Gẹn 43:1-14
Gẹn 43:1-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
ÌYAN na si mú ni ilẹ na gidigidi. O si ṣe, nigbati nwọn jẹ ọkà ti nwọn ti múbọ̀ Egipti wá tán, baba wọn wi fun wọn pe, Ẹ tun lọ irà onjẹ diẹ fun wa wá. Judah si wi fun u pe, ọkunrin na tẹnumọ́ ọ gidigidi fun wa pe, Ẹnyin kò gbọdọ ri oju mi, bikoṣepe arakunrin nyin ba pẹlu nyin. Bi iwọ o ba rán arakunrin wa pẹlu wa, awa o sọkalẹ lọ lati rà onjẹ fun ọ: Ṣugbọn bi iwọ ki yio ba rán a, awa ki yio sọkalẹ lọ: nitoriti ọkunrin na wi fun wa pe, Ẹnyin ki yio ri oju mi, bikoṣe arakunrin nyin ba pẹlu nyin. Israeli si wipe, Ẽṣe ti ẹnyin fi hùwa buburu bẹ̃ si mi, ti ẹnyin fi wi fun ọkunrin na pe, ẹnyin ní arakunrin kan pẹlu? Nwọn si wipe, ọkunrin na bère timọtimọ niti awa tikara wa, ati niti ibatan wa, wipe, Baba nyin wà sibẹ̀? ẹnyin li arakunrin miran? awa si wi fun u bi ọ̀rọ wọnyi: awa o ti ṣe le mọ̀ daju pe yio wipe, Mú arakunrin nyin sọkalẹ wá? Judah si wi fun Israeli baba rẹ̀ pe, Rán ọdọmọde na ba mi lọ, awa o si dide, a o lọ; ki awa ki o le yè, ki a má si ṣe kú, ati awa ati iwọ, ati awọn ọmọ wẹrẹ wa. Emi ni yio ṣe onigbọwọ rẹ̀: li ọwọ́ mi ni iwọ o bère rẹ̀; bi emi kò ba mú u pada fun ọ wá, ki nsi mu u duro niwaju rẹ, njẹ emi ni yio rù ẹbi na lailai. Bikoṣepe bi awa ti nṣe ilọra, awa iba sa ti pada bọ̀ lẹrinkeji nisisiyi. Israeli baba wọn si wi fun wọn pe, Njẹ bi bẹ̃ ba ni, eyi ni ki ẹ ṣe, ẹ mú ninu ãyo eso ilẹ yi, sinu ohun-èlo nyin, ki ẹ si mú ọrẹ lọ fun ọkunrin na, ikunra diẹ, ati oyin diẹ, ati turari, ojia, eso pupa, ati eso almondi: Ki ẹ si mú owo miran li ọwọ́ nyin; ati owo ti a mú pada wá li ẹnu àpo nyin, ẹ si tun mú u li ọwọ́ lọ; bọya o le ṣe èṣi: Ẹ mú arakunrin nyin pẹlu, ẹ si dide, ẹ tun pada tọ̀ ọkunrin na lọ: Ki Ọlọrun Olodumare ki o si fun nyin li ãnu niwaju ọkunrin na, ki o le rán arakunrin nyin ọhún wá, ati Benjamini. Bi a ba gbà mi li ọmọ, a gbà mi li ọmọ.
Gẹn 43:1-14 Yoruba Bible (YCE)
Ìyàn tí ó mú ní ilẹ̀ Kenaani ṣá túbọ̀ ń pọ̀ sí i ni. Nígbà tí wọ́n jẹ ọkà tí wọ́n rà ní Ijipti tán, baba wọn pè wọ́n, ó ní, “Ẹ tún wá lọ ra oúnjẹ díẹ̀ sí i.” Ṣugbọn Juda dá a lóhùn, ó ní, “Ọkunrin náà kìlọ̀ fún wa gidigidi pé a kò ní fi ojú kan òun láìjẹ́ pé a mú arakunrin wa lọ́wọ́. Bí o bá jẹ́ kí arakunrin wa bá wa lọ, a óo lọ ra oúnjẹ wá fún ọ, ṣugbọn bí o kò bá jẹ́ kí ó bá wa lọ, a kò ní lọ, nítorí pé ọkunrin náà tẹnumọ́ ọn fún wa pé a kò ní fi ojú kan òun láìjẹ́ pé arakunrin wa bá wa wá.” Israẹli ní, “Irú ọ̀ràn ńlá wo ni ẹ tún dá sí mi lọ́rùn yìí, tí ẹ lọ sọ fún ọkunrin náà pé ẹ ní arakunrin mìíràn?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Kò sí ohun tí ọkunrin náà kò bi wá tán nípa ará ati ẹbí wa, ó ní, ‘Ǹjẹ́ baba yín wà láàyè? Ǹjẹ́ ẹ tún ní arakunrin mìíràn?’ Àwọn ìbéèrè tí ó ń bèèrè ni ó mú kí á sọ ohun tí a sọ fún un. Báwo ni a ṣe lè mọ̀ pé yóo sọ pé kí á mú àbúrò wa wá?” Juda bá sọ fún Israẹli, ó ní, “Fa ọmọ náà lé mi lọ́wọ́, a óo sì lọ kí á lè wà láàyè, kí ebi má baà pa ẹnikẹ́ni kú ninu wa, ati àwọn ọmọ wa kéékèèké. N óo dúró fún ọmọ náà, ọwọ́ mi ni kí o ti bèèrè rẹ̀. Bí n kò bá mú un pada, kí n sì fà á lé ọ lọ́wọ́, da ẹ̀bi rẹ̀ lé mi lórí títí lae, nítorí pé bí a kò bá fi ìrìn àjò yìí falẹ̀ ni, à bá ti lọ, à bá sì ti dé, bí ẹẹmeji.” Israẹli, baba wọn bá sọ fún wọn pé, “Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ó dára, báyìí ni kí ẹ ṣe, ẹ dì ninu àwọn èso tí ó dára jùlọ ní ilẹ̀ yìí sinu àpò yín, kí ẹ gbé e lọ fún ọkunrin náà. Ẹ mú ìpara díẹ̀, oyin díẹ̀, turari díẹ̀ ati òjíá díẹ̀, ẹ mú èso pistakio ati èso alimọndi pẹlu. Ìlọ́po meji owó ọjà tí ẹ óo rà ni kí ẹ mú lọ́wọ́, ẹ mú owó tí ó wà lẹ́nu àpò yín níjelòó lọ́wọ́ pẹlu, bóyá wọ́n gbàgbé ni. Ẹ mú arakunrin yín náà lọ́wọ́, kí ẹ sì tọ ọkunrin náà lọ. Kí Ọlọrun Olodumare jẹ́ kí ọkunrin náà ṣàánú yín, kí ó sì dá arakunrin yín kan yòókù ati Bẹnjamini pada. Bí mo bá tilẹ̀ wá ṣòfò àwọn ọmọ mi nígbà náà, n óo gbà pé mo ṣòfò wọn.”
