Hab 3:2-6
Hab 3:2-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Oluwa, mo ti gbọ́ ohùn rẹ, ẹ̀ru si bà mi: Oluwa, mu iṣẹ rẹ sọji lãrin ọdun, lãrin ọdun sọ wọn di mimọ̀; ni ibinu ranti ãnu. Ọlọrun yio ti Temani wá, ati Ẹni Mimọ́ lati oke Parani. Ogo rẹ̀ bò awọn ọrun, ilẹ aiye si kun fun iyìn rẹ̀. Didán rẹ̀ si dabi imọlẹ; itanṣan nti iha rẹ̀ wá: nibẹ̀ si ni ipamọ agbara rẹ̀ wà. Ajàkalẹ arùn nlọ niwaju rẹ̀, ati okunrun njade lati ẹsẹ̀ rẹ̀ lọ. O duro, o si wọ̀n ilẹ aiye: o wò, o si mu awọn orilẹ-ède warìri; a si tú awọn oke-nla aiyeraiye ká, awọn òkèkékèké aiyeraiye si tẹba: ọ̀na rẹ̀ aiyeraiye ni.
Hab 3:2-6 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA, mo ti gbọ́ òkìkí rẹ, mo sì bẹ̀rù iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. Gbogbo bí ò ó tíí ṣe tí à ń gbọ́; tún wá ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tiwa; sì ranti àánú ní àkókò ibinu rẹ. OLUWA wá láti Temani, Ẹni Mímọ́ sì wá láti òkè Parani. Ògo rẹ̀ bo ojú ọ̀run, gbogbo ayé sì kún fún ìyìn rẹ̀. Dídán rẹ̀ dàbí ọ̀sán gangan, ìtànṣán ń ti ọwọ́ rẹ̀ jáde; níbẹ̀ ni ó fi agbára rẹ̀ pamọ́ sí. Àjàkálẹ̀ àrùn ń lọ níwájú rẹ̀, ìyọnu sì ń tẹ̀lé e lẹ́yìn pẹ́kípẹ́kí. Ó dúró, ó wọn ayé; Ó wo ayé, ó sì mi àwọn orílẹ̀-èdè tìtì; àwọn òkè ńláńlá ayérayé túká, àwọn òkè àtayébáyé sì wọlẹ̀. Ọ̀nà àtayébáyé ni ọ̀nà rẹ̀.
Hab 3:2-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA mo tí gbọ́ ohùn rẹ; ẹ̀rù sì ba mi fún iṣẹ́ rẹ OLúWA sọ wọn di ọ̀tún ní ọjọ́ ti wa, ní àkókò tiwa, jẹ́ kó di mí mọ̀; ni ìbínú, rántí àánú. Ọlọ́run yóò wa láti Temani, ibi mímọ́ jùlọ láti Òkè Parani ògo rẹ̀ sí bo àwọn ọ̀run, ilé ayé sì kún fún ìyìn rẹ Dídán rẹ sí dàbí ìmọ́lẹ̀ oòrùn ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ jáde wa láti ọwọ́ rẹ, níbi tí wọn fi agbára rẹ̀ pamọ́ sí. Àjàkálẹ̀-ààrùn ń lọ ni iwájú rẹ; ìyọnu sí ń tọ ẹsẹ̀ rẹ lọ. Ó dúró, ó sì mi ayé; ó wò, ó sì mú àwọn orílẹ̀-èdè wárìrì a sì tú àwọn òkè ńlá ayérayé ká, àwọn òkè kéékèèkéé ayérayé sì tẹríba: ọ̀nà rẹ ayérayé ni.