Gẹn 49:13-28

Gẹn 49:13-28 Bibeli Mimọ (YBCV)

Sebuloni ni yio ma gbé ebute okun: on ni yio si ma wà fun ebute ọkọ̀; ipinlẹ rẹ̀ yio si dé Sidoni. Issakari ni kẹtẹkẹtẹ ti o lera, ti o dubulẹ lãrin awọn agbo-agutan. O si ri pe isimi dara, ati ilẹ na pe o wuni; o si tẹ̀ ejiká rẹ̀ lati rẹrù, on si di ẹni nsìnrú. Dani yio ma ṣe idajọ awọn enia rẹ̀, bi ọkan ninu awọn ẹ̀ya Israeli. Dani yio dabi ejò li ẹba ọ̀na, bi paramọlẹ li ọ̀na, ti ibù ẹṣin ṣán ni gigĩsẹ, tòbẹ̃ ti ẹniti o gùn u yio fi ṣubu sẹhin. Emi ti duro dè ìgbala rẹ, OLUWA! Gadi ọwọ́-ogun ni yio kọlù u: ṣugbọn on lé wọn. Lati inu Aṣeri wá onjẹ rẹ̀ yio lọrá, on o si ma mú adidùn ọba wá. Naftali li abo-agbọnrin ti o le sare: o funni li ọ̀rọ rere. Josefu li ẹka eleso pupọ̀, ẹka eleso pupọ̀ li ẹba kanga; ẹtun ẹniti o yọ si ori ogiri. Awọn tafàtafa bà a ninu jẹ́ pọ̀ju, nwọn si tafà si i, nwọn si korira rẹ̀: Ṣugbọn ọrun rẹ̀ joko li agbara, a si mú apa ọwọ́ rẹ̀ larale, lati ọwọ́ Alagbara Jakobu wá, (lati ibẹ̀ li oluṣọ-agutan, okuta Israeli,) Ani lati ọwọ́ Ọlọrun baba rẹ wá, ẹniti yio ràn ọ lọwọ; ati lati ọwọ́ Olodumare wá, ẹniti yio fi ibukún lati oke ọrun busi i fun ọ, ibukún ọgbun ti o wà ni isalẹ, ibukún ọmú, ati ti inu. Ibukún baba rẹ ti jù ibukún awọn baba nla mi lọ, titi dé opin oke aiyeraiye wọnni: nwọn o si ma gbé ori Josefu, ati li atari ẹniti a yàsọtọ lãrin awọn arakunrin rẹ̀. Benjamini ni yio ma fàniya bi ikõkò: ni kutukutu ni yio ma jẹ ẹran-ọdẹ rẹ̀, ati li aṣalẹ ni yio ma pín ikogun rẹ̀. Gbogbo wọnyi li awọn ẹ̀ya Israeli mejejila: eyi ni baba wọn si sọ fun wọn, o si sure fun wọn; olukuluku bi ibukún tirẹ̀, li o sure fun wọn.

Gẹn 49:13-28 Yoruba Bible (YCE)

“Sebuluni yóo máa gbé etí òkun, ọkọ̀ ojú omi rẹ̀ kò ní níye, Sidoni ni yóo jẹ́ ààlà rẹ̀. “Isakari dàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó lágbára tí ó dùbúlẹ̀ láàrin gàárì ẹrù rẹ̀. Ṣugbọn nígbà tí ó rí i pé ibi ìsinmi dára ati pé ilẹ̀ náà dára, ó tẹ́ ẹ̀yìn sílẹ̀ láti ru ẹrù, ó sì di ẹni tí wọn ń mú sìn bí ẹrú. Dani ni yóo máa ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀yà Israẹli. Dani yóo dàbí ejò lójú ọ̀nà, ati bíi paramọ́lẹ̀ ní ẹ̀bá ọ̀nà, tí ń bu ẹṣin ní gìgísẹ̀ jẹ, kí ẹni tí ó gùn ún lè ṣubú sẹ́yìn. Mo dúró de ìgbàlà rẹ, Oluwa. Àwọn olè yóo máa kó Gadi lẹ́rù, ṣugbọn bí wọ́n ti ń kó o, bẹ́ẹ̀ ni yóo sì máa gbà á pada. Aṣeri yóo máa rí oúnjẹ dáradára mú jáde ninu oko rẹ̀, oúnjẹ ọlọ́lá ni yóo máa ti inú oko rẹ̀ jáde. Nafutali dàbí àgbọ̀nrín tí ń sáré káàkiri, tí ó sì ní àwọn ọmọ tí ó lẹ́wà. Josẹfu dàbí igi eléso tí ó wà lẹ́bàá odò, àwọn ẹ̀ka rẹ̀ nà mọ́ ara ògiri. Àwọn tafàtafà gbógun tì í kíkankíkan, wọ́n ń ta á lọ́fà, wọ́n sì ń dà á láàmú gidigidi, sibẹsibẹ ọrùn rẹ̀ kò mì, apá rẹ̀ sì ń lágbára sí i. Agbára Ọlọrun Jakọbu ni ó fún apá rẹ̀ ní okun, (ní orúkọ Olùṣọ́-aguntan náà, tí í ṣe Àpáta ààbò Israẹli), Ọlọrun baba rẹ yóo ràn ọ́ lọ́wọ́. Ọlọrun Olodumare yóo rọ òjò ibukun sórí rẹ láti òkè ọ̀run wá, yóo sì fún ọ ní ibukun omi tí ó wà ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀, ati ọpọlọpọ ọmọ ati ọpọlọpọ ẹran ọ̀sìn. Ibukun àwọn baba rẹ ju ti àwọn òkè ayérayé lọ, kí ibukun àwọn òkè ayérayé wá sórí Josẹfu, ẹni tí wọ́n yà ní ipá lọ́dọ̀ àwọn arakunrin rẹ̀. “Bẹnjamini dàbí ìkookò tí ebi ń pa, a máa pa ohun ọdẹ rẹ̀ ní òwúrọ̀, ati ní àṣáálẹ́ a máa pín ìkógun rẹ̀.” Àwọn ẹ̀yà Israẹli mejeejila ni a ti dárúkọ yìí, ati ohun tí baba wọn wí nígbà tí ó súre fún wọn. Ó súre tí ó tọ́ sí olukuluku fún un.

