Gẹn 50:11
Gẹn 50:11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati awọn ara ilẹ na, awọn ara Kenaani, si ri ọ̀fọ na ni ibi ilẹ ipakà Atadi, nwọn wipe, Ọ̀fọ nla li eyi fun awọn ara Egipti: nitorina ni nwọn ṣe sọ orukọ rẹ̀ ni Abel-misraimu, ti o wà loke odò Jordani.
Gẹn 50:11 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí àwọn ará Kenaani tí wọn ń gbé ibẹ̀ rí i bí wọ́n ti ń ṣọ̀fọ̀ ní ibi ìpakà náà, wọ́n wí pé, “Òkú yìí mà kúkú dun àwọn ará Ijipti o!” Nítorí náà, wọ́n sọ ibẹ̀ ní Abeli Misiraimu, ó wà ní apá ìlà oòrùn odò Jọdani.
Gẹn 50:11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí àwọn ará Kenaani tí ń gbé níbẹ̀ rí i bí wọ́n ti ń ṣọ̀fọ̀ náà ni ilẹ̀ ìpakà Atadi, wọ́n wí pé, “Ọ̀fọ̀ ńlá ni àwọn ará Ejibiti ń ṣe yìí.” Ìdí èyí ni a fi ń pe ibẹ̀ ní Abeli-Misraimu (Ìṣọ̀fọ̀ àwọn ará Ejibiti). Kò sì jìnnà sí Jordani.