Gẹn 6:5-8
Gẹn 6:5-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọlọrun si ri pe ìwabuburu enia di pipọ̀ li aiye, ati pe gbogbo ìro ọkàn rẹ̀ kìki ibi ni lojojumọ. Inu OLUWA si bajẹ nitori ti o dá enia si aiye, o si dùn u de ọkàn rẹ̀. OLUWA si wipe, Emi o pa enia ti mo ti dá run kuro li ori ilẹ; ati enia, ati ẹranko, ati ohun ti nrakò, ati ẹiyẹ oju-ọrun; nitori inu mi bajẹ ti mo ti dá wọn. Ṣugbọn Noa ri ojurere loju OLUWA.
Gẹn 6:5-8 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí OLUWA rí i pé ìwà burúkú eniyan ti pọ̀ jù láyé, ati pé kìkì ibi ni èrò inú wọn nígbà gbogbo, inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi pé ó dá eniyan sí ayé, ó sì dùn ún, tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi wí pé, “N óo pa àwọn ẹ̀dá alààyè tí mo dá run lórí ilẹ̀ ayé, ati eniyan ati ẹranko ati àwọn ohun tí ń fàyà fà káàkiri lórí ilẹ̀, ati ẹyẹ, gbogbo wọn ni n óo parun, nítorí ó bà mí ninu jẹ́ pé mo dá wọn.” Ṣugbọn Noa rí ojurere OLUWA.
Gẹn 6:5-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA sì rí bí ìwà búburú ènìyàn ti ń gbilẹ̀ si, àti pé gbogbo èrò inú rẹ̀ kìkì ibi ni, ní ìgbà gbogbo. Inú OLúWA sì bàjẹ́ gidigidi nítorí pé ó dá ènìyàn sí ayé, ọkàn rẹ̀ sì gbọgbẹ́. Nítorí náà, OLúWA wí pé, “Èmi yóò pa ènìyàn tí mo ti dá run kúrò lórí ilẹ̀, ènìyàn àti ẹranko, àti ohun tí ń rákò, àti ẹyẹ ojú ọ̀run, nítorí inú mi bàjẹ́ pé mo ti dá wọn.” Ṣùgbọ́n, Noa rí ojúrere OLúWA.