Hag 1:1-11
Hag 1:1-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
LI ọdun keji Dariusi ọba, li oṣù kẹfa, li ọjọ ekini oṣù na, ọ̀rọ Oluwa wá, nipa ọwọ Hagai woli, sọdọ Serubbabeli ọmọ Ṣealtieli, bãlẹ Juda, ati sọdọ Joṣua ọmọ Josedeki, olori alufa, wipe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, Awọn enia wọnyi nsọ pe, Akokò kò ti ide, akokò ti a ba fi kọ́ ile Oluwa. Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa wá nipa Hagai woli, wipe, Akokò ha ni fun nyin, ẹnyin, lati ma gbe ile ọṣọ nyin, ṣugbọn ile yi wà li ahoro? Njẹ nisisiyi bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wipe, Ẹ kiyesi ọ̀na nyin. Ẹnyin ti fọ́n irugbin pupọ̀, ẹ si mu diẹ wá ile; ẹnyin njẹ, ṣugbọn ẹnyin kò yo: ẹnyin nmu, ṣugbọn kò tẹ nyin lọrun; ẹnyin mbora, ṣugbọn kò si ẹniti o gboná; ẹniti o si ngbowo ọ̀ya ńgbà a sinu ajadi àpo. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi: Ẹ kiyesi ọ̀na nyin. Ẹ gùn ori oke-nla lọ, ẹ si mu igi wá, ki ẹ si kọ́ ile na; inu mi yio si dùn si i, a o si yìn mi logo, li Oluwa wi. Ẹnyin tí nreti ọ̀pọ, ṣugbọn kiyesi i, diẹ ni; nigbati ẹnyin si mu u wá ile, mo si fẹ ẹ danù. Nitori kini? li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. Nitori ti ile mi ti o dahoro; ti olukuluku nyin si nsare fun ile ara rẹ̀. Nitorina ni a ṣe dá ìri ọrun duro lori nyin, a si da eso ilẹ duro. Mo si ti pè ọdá sori ilẹ, ati sori oke-nla, ati sori ọkà ati sori ọti-waini titún, ati sori ororo, ati sori ohun ti ilẹ mu jade, ati sori enia, ati sori ẹran, ati sori gbogbo iṣẹ ọwọ ẹni.
Hag 1:1-11 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọjọ́ kinni, oṣù kẹfa, ọdún keji ìjọba Dariusi, OLUWA rán wolii Hagai sí Serubabeli, ọmọ Ṣealitieli, gomina ilẹ̀ Juda, ati sí Joṣua ọmọ Jehosadaki, olórí alufaa. OLUWA àwọn ọmọ ogun ní: “Àwọn eniyan wọnyi ní, kò tíì tó àkókò láti tún Tẹmpili kọ́.” Nítorí náà ni OLUWA ṣe rán wolii Hagai sí wọn ó ní, “Ẹ̀yin eniyan mi, ṣé àkókò nìyí láti máa gbé inú ilé tiyín tí ẹ ṣe lọ́ṣọ̀ọ́, nígbà tí Tẹmpili wà ní àlàpà? Nítorí náà, nisinsinyii, ẹ kíyèsí àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ si yín: Ohun ọ̀gbìn pupọ ni ẹ gbìn, ṣugbọn díẹ̀ ni ẹ kórè; ẹ jẹun, ṣugbọn ẹ kò yó; ẹ mu, ṣugbọn kò tẹ yín lọ́rùn; ẹ wọṣọ, sibẹ òtútù tún ń mu yín. Àwọn tí wọn ń gba owó iṣẹ́ wọn, inú ajádìí-àpò ni wọ́n ń gbà á sí. Ẹ kíyèsí àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ si yín. Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Ẹ lọ sórí àwọn òkè, kí ẹ gé igi ìrólé láti kọ́ ilé náà, kí inú mi lè dùn sí i, kí n sì lè farahàn ninu ògo mi. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA wí. “Ẹ̀ ń retí ọ̀pọ̀ ìkórè, ṣugbọn díẹ̀ ni ẹ̀ ń rí; nígbà tí ẹ sì mú díẹ̀ náà wálé, èmi á gbọ̀n ọ́n dànù. Mò ń bi yín, ǹjẹ́ ẹ mọ ohun tí ó fà á? Ìdí rẹ̀ ni pé, ẹ fi ilé mi sílẹ̀ ní òkítì àlàpà, olukuluku sì múra sí kíkọ́ ilé tirẹ̀. Ìdí nìyí tí ìrì kò fi sẹ̀ láti òkè ọ̀run wá, tí ilẹ̀ kò sì fi so èso bí ó ti yẹ. Mo mú ọ̀gbẹlẹ̀ wá sórí ilẹ̀, ati sórí àwọn òkè, ati oko ọkà, ati ọgbà àjàrà ati ọgbà igi olifi. Bẹ́ẹ̀ náà ló kan gbogbo ohun tí ń hù lórí ilẹ̀, ati eniyan ati ẹran ọ̀sìn, ati gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ eniyan.”
Hag 1:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ọdún kejì ọba Dariusi ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kẹfà, ọ̀rọ̀ OLúWA wá nípasẹ̀ wòlíì Hagai sí Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli, baálẹ̀ Juda, àti Sọ́dọ̀ Joṣua ọmọ Josadaki, olórí àlùfáà. Báyìí ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí: “Àwọn ènìyàn wọ̀nyí wí pé, ‘Kò tí ì tó àkókò láti kọ́ ilé OLúWA.’ ” Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ OLúWA wá láti ọ̀dọ̀ wòlíì Hagai wí pé: “Ǹjẹ́ àkókò ni fún ẹ̀yin fúnrayín láti máa gbé ní ilé tí a ṣe ní ọ̀ṣọ́ nígbà tí ilé yìí wà ni ahoro?” Ní ṣinṣin yìí, èyí ni ohun tí OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí: “Ẹ kíyèsi ọ̀nà yín. Ẹ̀yin ti gbìn ohun ti ó pọ̀. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kórè díẹ̀ níbẹ̀; Ẹ̀yin jẹun, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò yó. Ẹ̀yin mu ṣùgbọ́n kò tẹ́ ẹ yín lọ́run; ẹ̀yin wọ aṣọ, ṣùgbọ́n kò mú òtútù yin lọ; ẹyin gba owó iṣẹ́ ṣùgbọ́n ẹ ń gbà á sínú ajádìí àpò.” Báyìí ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí: “Ẹ kíyèsi ọ̀nà yín. Ẹ gun orí àwọn òkè ńlá lọ, kí ẹ sì mú igi wá pẹ̀lú yín. Kí ẹ sì kọ́ ilé náà, kí inú mi bà le è dùn sí i, kí a sì yín mí lógo,” ni OLúWA wí. “Ẹyin ti ń retí ọ̀pọ̀, ṣùgbọ́n kíyèsi i, o yípadà sí díẹ̀. Ohun tí ẹ̀yin mú wa ilé, èmi sì fẹ́ ẹ dànù. Nítorí kí ni?” ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí. “Nítorí ilé mi tí ó dahoro; tí olúkúlùkù yín sì ń sáré fún ilé ara rẹ̀. Nítorí yín ni àwọn ọ̀run ṣe dá ìrì dúró tí ilẹ̀ sì kọ̀ láti mu èso jáde. Mo sì ti pe ọ̀dá sórí ilẹ̀ àti sórí àwọn òkè ńlá, sórí ọkà àti sórí wáìnì tuntun, sórí òróró àti sórí ohun ti ilẹ̀ ń mú jáde, sórí ènìyàn, sórí ẹran àti sórí gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín.”