Hab 1:1-3
Hab 1:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọ̀rọ-ìmọ ti Habakuku wolii rí. Oluwa, emi o ti ke pẹ to, ti iwọ kì yio fi gbọ́! ti emi o kigbe si ọ, niti ìwa-ipa, ti iwọ kì yio si gbalà! Ẽṣe ti o mu mi ri aiṣedede, ti o si jẹ ki nma wò ìwa-ìka? nitori ikógun ati ìwa-ipá wà niwaju mi: awọn ti si nrú ijà ati ãwọ̀ soke mbẹ.
Hab 1:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Ìran tí Ọlọrun fihan wolii Habakuku nìyí. OLUWA, yóo ti pẹ́ tó, tí n óo máa ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́; tí o kò sì ní dá mi lóhùn? Tí n óo máa ké pé, “Wo ìwà ipá!” tí o kò sì ní gba olúwarẹ̀ sílẹ̀? Kí ló dé tí o fi ń jẹ́ kí n máa rí àwọn nǹkan tí kò tọ́, tí o jẹ́ kí n máa rí ìyọnu? Ìparun ati ìwà ipá wà níwájú mi, ìjà ati aáwọ̀ sì wà níbi gbogbo.
Hab 1:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àsọtẹ́lẹ̀ tí wòlíì Habakuku rí. OLúWA, èmi yóò ti ké pẹ́ tó fún ìrànlọ́wọ́, Ṣùgbọ́n ti ìwọ kò ni fetí sí mi? Tàbí kígbe sí ọ ní ti, “Ìwà ipá!” ṣùgbọ́n tí ìwọ kò sì gbàlà? Èéṣe tí ìwọ fi mú mi rí àìṣedéédéé Èéṣe tí ìwọ sì fi ààyè gba ìwà ìkà? Ìparun àti ìwà ipá wà ní iwájú mi; ìjà ń bẹ, ìkọlù sì wà pẹ̀lú.