Hag 1:1-5
Hag 1:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
LI ọdun keji Dariusi ọba, li oṣù kẹfa, li ọjọ ekini oṣù na, ọ̀rọ Oluwa wá, nipa ọwọ Hagai woli, sọdọ Serubbabeli ọmọ Ṣealtieli, bãlẹ Juda, ati sọdọ Joṣua ọmọ Josedeki, olori alufa, wipe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, Awọn enia wọnyi nsọ pe, Akokò kò ti ide, akokò ti a ba fi kọ́ ile Oluwa. Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa wá nipa Hagai woli, wipe, Akokò ha ni fun nyin, ẹnyin, lati ma gbe ile ọṣọ nyin, ṣugbọn ile yi wà li ahoro? Njẹ nisisiyi bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wipe, Ẹ kiyesi ọ̀na nyin.
Hag 1:1-5 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọjọ́ kinni, oṣù kẹfa, ọdún keji ìjọba Dariusi, OLUWA rán wolii Hagai sí Serubabeli, ọmọ Ṣealitieli, gomina ilẹ̀ Juda, ati sí Joṣua ọmọ Jehosadaki, olórí alufaa. OLUWA àwọn ọmọ ogun ní: “Àwọn eniyan wọnyi ní, kò tíì tó àkókò láti tún Tẹmpili kọ́.” Nítorí náà ni OLUWA ṣe rán wolii Hagai sí wọn ó ní, “Ẹ̀yin eniyan mi, ṣé àkókò nìyí láti máa gbé inú ilé tiyín tí ẹ ṣe lọ́ṣọ̀ọ́, nígbà tí Tẹmpili wà ní àlàpà? Nítorí náà, nisinsinyii, ẹ kíyèsí àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ si yín
Hag 1:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ọdún kejì ọba Dariusi ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kẹfà, ọ̀rọ̀ OLúWA wá nípasẹ̀ wòlíì Hagai sí Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli, baálẹ̀ Juda, àti Sọ́dọ̀ Joṣua ọmọ Josadaki, olórí àlùfáà. Báyìí ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí: “Àwọn ènìyàn wọ̀nyí wí pé, ‘Kò tí ì tó àkókò láti kọ́ ilé OLúWA.’ ” Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ OLúWA wá láti ọ̀dọ̀ wòlíì Hagai wí pé: “Ǹjẹ́ àkókò ni fún ẹ̀yin fúnrayín láti máa gbé ní ilé tí a ṣe ní ọ̀ṣọ́ nígbà tí ilé yìí wà ni ahoro?” Ní ṣinṣin yìí, èyí ni ohun tí OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí: “Ẹ kíyèsi ọ̀nà yín.