Hag 2:6-9
Hag 2:6-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori bayi ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, pe, Ẹ̃kan ṣa, nigbà diẹ si i, li emi o mì awọn ọrun, ati aiye, ati okun, ati iyàngbẹ ilẹ. Emi o si mì gbogbo orilẹ-ède, ifẹ gbogbo orilẹ-ède yio si de: emi o si fi ogo kún ile yi, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. Temi ni fàdakà, temi si ni wurà, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. Ogo ile ikẹhìn yi yio pọ̀ jù ti iṣãju lọ, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi: nihinyi li emi o si fi alafia fun ni, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
Hag 2:6-9 Yoruba Bible (YCE)
“Nítorí pé èmi, OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ ọ́ pé láìpẹ́, n óo tún mi ọ̀run ati ayé jìgìjìgì lẹ́ẹ̀kan sí i, ati òkun ati ilẹ̀. N óo mi gbogbo orílẹ̀-èdè, wọn óo kó ìṣúra wọn wá, n óo sì ṣe ilé yìí lọ́ṣọ̀ọ́. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí. Tèmi ni gbogbo fadaka ati wúrà tí ó wà láyé; èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Ògo tí ilé yìí yóo ní tó bá yá, yóo ju ti àtijọ́ lọ. N óo fún àwọn eniyan mi ní alaafia ati ibukun ninu rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí.”
Hag 2:6-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Báyìí ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí pé: ‘Láìpẹ́ jọjọ, Èmi yóò mi àwọn ọrun àti ayé, Òkun àti ìyàngbẹ ilẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i. Èmi yóò mi gbogbo orílẹ̀-èdè, ìfẹ́ gbogbo orílẹ̀-èdè yóò fà sí tẹmpili yìí, Èmi yóò sì kún ilé yìí pẹ̀lú ògo;’ ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí. ‘Tèmi ni fàdákà àti wúrà,’ ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí. ‘Ògo ìkẹyìn ilé yìí yóò pọ̀ ju ti ìṣáájú lọ;’ ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Àti ní ìhín yìí ni Èmi ó sì fi àlàáfíà fún ni,’ ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí.”