Gẹn 43:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Báyìí, ìyàn náà sì mú gidigidi ní ilẹ̀ náà. Nígbà tí wọ́n sì ti jẹ gbogbo ọkà tí wọ́n rà ní Ejibiti tan, baba wọn wí fún wọn pé, “Ẹ padà lọ ra oúnjẹ díẹ̀ si wá fún wa.” Ṣùgbọ́n Juda wí fún un pé, “Ọkùnrin náà tẹnumọ́ ọn nínú ìkìlọ̀ rẹ̀ fún wa pé, ‘Ẹ̀yin kì yóò rí ojúrere mi mọ́, àyàfi bí arákùnrin yín bá bá a yín wá’. Tí ìwọ yóò bá rán Benjamini arákùnrin wa lọ pẹ̀lú wa, a ó lọ ra oúnjẹ wá fún ọ. Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá ni jẹ́ kí ó bá wa lọ, àwa kì yóò lọ, nítorí ọkùnrin náà sọ fún wa pé, ‘Ẹ̀yin kì yóò rí ojúrere mi mọ́ àyàfi bí arákùnrin yín bá bá a yín wá.’ ” Israẹli béèrè pé, “Èéṣe tí ẹ fi kó ìdààmú yìí bá mi nípa sísọ fún ọkùnrin náà wí pé ẹ ní arákùnrin mìíràn?” Wọ́n dáhùn pé, “Ọkùnrin náà fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wádìí lọ́wọ́ wa nípa ìdílé wa àti àwa fúnra wa. Ó béèrè pé, ‘Ṣe baba yín ṣì wà láààyè? Ǹjẹ́ ẹ tún ní arákùnrin mìíràn?’ A kàn dáhùn ìbéèrè rẹ̀ ni. Báwo ni a ṣe le mọ̀ pé yóò wí pé, ‘Ẹ mú arákùnrin yín wá’?” Juda sì wí fún Israẹli baba rẹ̀, “Jẹ́ kí ọmọkùnrin náà lọ pẹ̀lú mi, a ó sì lọ ní kíákíá, kí àwa àti ìwọ àti àwọn ọmọ wa le yè, kí a má sì kú. Èmi fúnra mi yóò ṣe onídùúró fún un, èmi ni kí o gbà pé o fi lé lọ́wọ́. Bí n kò bá sì mú un padà tọ̀ ọ́ wá, jẹ́ kí ẹ̀bi rẹ̀ kí ó jẹ́ tèmi ní gbogbo ọjọ́ ayé mi níwájú rẹ. Bí ó bá ṣe pé a kò fi falẹ̀ ni, àwa ìbá ti lọ, à bá sì ti padà ní ìgbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.” Nígbà náà ni Israẹli baba wọn wí fún wọn, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, èyí ni kí ẹ ṣe: Ẹ mú àwọn ohun dáradára ilẹ̀ yìí lọ́wọ́ lọ bí ẹ̀bùn fún ọkùnrin náà—ìkunra díẹ̀, oyin díẹ̀, tùràrí àti òjìá, èso pisitakio àti èso almondi ìlọ́po owó méjì ni kí ẹ mú lọ́wọ́, nítorí ẹ gbọdọ̀ dá owó tí ẹ bá lẹ́nu àpò yín padà. Bóyá ẹnìkan ló ṣèèṣì fi síbẹ̀. Ẹ mú arákùnrin yín lọ́wọ́ pẹ̀lú ki ẹ sì tọ arákùnrin náà lọ. Kí Ọlọ́run alágbára (Eli-Ṣaddai) jẹ́ kí ẹ rí àánú gbà lọ́dọ̀ ọkùnrin náà kí ó ba à le jẹ́ kí arákùnrin yín tí ó wà lọ́hùn ún àti Benjamini padà wá pẹ̀lú yín. Ní tèmi, bí mo bá pàdánù àwọn ọmọ mi, n ó ṣọ̀fọ̀ wọn náà ni.”