Heb 11:8-22

Heb 11:8-22 Bibeli Mimọ (YBCV)

Nipa igbagbọ́ ni Abrahamu, nigbati a ti pè e lati jade lọ si ibi ti on yio gbà fun ilẹ-ini, o gbọ́, o si jade lọ, lai mọ̀ ibiti on nrè. Nipa igbagbọ́ li o ṣe atipo ni ilẹ ileri, bi ẹnipe ni ilẹ àjeji, o ngbé inu agọ́, pẹlu Isaaki ati Jakọbu, awọn ajogún ileri kanna pẹlu rẹ̀: Nitoriti o nreti ilu ti o ni ipilẹ̀; eyiti Ọlọrun tẹ̀do ti o si kọ́. Nipa igbagbọ́ ni Sara tikararẹ̀ pẹlu fi ni agbara lati lóyun, nigbati o kọja ìgba rẹ̀, nitoriti o kà ẹniti o ṣe ileri si olõtọ. Nitorina li ọ̀pọlọpọ ṣe ti ara ẹnikan jade, ani ara ẹniti o dabi okú, ọ̀pọ bi irawọ oju ọrun li ọ̀pọlọpọ, ati bi iyanrin eti okun li ainiye. Gbogbo awọn wọnyi li o kú ni igbagbọ́, lai ri ileri wọnni gbà, ṣugbọn ti nwọn ri wọn li òkere rere, ti nwọn si gbá wọn mú, ti nwọn si jẹwọ pe alejò ati atipò li awọn lori ilẹ aiye. Nitoripe awọn ti o nsọ irú ohun bẹ̃, fihan gbangba pe, nwọn nṣe afẹri ilu kan ti iṣe tiwọn. Ati nitõtọ, ibaṣepe nwọn fi ilu tí nwọn ti jade wa si ọkàn, nwọn iba ti ri aye lati pada. Ṣugbọn nisisiyi nwọn nfẹ ilu kan ti o dara jù bẹ̃ lọ, eyini ni ti ọ̀run: nitorina oju wọn kò ti Ọlọrun, pe ki a mã pe On ni Ọlọrun wọn; nitoriti o ti pèse ilu kan silẹ fun wọn. Nipa igbagbọ́ ni Abrahamu, nigbati a dán a wò, fi Isaaki rubọ: ẹniti o si ti fi ayọ̀ gbà ileri wọnni fi ọmọ-bíbi rẹ̀ kanṣoṣo rubọ. Niti ẹniti a wipe, Ninu Isaaki li a o ti pè irú-ọmọ rẹ: O si pari rẹ̀ si pe Ọlọrun tilẹ le gbe e dide, ani kuro ninu oku, ati ibiti o ti gbà a pada pẹlu ni apẹrẹ. Nipa igbagbọ́ ni Isaaki sure fun Jakọbu ati Esau niti ohun ti mbọ̀. Nipa igbagbọ́ ni Jakọbu, nigbati o nkú lọ, o súre fun awọn ọmọ Josefu ni ọ̀kọ̃kan; o si tẹriba, o simi le ori ọpá rẹ̀. Nipa igbagbọ́ ni Josefu, nigbati o nkú lọ, o ranti ìjadelọ awọn ọmọ Israeli; o si paṣẹ niti awọn egungun rẹ̀.

Heb 11:8-22 Yoruba Bible (YCE)

Nípa igbagbọ ni Abrahamu fi gbà nígbà tí Ọlọrun pè é pé kí ó jáde lọ sí ilẹ̀ tí òun óo fún un. Ó jáde lọ láìmọ̀ ibi tí ó ń lọ. Nípa igbagbọ ni ó fi ń gbé ilẹ̀ ìlérí bí àlejò, ó ń gbé inú àgọ́ bíi Isaaki ati Jakọbu, àwọn tí wọn óo jọ jogún ìlérí kan náà. Nítorí ó ń retí ìlú tí ó ní ìpìlẹ̀, tí ó jẹ́ pé Ọlọrun ni ó ṣe ètò rẹ̀ tí ó sì kọ́ ọ. Nípa igbagbọ, Abrahamu ní agbára láti bímọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Sara yàgàn, ó sì ti dàgbà kọjá ọmọ bíbí, Abrahamu gbà pé ẹni tí ó ṣèlérí tó gbẹ́kẹ̀lé. Nítorí èyí, láti ọ̀dọ̀ ẹyọ ọkunrin kan, tí ó ti dàgbà títí, tí ó ti kú sára, ni ọpọlọpọ ọmọ ti jáde, wọ́n pọ̀ bíi ìràwọ̀ ojú ọ̀run, ati bíi iyanrìn etí òkun. Gbogbo àwọn wọnyi kú ninu igbagbọ. Wọn kò rí ohun tí Ọlọrun ṣe ìlérí gbà, òkèèrè ni wọ́n ti rí i, wọ́n sì ń fi ayọ̀ retí rẹ̀. Wọ́n jẹ́wọ́ pé àlejò tí ń rékọjá lọ ni àwọn ní ayé. Àwọn eniyan tí ó bá ń sọ̀rọ̀ báyìí fihàn pé wọ́n ń wá ìlú ti ara wọn. Bí ó bá jẹ́ pé wọ́n tún ń ronú ti ibi tí wọ́n ti jáde wá, wọn ìbá ti wá ààyè láti pada sibẹ. Ṣugbọn wọ́n ń dàníyàn fún ìlú tí ó dára ju èyí tí wọ́n ti jáde kúrò lọ, tíí ṣe ìlú ti ọ̀run. Nítorí náà Ọlọrun kò tijú pé kí á pe òun ní Ọlọrun wọn, nítorí ó ti ṣe ètò ìlú kan fún wọn. Nípa igbagbọ ni Abrahamu fi Isaaki rúbọ nígbà tí Ọlọrun dán an wò. Ó fi ààyò ọmọ rẹ̀ rúbọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọrun ti ṣe ìlérí fún un nípa rẹ̀, tí Ọlọrun ti sọ fún un pé, “Láti inú Isaaki ni ìdílé rẹ yóo ti gbilẹ̀.” Èrò rẹ̀ ni pé Ọlọrun lè tún jí eniyan dìde ninu òkú. Nítorí èyí, àfi bí ẹni pé ó tún gba ọmọ náà pada láti inú òkú. Nípa igbagbọ ni Isaaki fi súre fún Jakọbu ati Esau tí ó sì sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí wọn. Nígbà tí Jakọbu ń kú lọ, nípa igbagbọ ni ó fi súre fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Josẹfu. Ó ń sin Ọlọrun bí ó ti tẹríba lórí ọ̀pá rẹ̀. Nígbà tí ó tó àkókò tí Josẹfu yóo kú, nípa igbagbọ ni ó fi ranti pé àwọn ọmọ Israẹli yóo jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, tí ó sì sọ bí òun ti fẹ́ kí wọ́n ṣe egungun òun.

