Gẹn 41:1-4
Gẹn 41:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
O SI ṣe li opin ọdún meji ṣanṣan, ni Farao lá alá: si kiyesi i, o duro li ẹba odo. Si kiyesi i abo-malu meje, ti o dara ni wiwò, ti o sanra, jade lati inu odò na wá: nwọn si njẹ ninu ẽsu-odò. Si kiyesi i, abo-malu meje miran ti o buru ni wiwò, ti o si rù, jade lẹhin wọn lati inu odò na wá; nwọn si duro tì awọn abo-malu nì ni bèbe odò na. Awọn abo-malu ti o buru ni wiwò ti o si rù si mú awọn abo-malu meje ti o dara ni wiwò ti o si sanra wọnni jẹ. Bẹ̃ni Farao jí.
Gẹn 41:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn ọdún meji gbáko, Farao náà wá lá àlá pé òun dúró létí odò Naili. Ó rí àwọn mààlúù meje kan tí wọ́n sanra rọ̀pọ̀tọ̀ rọ̀pọ̀tọ̀, tí ara wọ́n sì ń dán, wọ́n ti inú odò náà jáde wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ koríko létí odò. Rírí tí yóo tún rí, ó rí àwọn mààlúù meje mìíràn, wọ́n tún ti inú odò náà jáde wá, àwọn wọnyi rù hangangan, wọ́n rí jàpàlà jàpàlà, wọ́n dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn meje ti àkọ́kọ́. Àwọn meje tí wọ́n rù hangangan náà ki àwọn meje tí wọ́n sanra rọ̀pọ̀tọ̀ rọ̀pọ̀tọ̀ mọ́lẹ̀, wọ́n sì gbé wọn mì, Farao bá tají.
Gẹn 41:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí odindi ọdún méjì sì ti kọjá, Farao lá àlá: ó rí ara rẹ̀ tó dúró ní etí odò Naili. Nígbà náà ni màlúù méje jáde láti inú odò, wọ́n dára láti wò, wọ́n sì sanra, wọ́n sì ń jẹ koríko. Lẹ́yìn àwọn wọ̀nyí, ni àwọn màlúù méje mìíràn tí kò lẹ́wà tí ó sì rù jáde wá láti inú odò Naili, wọ́n sì dúró ti àwọn méje tí ó sanra tí ó wà ní bèbè odò náà. Àwọn màlúù tí ó rù, tí kò sì lẹ́wà sì gbé àwọn tí ó lẹ́wà tí ó sanra jẹ. Nígbà náà ni Farao jí.