Gẹn 46:2-4
Gẹn 46:2-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọlọrun si bá Israeli sọ̀rọ li ojuran li oru, o si wipe, Jakobu, Jakobu. O si wipe, Emi niyi. O si wipe, Emi li Ọlọrun, Ọlọrun baba rẹ: má bẹ̀ru lati sọkalẹ lọ si ilẹ Egipti; nitori ibẹ̀ li emi o gbé sọ iwọ di orilẹ-ède nla. Emi o si bá ọ sọkalẹ lọ si Egipti; emi o si mú ọ goke wá nitõtọ: Josefu ni yio si fi ọwọ́ rẹ̀ pa ọ li oju dé.
Gẹn 46:2-4 Yoruba Bible (YCE)
Ọlọrun bá a sọ̀rọ̀ lójú ìran lóru, ó pè é, ó ní, “Jakọbu, Jakọbu.” Ó dáhùn, ó ní, “Èmi nìyí.” Ọlọrun wí pé, “Èmi ni Ọlọrun baba rẹ, má fòyà rárá láti lọ sí Ijipti, nítorí pé n óo sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá níbẹ̀. N óo bá ọ lọ sí Ijipti, n óo sì tún mú ọ pada wá, ọwọ́ Josẹfu ni o óo sì dákẹ́ sí.”
Gẹn 46:2-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọlọ́run sì bá Israẹli sọ̀rọ̀ ní ojú ìran ní òru pé, “Jakọbu! Jakọbu!” Ó sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.” Ọlọ́run sì wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run, Ọlọ́run baba rẹ, má ṣe bẹ̀rù láti sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Ejibiti nítorí, èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá níbẹ̀. Èmi yóò sì sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú rẹ lọ sí Ejibiti, èmi yóò sì tún mú ọ padà wá. Ọwọ́ Josẹfu fúnrarẹ̀ ni ìwọ yóò sì kú sí.”