Heb 11:8-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nípa ìgbàgbọ́ ní Abrahamu, nígbà tí a ti pé e láti jáde lọ sí ibi tí òun yóò gbà fún ilẹ̀ ìní, ó gbọ́, ó sì jáde lọ, láì mọ ibi tí òun ń rè. Nípa ìgbàgbọ́ ní o ṣe àtìpó ní ilẹ̀ ìlérí, bí ẹni pé ni ilẹ̀ àjèjì, o ń gbé inú àgọ́, pẹ̀lú Isaaki àti Jakọbu, àwọn ajogún ìlérí kan náà pẹ̀lú rẹ̀: Nítorí tí ó ń retí ìlú tí ó ní ìpìlẹ̀; èyí tí Ọlọ́run tẹ̀dó tí ó sì kọ́. Nípa ìgbàgbọ́ ni Sara tìkára rẹ̀ pẹ̀lú fi gba agbára láti lóyún, nígbà tí ó kọjá ìgbà rẹ̀, nítorí tí o ka ẹni tí o ṣe ìlérí sí olóòótọ́. Nítorí náà ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ṣe ti ara ọkùnrin kan jáde, àní ara ẹni tí o dàbí òkú, ọmọ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run lọ́pọ̀lọpọ̀, àti bí iyanrìn etí Òkun láìníye. Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ó kú nínú ìgbàgbọ́, láìrí àwọn ìlérí náà gbà, ṣùgbọ́n tí wọn rí wọn ni òkèrè réré, tí wọ́n sì gbá wọn mú, tí wọ́n sì jẹ́wọ́ pé àlejò àti àjèjì ni àwọn lórí ilẹ̀ ayé. Nítorí pé àwọn tí o ń sọ irú ohun bẹ́ẹ̀ fihàn gbangba pé, wọn ń ṣe àfẹ́rí ìlú kan tí i ṣe tiwọn. Àti nítòótọ́, ìbá ṣe pé wọ́n fi ìlú tiwọn tí jáde wá sí ọkàn, wọn ìbá ti rí ààyè padà. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n ń fẹ́ ìlú kan tí o dára jù bẹ́ẹ̀ lọ, èyí yìí ni ti ọ̀run: nítorí náà ojú wọn kò ti Ọlọ́run, pé kí a máa pé òun ni Ọlọ́run wọn; nítorí tí o ti pèsè ìlú kan sílẹ̀ fún wọn. Nípa ìgbàgbọ́ ni Abrahamu, nígbà tí a dán an wò láti, fi Isaaki rú ẹbọ: àní òun ẹni tí ó rí ìlérí gba múra tan láti fi ọmọ bíbí rẹ kan ṣoṣo rú ẹbọ. Nípa ẹni tí wí pé, “Nínú Isaaki ni a ó ti pe irú-ọmọ rẹ̀:” Ó sì rò ó si pé Ọlọ́run tilẹ̀ lè gbé e dìde kúrò nínú òkú, bẹ́ẹ̀ ni, bí a bá sọ ọ́ lọ́nà àpẹẹrẹ, ó gbà á padà. Nípa ìgbàgbọ́ ní Isaaki súre fún Jakọbu àti Esau ní ti ohun tí ń bọ̀. Nípa ìgbàgbọ́ ni Jakọbu, nígbà tí o ń ku lọ, ó súre fún àwọn ọmọ Josẹfu ni ọ̀kọ̀ọ̀kan; ó sì sinmi ní ìtẹríba lé orí ọ̀pá rẹ̀. Nípa ìgbàgbọ́ ni Josẹfu, nígbà tí ó ń ku lọ, ó rántí ìjáde lọ àwọn ọmọ Israẹli; ó sì pàṣẹ ní ti àwọn egungun rẹ̀.