Gẹn 41:14-32

Gẹn 41:14-32 Bibeli Mimọ (YBCV)

Nigbana ni Farao ranṣẹ o si pè Josefu, nwọn si yara mú u jade kuro ninu ihò-túbu; o si fari rẹ̀, o si parọ̀ aṣọ rẹ̀, o si tọ̀ Farao wá. Farao sí wi fun Josefu pe, Emi lá alá, kò si si ẹnikan ti o le tumọ̀ rẹ̀: emi si gburó rẹ pe, bi iwọ ba gbọ́ alá, iwọ le tumọ̀ rẹ̀. Josefu si da Farao li ohùn pe, Ki iṣe emi: Ọlọrun ni yio fi idahùn alafia fun Farao. Farao si wi fun Josefu pe, Li oju-alá mi, kiyesi i, emi duro lori bèbe odò. Si kiyesi i, abo-malu meje ti o sanra, ti o si dara lati wò, jade lati inu odò na wa; nwọn si njẹ ni ẽsu-odò: Si kiyesi i, abo-malu meje miran ti o joro, ti o burujù ni wiwò, ti o si rù, jade soke lẹhin wọn, nwọn buru tobẹ̃ ti emi kò ri irú wọn rí ni ilẹ Egipti. Awọn abo-malu ti o rù, ti nwọn si buru ni wiwò, nwọn mú awọn abo-malu meje sisanra iṣaju wọnni jẹ: Nigbati nwọn si jẹ wọn tán, a kò le mọ̀ pe, nwọn ti jẹ wọn: nwọn si buru ni wiwò sibẹ̀ gẹgẹ bi ìgba iṣaju. Bẹ̃ni mo jí. Mo si ri li oju-alá mi, si kiyesi i, ṣiri ọkà meje jade lara igi ọkà kan, o kún o si dara: Si kiyesi i, ṣiri ọkà meje rirẹ̀, ti o si fori, ati ti ẹfũfu ìla-õrùn rẹ̀ dànu, o rú jade lẹhin wọn: Awọn ṣiri ti o fori si mú awọn ṣiri rere meje nì jẹ; mo si rọ́ ọ fun awọn amoye; ṣugbọn kò sí ẹniti o le sọ ọ fun mi. Josefu si wi fun Farao pe, Ọkan li alá Farao: Ọlọrun ti fi ohun ti on mbọ̀wá iṣe hàn fun Farao. Awọn abo-malu daradara meje nì, ọdún meje ni: ati ṣiri daradara meje nì, ọdún meje ni: ọkan li alá na. Ati awọn abo-malu meje nì ti o rù ti o si buru ni wiwò ti nwọn jade soke lẹhin wọn, ọdún meje ni; ati ṣiri ọkà meje ti o fori nì, ti ẹfũfu ìla-õrùn rẹ̀ dànu nì, ọdún meje ìyan ni yio jasi. Eyi li ohun ti mo ti wi fun Farao pe, ohun ti Ọlọrun mbọ̀wá iṣe, o ti fihàn fun Farao. Kiyesi i, ọdún meje ọ̀pọ mbọ̀ já gbogbo ilẹ Egipti: Lẹhin wọn ọdún meje ìyan si mbọ̀; gbogbo ọ̀pọ nì li a o si gbagbe ni ilẹ Egipti; ìyan na yio si run ilẹ; A ki yio si mọ̀ ọ̀pọ na mọ́ ni ilẹ nitori ìyan na ti yio tẹle e, nitori yio mú gidigidi. Nitorina li alá na ṣe dìlu ni meji fun Farao; nitoripe lati ọdọ Ọlọrun li a ti fi idi ọ̀ran na mulẹ, Ọlọrun yio si mú u ṣẹ kánkan.

