Gẹn 5:1-3
Gẹn 5:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
EYI ni iwe iran Adamu: Li ọjọ́ ti Ọlọrun dá ọkunrin, li aworan Ọlọrun li o dá a. Ati akọ ati abo li o dá wọn; o si súre fun wọn, o si pè orukọ wọn ni Adamu, li ọjọ́ ti a dá wọn. Adamu si wà li ãdoje ọdún, o si bí ọmọkunrin kan ni jijọ ati li aworan ara rẹ̀; o si pè orukọ rẹ̀ ni Seti
Gẹn 5:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Àkọsílẹ̀ ìran Adamu nìyí: Nígbà tí Ọlọrun dá eniyan, ó dá wọn ní àwòrán ara rẹ̀. Takọ-tabo ni ó dá wọn, ó súre fún wọn, ó sì sọ wọ́n ní eniyan. Nígbà tí Adamu di ẹni aadoje (130) ọdún, ó bí ọmọkunrin kan. Ọmọ náà jọ ọ́ gidigidi, bí Adamu ti rí gan-an ni ọmọ náà rí. Ó bá sọ ọ́ ní Seti.
Gẹn 5:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èyí ni àkọsílẹ̀ ìran Adamu. Nígbà tí Ọlọ́run dá ènìyàn, ní àwòrán Ọlọ́run ni ó dá a. Àti akọ àti abo ni Ó dá wọn, ó sì súre fún wọn, ó sì pe orúkọ wọ́n ní Adamu ní ọjọ́ tí ó dá wọn. Nígbà tí Adamu di ẹni àádóje ọdún (130), ó bí ọmọkùnrin kan tí ó jọ ọ́, tí ó jẹ́ àwòrán ara rẹ̀, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Seti.