Gẹn 8:1-5
Gẹn 8:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
ỌLỌRUN si ranti Noa, ati ohun alãye gbogbo, ati gbogbo ẹran-ọ̀sin ti o wà pẹlu rẹ̀ ninu ọkọ̀: Ọlọrun si mu afẹfẹ kọja lori ilẹ, omi na si fà. A si dí gbogbo isun ibú ati awọn ferese ọrun, o si mu òjo dá lati ọrun wá. Omi si npada kuro lori ilẹ, lojojumọ lẹhin ãdọjọ ọjọ́, omi si fà. Ọkọ̀ si kanlẹ li oṣù keje, ni ijọ́ kẹtadilogun oṣù, lori oke Ararati. Omi si nfà titi o fi di oṣù kẹwa: li oṣù kẹwa, li ọjọ́ kini oṣù li ori awọn okenla hàn
Gẹn 8:1-5 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn Ọlọrun ranti Noa, ati gbogbo ẹranko, ati ẹran ọ̀sìn tí ó wà pẹlu rẹ̀ ninu ọkọ̀. Nítorí náà, Ọlọrun mú kí afẹ́fẹ́ kan fẹ́ sórí ilẹ̀, omi náà sì bẹ̀rẹ̀ sí fà. Ọlọrun sé orísun omi tí ó wà lábẹ́ ilẹ̀, ó ti àwọn fèrèsé ojú ọ̀run, òjò náà sì dá. Omi bá bẹ̀rẹ̀ sí fà lórí ilẹ̀. Lẹ́yìn aadọjọ (150) ọjọ́, omi náà fà tán. Ní ọjọ́ kẹtadinlogun oṣù keje, ìdí ọkọ̀ náà kanlẹ̀ lórí òkè Ararati. Omi náà sì ń fà sí i títí di oṣù kẹwaa. Ní ọjọ́ kinni oṣù náà ni ṣóńṣó orí àwọn òkè ńlá hàn síta.
Gẹn 8:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọlọ́run sì rántí Noa àti ohun alààyè gbogbo tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, bí àwọn ẹranko igbó àti ohun ọ̀sìn, ó sì mú kí afẹ́fẹ́ fẹ́ sórí ilẹ̀, omi náà sì fà. Gbogbo ìsun ibú àti fèrèsé ìṣàn ọ̀run tì, òjò pẹ̀lú sì dáwọ́ rírọ̀ dúró. Omi sì bẹ̀rẹ̀ sí ní gbẹ kúrò lórí ilẹ̀, lẹ́yìn àádọ́jọ ọjọ́, ó sì ti ń fà. Ní ọjọ́ kẹtà-dínlógún oṣù kejì ni ọkọ̀ náà gúnlẹ̀ sórí òkè Ararati. Omi náà sì ń gbẹ si títí di oṣù kẹwàá. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kẹwàá, orí àwọn òkè sì farahàn.