Gẹn 49:13-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Sebuluni yóò máa gbé ní etí Òkun, yóò sì jẹ́ èbúté fún ọkọ̀ ojú omi, agbègbè rẹ yóò tàn ká títí dé Sidoni. “Isakari jẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ alágbára tí ó dùbúlẹ̀ láàrín agbo àgùntàn. Nígbà tí ó bá rí bí ibi ìsinmi òun ti dára tó, àti bí ilẹ̀ rẹ̀ ti ní ìdẹ̀ra tó, yóò tẹ èjìká rẹ̀ ba láti ru àjàgà, yóò sì fi ara rẹ̀ fún iṣẹ́ ipá. “Dani yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀yà Israẹli. Dani yóò jẹ́ ejò ni pópónà àti paramọ́lẹ̀ ní ẹ̀bá ọ̀nà, tí ó bu ẹṣin jẹ ní ẹsẹ̀, kí ẹni tí ń gùn ún bá à le è ṣubú sẹ́yìn. “Mo ń dúró de ìtúsílẹ̀ rẹ, OLúWA. “Ẹgbẹ́ ogun àwọn ẹlẹ́ṣin yóò kọlu Gadi, ṣùgbọ́n yóò kọlu wọ́n ní gìgísẹ̀ wọn. “Oúnjẹ Aṣeri yóò dára; yóò ṣe àsè tí ó yẹ fún ọba. “Naftali yóò jẹ́ abo àgbọ̀nrín tí a tú sílẹ̀ tí ó ń bí ọmọ dáradára. “Josẹfu jẹ́ àjàrà eléso, àjàrà eléso ní etí odò, tí ẹ̀ka rẹ̀ gun orí odi. Pẹ̀lú ìkorò, àwọn tafàtafà dojú ìjà kọ ọ́, wọ́n tafà sí í pẹ̀lú ìkanra, Ṣùgbọ́n ọrun rẹ̀ dúró ni agbára, ọwọ́ agbára rẹ̀ ni a sì mu lára le, nítorí ọwọ́ alágbára Jakọbu, nítorí olùtọ́jú àti aláàbò àpáta Israẹli, nítorí Ọlọ́run baba rẹ tí ó ràn ọ́ lọ́wọ́, nítorí Olódùmarè tí ó bùkún ọ pẹ̀lú láti ọ̀run wá, ìbùkún ọ̀gbìn tí ó wà ní ìsàlẹ̀, ìbùkún ti ọmú àti ti inú. Ìbùkún baba rẹ pọ̀ púpọ̀ ju ìbùkún àwọn òkè ńlá ìgbàanì, ju ẹ̀bùn ńlá àwọn òkè láéláé. Jẹ́ kí gbogbo èyí sọ̀kalẹ̀ sí orí Josẹfu, lé ìpéǹpéjú ọmọ-aládé láàrín arákùnrin rẹ̀. “Benjamini jẹ́ ìkookò tí ó burú; ní òwúrọ̀ ni ó jẹ ẹran ọdẹ rẹ, ní àṣálẹ́, ó pín ìkógun.” Gbogbo ìwọ̀nyí ni àwọn ẹ̀yà Israẹli méjìlá, èyí sì ni ohun tí baba wọn sọ fún wọn nígbà tí ó súre fún wọn, tí ó sì fún ẹnìkọ̀ọ̀kan ní ìbùkún tí ó tọ́ sí i.