Hag 2:3-9
Hag 2:3-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Tali o kù ninu nyin ti o ti ri ile yi li ogo rẹ̀ akọṣe? bawo li ẹnyin si ti ri i si nisisiyi? kò ha dàbi asan loju nyin bi a fi ṣe akawe rẹ̀? Ṣugbọn nisisiyi mura giri, Iwọ Serubbabeli, li Oluwa wi, ki o si mura giri, Iwọ Joṣua, ọmọ Josedeki, olori alufa; ẹ si mura giri gbogbo ẹnyin enia ilẹ na, li Oluwa wi, ki ẹ si ṣiṣẹ: nitori emi wà pẹlu nyin, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. Gẹgẹ bi ọ̀rọ ti mo ba nyin dá majẹmu nigbati ẹnyin ti Egipti jade wá, bẹ̃ni ẹmi mi wà lãrin nyin: ẹ máṣe bẹ̀ru. Nitori bayi ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, pe, Ẹ̃kan ṣa, nigbà diẹ si i, li emi o mì awọn ọrun, ati aiye, ati okun, ati iyàngbẹ ilẹ. Emi o si mì gbogbo orilẹ-ède, ifẹ gbogbo orilẹ-ède yio si de: emi o si fi ogo kún ile yi, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. Temi ni fàdakà, temi si ni wurà, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. Ogo ile ikẹhìn yi yio pọ̀ jù ti iṣãju lọ, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi: nihinyi li emi o si fi alafia fun ni, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
Hag 2:3-9 Yoruba Bible (YCE)
‘Àwọn wo ni wọ́n ṣẹ́kù ninu yín tí wọ́n rí i bí ẹwà ògo ilé yìí ti pọ̀ tó tẹ́lẹ̀? Báwo ni ẹ ti rí i sí nisinsinyii? Ǹjẹ́ ó jẹ́ nǹkankan lójú yín? Ṣugbọn, mú ọkàn le, ìwọ Serubabeli, má sì fòyà, ìwọ Joṣua, ọmọ Jehosadaki, olórí alufaa; ẹ ṣe ara gírí kí ẹ sì ṣe iṣẹ́ náà ẹ̀yin eniyan; nítorí mo wà pẹlu yín. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA wí. Gẹ́gẹ́ bí ìlérí tí mo ṣe fun yín, nígbà tí ẹ jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, mo wà láàrin yín; nítorí náà, ẹ má ṣe bẹ̀rù.’ “Nítorí pé èmi, OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ ọ́ pé láìpẹ́, n óo tún mi ọ̀run ati ayé jìgìjìgì lẹ́ẹ̀kan sí i, ati òkun ati ilẹ̀. N óo mi gbogbo orílẹ̀-èdè, wọn óo kó ìṣúra wọn wá, n óo sì ṣe ilé yìí lọ́ṣọ̀ọ́. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí. Tèmi ni gbogbo fadaka ati wúrà tí ó wà láyé; èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Ògo tí ilé yìí yóo ní tó bá yá, yóo ju ti àtijọ́ lọ. N óo fún àwọn eniyan mi ní alaafia ati ibukun ninu rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí.”
Hag 2:3-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
‘Ta ni nínú yín tí ó kù tí ó sì ti rí ilé yìí ní ògo rẹ̀ àkọ́kọ́? Báwo ni ó ṣe ri sí yín nísinsin yìí? Ǹjẹ́ kò dàbí asán lójú yín? Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, múra gírí, ìwọ Serubbabeli,’ ni OLúWA wí. ‘Múra gírí, ìwọ Joṣua ọmọ Josadaki, olórí àlùfáà. Ẹ sì múra gírí gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ilẹ̀ náà;’ ni OLúWA wí, ‘kí ẹ sì ṣiṣẹ́. Nítorí èmi wà pẹ̀lú yín;’ ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí. ‘Èyí ni ohun tí Èmi fi bá a yín dá májẹ̀mú nígbà tí ẹ jáde kúrò ní Ejibiti, bẹ́ẹ̀ ni Ẹ̀mí ì mi sì wà pẹ̀lú yín. Ẹ má ṣe bẹ̀rù.’ “Báyìí ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí pé: ‘Láìpẹ́ jọjọ, Èmi yóò mi àwọn ọrun àti ayé, Òkun àti ìyàngbẹ ilẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i. Èmi yóò mi gbogbo orílẹ̀-èdè, ìfẹ́ gbogbo orílẹ̀-èdè yóò fà sí tẹmpili yìí, Èmi yóò sì kún ilé yìí pẹ̀lú ògo;’ ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí. ‘Tèmi ni fàdákà àti wúrà,’ ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí. ‘Ògo ìkẹyìn ilé yìí yóò pọ̀ ju ti ìṣáájú lọ;’ ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Àti ní ìhín yìí ni Èmi ó sì fi àlàáfíà fún ni,’ ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí.”