Gẹn 41:14-32 Yoruba Bible (YCE)

Farao bá ranṣẹ lọ pe Josẹfu, wọ́n sì mú un jáde kúrò ninu ẹ̀wọ̀n kíá. Lẹ́yìn tí ó fá irun rẹ̀, tí ó sì pààrọ̀ aṣọ rẹ̀, ó wá siwaju Farao. Farao sọ fún un pé, “Mo lá àlá kan, kò sì tíì sí ẹni tí ó lè túmọ̀ rẹ̀. Wọ́n bá sọ fún mi pé, bí o bá gbọ́ àlá, o óo lè túmọ̀ rẹ̀.” Josẹfu dá Farao lóhùn, ó ní, “Kò sí ní ìkáwọ́ mi, Ọlọrun ni yóo fún kabiyesi ní ìdáhùn rere.” Farao bá sọ fún Josẹfu pé, “Wò ó, lójú àlá, bí mo ti dúró létí bèbè odò Naili, mo rí i tí àwọn mààlúù meje kan tí wọ́n sanra rọ̀pọ̀tọ̀ rọ̀pọ̀tọ̀, tí ara wọn sì ń dán, ti inú odò náà jáde wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ koríko létí odò. Àwọn mààlúù meje mìíràn tún jáde láti inú odò náà, gbogbo wọn rù hangangan, wọ́n rí jàpàlà jàpàlà, n kò rí irú rẹ̀ rí ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti. Àwọn mààlúù tí wọ́n rù wọnyi gbé àwọn tí wọ́n sanra mì. Nígbà tí wọ́n gbé wọn mì tán, eniyan kò lè mọ̀ rárá pé wọ́n jẹ ohunkohun, nítorí pé wọ́n tún rù hangangan bákan náà ni. Mo bá tají. Mo tún lá àlá lẹẹkeji, mo rí ṣiiri ọkà meje lórí igi ọkà kan, wọ́n tóbi, wọ́n sì yọmọ. Mo tún rí i tí ṣiiri ọkà meje mìíràn yọ lẹ́yìn wọn, wọ́n tínínrín, wọn kò sì ní ọmọ ninu rárá, nítorí afẹ́fẹ́ ìhà ìlà oòrùn ti pa ọlá mọ́ wọn lára. Àwọn ṣiiri ọkà tí kò níláárí wọnyi gbé àwọn tí wọ́n dára mì. Mo rọ́ àwọn àlá mi fún àwọn adáhunṣe, ṣugbọn kò sí ẹnìkan tí ó lè túmọ̀ wọn fún mi.” Josẹfu sọ fún Farao, ó ní, “Ọ̀kan náà ni àlá mejeeji, Ọlọrun fi ohun tí ó fẹ́ ṣe han kabiyesi ni. Àwọn mààlúù rọ̀pọ̀tọ̀ rọ̀pọ̀tọ̀ meje nnì ati àwọn ṣiiri ọkà meje tí wọ́n yọmọ dúró fún ọdún meje. Ọ̀kan náà ni àwọn àlá mejeeji. Àwọn mààlúù meje tí wọ́n rù, tí wọ́n sì rí jàpàlà jàpàlà tí wọ́n jáde lẹ́yìn àwọn ti àkọ́kọ́, ati àwọn ṣiiri ọkà meje tí kò yọmọ, tí afẹ́fẹ́ ìhà ìlà oòrùn ti pa ọlá mọ́ lára, àwọn náà dúró fún ìyàn ọdún meje. Bí ọ̀rọ̀ ti rí gan-an ni mo sọ fún kabiyesi yìí, Ọlọrun ti fi ohun tí ó fẹ́ ṣe han kabiyesi. Ọdún meje kan ń bọ̀ tí oúnjẹ yóo pọ̀ yanturu ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti, ṣugbọn lẹ́yìn náà ìyàn yóo mú fún ọdún meje, ìyàn náà yóo pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ọdún meje tí oúnjẹ pọ̀ yóo di ìgbàgbé ní ilẹ̀ Ijipti, ìyàn náà yóo run ilẹ̀ yìí. Ẹnikẹ́ni kò sì ní mọ̀ pé oúnjẹ ti fi ìgbà kan pọ̀ rí, nítorí ìyàn ńlá tí yóo tẹ̀lé e yóo burú jáì. Ìdí tí àlá kabiyesi náà fi jẹ́ meji ni láti fihàn pé Ọlọrun ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀, láìpẹ́, Ọlọrun yóo mú un ṣẹ.

