.
Heb 6:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí náà, ó yẹ kí á fi àwọn ẹ̀kọ́ ìgbà tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gba Kristi sílẹ̀, kí á tẹ̀síwájú nínú àwọn ẹ̀kọ́ tí yóò mú wa dàgbàsókè ní pípé. Láìtún ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ máa tẹnumọ́ ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ bí i ìrònúpìwàdà kúrò nínú òkú iṣẹ́ àti ìgbàgbọ́ nípa ti Ọlọ́run, ti ẹ̀kọ́ àwọn bamitiisi, àti ti ìgbọ́wọ́-léni, ti àjíǹde òkú, àti tí ìdájọ́ àìnípẹ̀kun. Èyí ní àwa yóò sì ṣe bí Ọlọ́run bá fẹ́.