Gẹn 7:1-5
Gẹn 7:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA si wi fun Noa pe, iwọ wá, ati gbogbo awọn ara ile rẹ sinu ọkọ̀, nitori iwọ ni mo ri li olododo niwaju mi ni iran yi. Ninu onirũru ẹran ti o mọ́ meje meje ni ki iwọ ki o mu wọn, ati akọ ati abo rẹ̀; ati ninu ẹran ti kò mọ́ meji meji, ati akọ ati abo rẹ̀. Ninu ẹiyẹ oju-ọrun pẹlu ni meje meje, ati akọ ati abo; lati dá irú si lãye lori ilẹ gbogbo. Nitori ijọ́ meje si i, emi o mu òjo rọ̀ si ilẹ li ogoji ọsán ati li ogoji oru; ohun alãye gbogbo ti mo dá li emi o parun kuro lori ilẹ. Noa si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA paṣẹ fun u.
Gẹn 7:1-5 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó yá OLUWA sọ fún Noa pé, “Wọ inú ọkọ̀ lọ, ìwọ ati àwọn ará ilé rẹ, nítorí pé ìwọ nìkan ni o jẹ́ olódodo sí mi ní gbogbo ayé. Ninu gbogbo ẹran tí ó bá jẹ́ mímọ́, mú wọn ní takọ-tabo, meje meje, ṣugbọn ninu gbogbo ẹran tí kò bá jẹ́ mímọ́, mú akọ kan ati abo kan. Mú takọ-tabo meje meje ninu àwọn ẹyẹ, kí irú wọn lè wà láàyè lórí ilẹ̀ ayé. Nítorí pé ọjọ́ meje ló kù tí n óo bẹ̀rẹ̀ sí rọ òjò sórí ilẹ̀ fún ogoji ọjọ́ tọ̀sán-tòru, gbogbo ẹ̀dá alààyè tí mo dá ni yóo sì parun lórí ilẹ̀ ayé.” Noa bá ṣe gbogbo ohun tí OLUWA pa láṣẹ fún un.
Gẹn 7:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Noa pé, “Wọ inú ọkọ̀ lọ ìwọ àti gbogbo ìdílé rẹ, nítorí ìwọ nìkan ni mo rí bí olódodo nínú ìran yìí. Mú méje méje nínú àwọn ẹran tí ó mọ́, akọ àti abo, mú méjì méjì takọ tabo nínú àwọn ẹran aláìmọ́. Sì mú méje méje pẹ̀lú nínú onírúurú ẹyẹ, takọ tabo ni kí o mú wọn, wọlé sínú ọkọ̀ pẹ̀lú rẹ, kí á ba à lè pa wọ́n mọ́ láààyè ní gbogbo ayé. Nítorí ní ọjọ́ méje sí ìhín, èmi yóò rọ òjò sórí ilẹ̀ fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, èmi yóò sì pa gbogbo ohun alààyè tí mo ti dá run kúrò lórí ilẹ̀.” Noa sì ṣe ohun gbogbo tí Ọlọ́run pàṣẹ fún un.