Gẹn 41:14-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nítorí náà Farao ránṣẹ́ pe Josẹfu, wọn sì mú un wá kíákíá láti inú ìhámọ́. Nígbà tí ó fá irun rẹ̀, tí ó sì pààrọ̀ aṣọ rẹ̀, ó wá síwájú Farao. Farao wí fún Josẹfu, “Mo lá àlá kan, kò sì sí ẹni tí o le è túmọ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n mo ti gbọ́ nípa rẹ pé bí o bá ti gbọ́ àlá, o le è túmọ̀ rẹ̀.” Josẹfu dá Farao ní ohùn pé, “Kì í ṣe agbára mi, ṣùgbọ́n, Ọlọ́run ni yóò fi ìdáhùn àlàáfíà fún Farao ní ìtumọ̀ àlá náà.” Nígbà náà ni Farao wí fún Josẹfu pé, “Ní inú àlá mi, mo dúró ni etí bèbè odò Naili, sì kíyèsi i, màlúù méje tí ó sanra tí o sì lẹ́wà jáde wá, wọ́n sì ń jẹ koríko ní tòsí ibẹ̀. Lẹ́yìn wọn, màlúù méje mìíràn jáde wá, wọ́n rù hángógó, wọn kò sì lẹ́wà tó bẹ́ẹ̀ tí n kò tí ì rí irú màlúù tí ó ṣe àìlẹ́wà tó bẹ́ẹ̀ rí ní ilẹ̀ Ejibiti. Àwọn màlúù tí ó rù tí kò sì lẹ́wà sì jẹ àwọn màlúù tí ó sanra tí ó kọ́ jáde nínú odò. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jẹ́ wọ́n tan, kò sì ẹni tí ó le mọ̀ pé wọ́n jẹ ohunkóhun, nítorí wọn kò sanra sí i, wọn sì bùrẹ́wà síbẹ̀. Nígbà náà ni mo tají. “Ní ojú àlá mi, mo tún rí síírí ọkà méje tí ó yó ọmọ tí ó sì dára, wọ́n jáde láti ara igi ọkà kan. Lẹ́yìn wọn, àwọn méje mìíràn yọ jáde, tí kò yó ọmọ bẹ́ẹ̀ ni afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn ti rẹ̀ ẹ́ dànù tán. Àwọn síírí ọkà méje tí kò yómọ sì gbé àwọn méje tí ó dára wọ̀nyí mì. Mo sọ àlá yìí fún àwọn onídán mi, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó le túmọ̀ rẹ̀ fún mi.” Nígbà náà ni Josẹfu wí fún Farao, “Ìtumọ̀ kan náà ni àwọn àlá méjèèjì ní. Ọlọ́run fi ohun tí ó fẹ́ ṣe hàn fún Farao. Àwọn màlúù méje ti ó dára jẹ́ ọdún méje, síírí ọkà méje tí ó dára náà sì jẹ́ ọdún méje: ọ̀kan ṣoṣo ni wọn, àlá kan náà ni. Àwọn màlúù méje tí kò sanra, tí kò sì rẹwà tí ó jáde gbẹ̀yìn jẹ́ ọdún méje, bẹ́ẹ̀ náà ni síírí ọkà méje tí kò dára, tí afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn ti rẹ̀ dànù tan: Wọn jẹ́ ọdún méje tí ìyàn yóò fi mú. “Bí mo ti wí fún Farao ní ìṣáájú náà ni: Ọlọ́run fi ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ han Farao. Ọdún méje tí oúnjẹ yóò pọ̀ yanturu ń bọ̀ wà ní Ejibiti. Ṣùgbọ́n ọdún méje mìíràn tí ìyàn yóò mú ń bọ̀, nígbà náà ni a ó tilẹ̀ gbàgbé gbogbo ọ̀pọ̀ ní ilẹ̀ Ejibiti, ìyàn yóò sì run gbogbo ilẹ̀ náà, A kò ní rántí àsìkò ọ̀pọ̀ oúnjẹ yanturu náà mọ́ nítorí pé ìyàn tí yóò tẹ̀lé e yóò pọ̀ púpọ̀. Ìdí tí Ọlọ́run fi fi àlá náà han fún Farao ní ọ̀nà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni pé, Ọlọ́run ti pinnu pé yóò ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ dandan, àti pé kò ni pẹ́ tí Ọlọ́run yóò fi ṣe é.