Hab 2:1-2
Hab 2:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
LORI ibuṣọ́ mi li emi o duro, emi o si gbe ara mi kà ori alore, emi o si ṣọ lati ri ohun ti yio sọ fun mi, ati èsi ti emi o fọ́, nigbati a ba mba mi wi. Oluwa si da mi lohùn, o si wipe, Kọ iran na, ki o si hàn a lara wàlã, ki ẹniti nkà a, le ma sare.
Hab 2:1-2 Yoruba Bible (YCE)
N óo dúró sí ibìkan lórí ilé-ìṣọ́, n óo máa wòran. N óo dúró, n óo máa retí ohun tí yóo sọ fún mi, ati irú èsì tí èmi náà óo fún un. OLUWA dá mi lóhùn, ó ní: “Kọ ìran yìí sílẹ̀; kọ ọ́ sórí tabili kí ó hàn ketekete, kí ó lè rọrùn fún ẹni tí ń sáré lọ láti kà á.
Hab 2:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi yóò dúró lórí ibusọ́ mi láti máa wòye Èmi yóò sì gbé ara mi ka orí alóre Èmi yóò si ṣọ́ láti gbọ́ ohun tí yóò sọ fún mi àti èsì ti èmi yóò fún ẹ̀sùn yìí nígbà tó bá ń bá mi wí. OLúWA Nígbà náà ni OLúWA dáhùn pé: “Kọ ìṣípayá náà sílẹ̀ kí o sì fi hàn ketekete lórí wàláà kí ẹni tí ń kà á, lè máa sáré.