Heb 2:2-3
Heb 2:2-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori bi ọ̀rọ ti a ti ẹnu awọn angẹli sọ ba duro ṣinṣin, ati ti olukuluku irekọja ati aigbọran si gbà ẹsan ti o tọ́; Awa o ti ṣe là a, bi awa kò ba nani irú igbala nla bi eyi; ti àtetekọ bẹ̀rẹ si isọ lati ọdọ Oluwa, ti a si fi mulẹ fun wa lati ọdọ awọn ẹniti o gbọ́
Heb 2:2-3 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí bí ọ̀rọ̀ tí ó ti ẹnu àwọn angẹli sọ bá fẹsẹ̀ múlẹ̀, tí gbogbo ìwà àìṣedéédé ati ìwà àìgbọràn bá gba ìbáwí tí ó tọ́ sí wọn, báwo ni a óo ti ṣe sá àsálà, tí a bá kọ etí-ikún sí ìgbàlà tí ó tóbi tó báyìí? Oluwa fúnrarẹ̀ ni ó kọ́kọ́ kéde ìgbàlà yìí ní ìbẹ̀rẹ̀. Àwọn tí wọ́n gbọ́ ni wọ́n fún wa ní ìdánilójú pé bẹ́ẹ̀ ni ó rí.
Heb 2:2-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí bí ọ̀rọ̀ tí a tí ẹnu àwọn angẹli sọ bá sì dúró ṣinṣin, àti tí olúkúlùkù ẹ̀ṣẹ̀ sí òfin àti àìgbọ́ràn gba ìjìyà tí ó tọ́ sí i, kín ni ohun náà tí ó mú wa lérò pé a lè bọ́ kúrò nínú ìjìyà bí a kò bá náání ìgbàlà ńlá yìí? Ìgbàlà tí Olúwa fúnrarẹ̀ kọ́kọ́ kéde, èyí tí a sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ fún wa láti ọwọ́ àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà lẹ́nu rẹ̀.