Heb 4:9-12
Heb 4:9-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitorina isimi kan kù fun awọn enia Ọlọrun. Nitoripe ẹniti o ba bọ́ sinu isimi rẹ̀, on pẹlu simi kuro ninu iṣẹ tirẹ̀, gẹgẹ bi Ọlọrun ti simi kuro ni tirẹ̀. Nitorina ẹ jẹ ki a mura giri lati wọ̀ inu isimi na, ki ẹnikẹni ki o má ba ṣubu nipa apẹrẹ aigbagbọ́ kanna. Nitori ọ̀rọ Ọlọrun yè, o si li agbara, o si mú jù idàkídà oloju meji lọ, o si ngúnni ani tìti de pipín ọkàn ati ẹmí niya, ati oríke ati ọrá inu egungun, on si ni olumọ̀ erò inu ati ète ọkàn.
Heb 4:9-12 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí náà, ìsinmi ọjọ́ ìsinmi wà nílẹ̀ fún àwọn eniyan Ọlọrun. Nítorí ẹni tí ó bá wọ inú ìsinmi rẹ̀ ti sinmi ninu iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti sinmi ninu tirẹ̀. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á sa gbogbo ipá wa láti wọ inú ìsinmi náà, kí ẹnikẹ́ni má tẹ̀lé àpẹẹrẹ burúkú ati àìgbọràn bíi ti àwọn tí à ń sọ̀rọ̀ wọn. Nítorí pé ọ̀rọ̀ Ọlọrun wà láàyè, ó sì lágbára. Ó mú ju idà olójú meji lọ. Ó mú tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi lè gé ẹ̀mí kúrò lára ọkàn, ó sì lè rẹ́ mùdùnmúdùn kúrò lára àwọn oríkèé ara. Ó yára láti mọ ète ati èrò ọkàn eniyan.
Heb 4:9-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
nítorí náà ìsinmi kan kù fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run. Nítorí pé ẹni tí ó ba bọ́ sínú ìsinmi rẹ̀, òun pẹ̀lú sinmi kúrò nínú iṣẹ́ tirẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti sinmi kúrò nínú iṣẹ́ tirẹ̀. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á múra gírí láti wọ inú ìsinmi náà, kí ẹnikẹ́ni má ba à ṣubú nípa irú àìgbàgbọ́ kan náà. Nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ní agbára, ó sì mu ju idàkídà olójú méjì lọ, ó sì ń gún ni, àní títí dé pínpín ọkàn àti ẹ̀mí ní yà, àti ní oríkèé àti ọ̀rá inú egungun, òun sì ni olùmọ̀ èrò inú àti ète ọkàn.