Gẹn 48:6 - Compare All Versions

Gẹn 48:6 YBCV (Bibeli Mimọ)

Ṣugbọn awọn ọmọ rẹ ti iwọ bí lẹhin wọn ni yio ṣe tirẹ, a o si ma pè wọn li orukọ awọn arakunrin wọn ni ilẹ iní wọn.

Gẹn 48:6 YCE (Yoruba Bible)

Àwọn ọmọ tí o bá tún bí lẹ́yìn wọn, ìwọ ni o ni wọ́n, ninu ogún tí ó bá kan Manase ati Efuraimu ni wọn yóo ti pín.

Gẹn 48:6 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Àwọn ọmọ mìíràn tí ìwọ bá bí lẹ́yìn wọn yóò jẹ́ ọmọ rẹ. Ní ilẹ̀ tí wọn yóò jogún, orúkọ arákùnrin wọn ni a ó máa fi pè wọ́n.