Heb 1:1-2
Heb 1:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
ỌLỌRUN, ẹni, ni igba pupọ̀ ati li onirũru ọna, ti o ti ipa awọn woli ba awọn baba sọ̀rọ nigbãni. Ni ikẹhin ọjọ wọnyi o ti ipasẹ Ọmọ rẹ̀ ba wa sọ̀rọ, ẹniti o fi ṣe ajogun ohun gbogbo, nipasẹ ẹniti o dá awọn aiye pẹlu
Heb 1:1-2 Yoruba Bible (YCE)
Ní ìgbà àtijọ́, oríṣìíríṣìí ọ̀nà ni Ọlọrun fi ń bá àwọn baba wa sọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn wolii rẹ̀. Ní àkókò ìkẹyìn yìí, ó wá bá wa sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀, ẹni tí ó fi ṣe àrólé ohun gbogbo, nípasẹ̀ ẹni tí ó dá ayé.
Heb 1:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ìgbà àtijọ́, Ọlọ́run bá àwọn baba ńlá wa sọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì ní ọ̀pọ̀ ìgbà àti ní onírúurú ọ̀nà, ṣùgbọ́n ní ìgbà ìkẹyìn yìí Ọlọ́run ń bá wa sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi, ẹni tí ó fi ṣe ajogún ohun gbogbo, nípasẹ̀ ẹni tí ó dá gbogbo ayé yìí àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